ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁÀKÙ 1-2
“A Dárí Àwọn Ẹ̀ṣẹ̀ Rẹ Jì”
Ẹ̀kọ́ wo ni a rí kọ́ nínú iṣẹ́ ìyanu yìí?
- Ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún ló jẹ́ ká máa ṣàìsàn 
- Jésù ní agbára láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini àti láti mú àwọn aláìsàn lára dá 
- Nínú Ìjọba Ọlọ́run, Jésù máa mú àìpé àti àìsàn kúrò títí láé 
Báwo ni Máàkù 2:5-12 ṣe lè ràn mí lọ́wọ́ láti fara dà á tí mo bá ń ṣàìsàn?