Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní August: Ẹ lè lo èyíkéyìí lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 tó bá wà lọ́wọ́: Ẹmi Awọn Oku, Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!, Ki Ni Ète Igbesi-Aye—Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? àti Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I? Ẹ tún lè lo àwọn ìwé pẹlẹbẹ míì tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ tí ìjọ bá ní lọ́wọ́. September: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́ tẹ́ ẹ bá wàásù fún ẹnì kan. October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Ẹ fún ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ wa ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́?, kẹ́ ẹ sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. November: Kí Ló Wà Nínú Bíbélì? A ṣì máa pèsè ìsọfúnni nípa bá a ṣe máa pín ìwé pẹlẹbẹ yìí kárí ayé. Ẹ tún fún àwọn èèyàn ní àwọn ìwé pẹlẹbẹ yìí ní àfikún sí ìwé pẹlẹbẹ tuntun náà: Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run! àti Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù September, àkòrí àsọyé fún gbogbo ènìyàn tí àwọn alábòójútó àyíká yóò máa sọ ni, “Má Ṣe Máa Wo Àwọn Ohun Tí Kò Ní Láárí!”
◼ A ti ṣe àwọn àtúnṣe tó tẹ̀ lé e yìí sí àwọn ibi tá a ti máa ṣe Àpéjọ Àgbègbè ọdún 2010 sí 2011:
November 26-28, 2010
BÀDÁGÌRÌ 9 (Gẹ̀ẹ́sì)
BENIN CITY 9 (Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà)
December 3-5, 2010
BÀDÁGÌRÌ 10 (Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà)
BENIN CITY 10 (Ẹdó)
January 7-9, 2011
ÙLÌ 12 (Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà)