ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÒHÁNÙ 1-2
Iṣẹ́ Ìyanu Àkọ́kọ́ Tí Jésù Ṣe
Iṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́ tí Jésù ṣe jẹ́ ká mọ irú ẹni tó jẹ́. Kí ni ìtàn Bíbélì yìí kọ́ wa nípa àwọn nǹkan yìí?
- Jésù ní èrò tó tọ́ nípa fàájì, ó gbádùn ara ẹ̀, ó sì lo àkókò tó tura pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ 
- Jésù máa ń bìkítà nípa bọ́rọ̀ ṣe rí lára àwọn ẹlòmíì 
- Ọ̀làwọ́ ni Jésù