Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ August 30
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ AUGUST 30
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cf orí 9 ìpínrọ̀ 17 sí 21 àti àpótí tó wà lójú ìwé 96
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 2 Àwọn Ọba 9-11
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: “Ǹjẹ́ O Ti Lo Ẹ̀yìn Ìwé Ìròyìn?” Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Lo àbá kan láti inú àpilẹ̀kọ náà láti ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ September 1 lóde ẹ̀rí. Lẹ́yìn náà, yan ọ̀kan tàbí méjì lára àwọn àpilẹ̀kọ tó wà nínú Jí! July–September, kó o sì ní kí àwọn ará sọ ìbéèrè àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè fi gbé ọ̀rọ̀ wọn kalẹ̀. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo ìwé ìròyìn Jí! náà.
10 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tàbí méjì tó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ nínú ìjọ, tí wọ́n sì ti ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àwọn ìyípadà wo ló ti bá ọ̀nà tá a gbà ń wàásù látìgbà tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù? Àwọn ìtẹ̀síwájú wo ni wọ́n ti fojú ara wọn rí nínú ètò Ọlọ́run ní àdúgbò àti yíká ayé? Àwọn ọ̀nà wo ni ètò Ọlọ́run ti gbà ràn wọ́n lọ́wọ́ tó mú kí wọ́n tẹ̀ síwájú gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere?