Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ December 16
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ DECEMBER 16
Orin 116 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jl Ẹ̀kọ́ 20 sí 22 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ìṣípayá 1-6 (10 min.)
No. 1: Ìṣípayá 3:14–4:8 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ṣé Èṣù Wà Lóòótọ́?—td 10A (5 min.)
No. 3: Báwo Ni Jésù Ṣe “Fi Àwòṣe Lélẹ̀” Fáwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Rẹ̀?—Jòh. 13:15 (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Bí Ìlapa Èrò Ṣe Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù. Ìjíròrò tá a gbé ka ìwé Jàǹfààní, ojú ìwé 167, ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 168, ìpínrọ̀ 1. Ẹ fi ìwé tá a máa lò ní oṣù yìí ṣe àṣefihàn kan tó jẹ́ ìdánìkansọ̀rọ̀. Akéde kan ń múra ìlapa èrò tó máa lò sílẹ̀ kó tó lọ sóde ẹ̀rí.
10 min: Kí Àwọn Ọ̀dọ́ Máa Yin Jèhófà. (Sm. 148:12, 13) Fi ọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn ọ̀dọ́ méjì tàbí mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà. Àwọn ìṣòro wo ni wọ́n dojú kọ níléèwé tó dán ìgbàgbọ́ wọn wò? Báwo ni àwọn òbí wọn àtàwọn míì ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro náà? Kí ló mú kí wọ́n lè fi ìgboyà sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́? Ní kí wọ́n sọ ohun tó ṣẹlẹ̀.
10 min: “A Máa Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Sún Mọ́ Jèhófà Lọ́sẹ̀ January 6.” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
Orin 75 àti Àdúrà