ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yb14 ojú ìwé 154-160
  • 2002 sí 2013 Ohun Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Láwọn Ọdún Àìpẹ́ Yìí (Apá Kìíní)

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • 2002 sí 2013 Ohun Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Láwọn Ọdún Àìpẹ́ Yìí (Apá Kìíní)
  • Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
  • Ìsọ̀rí
  • “Jèhófà O Ṣeun O!”
  • A Rí Àwọn Àgùntàn Jèhófà Tó Sọ Nù
  • Àwọn Mùsùlùmí Tó Lọ́kàn Rere Gba Òtítọ́
  • Fífi Ìgboyà Tẹ̀ Lé Ìlànà Ìjẹ́mímọ́ Ẹ̀jẹ̀
Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
yb14 ojú ìwé 154-160
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 154]

SIERRA LEONE ÀTI GUINEA

2002 sí 2013 Ohun Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Láwọn Ọdún Àìpẹ́ Yìí (Apá Kìíní)

“Jèhófà O Ṣeun O!”

Nígbà tí àwọn nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí í pa dà bọ̀ sípò nílùú, àwọn ará ń pa dà wá sí ibùgbé wọn tí ogun ti bà jẹ́. Ìjọ tún bẹ̀rẹ̀ pa dà láwọn ibi tí ìjọ ti tú ká nígbà ogun, pàápàá lápá ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Sierra Leone. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe tó wà ní àgbègbè kan ròyìn pé: “Èèyàn mẹ́rìndínlógún [16] ló wá sí ìpàdé wa àkọ́kọ́, mẹ́rìndínlógójì [36] wá sí èyí tó tẹ̀ lé e, mẹ́rìndínlọ́gọ́ta [56] ló wá gbádùn èyí tó tẹ̀ lé ìyẹn, mẹ́tàdínlọ́gọ́rin [77] sì wá sí Ìrántí Ikú Kristi! Èyí wú wa lórí gan-an ni!” Ìjọ tuntun mẹ́sàn-án ni wọ́n dá sílẹ̀, tí iye ìjọ lápapọ̀ fi wá di mẹ́rìnlélógún [24]. Míṣọ́nnárì mẹ́wàá míì tó jáde ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì tún dé, ìyẹn sì mú kí iṣẹ́ ìwàásù túbọ̀ tẹ̀ síwájú. Lọ́dún 2004, àwọn tó wá sí Ìrántí Ikú Kristi jẹ́ ẹgbẹ̀rún méje àti ẹgbẹ̀ta ó dín mẹ́fà [7,594], èyí sì ju ìlọ́po márùn-ún iye àwọn akéde lọ! Irú ìtẹ̀síwájú yìí náà ló wáyé ní orílẹ̀-èdè Guinea.

[Graph tó wà ní ojú ìwé 154]

Ní kánmọ́, Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣètò owó àkànlò fún ìrànlọ́wọ́ pàjáwìrì láti fi ran àwọn tí ogun lé kúrò nílùú lọ́wọ́, kí wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé wọn lákọ̀tun nígbà tí wọ́n pa dà dé. (Ják. 2:15, 16) Gbọ̀ngàn Ìjọba méjìlá ni àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn kọ́ tàbí tí wọ́n tún ṣe bí wọ́n ṣe ń lọ káàkiri láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tí àjálù bá. Wọ́n sì tún Gbọ̀ngàn Àpéjọ kan ṣe ní ìlú Koindu. Wọ́n tún fi bíríkì alámọ̀ kọ́ ilé méjìlélógójì [42] tó mọ níwọ̀n fún ìdílé àwọn ará wa tí ogun ba ilé wọn jẹ́. Nígbà tí arábìnrin opó kan tó jẹ́ ẹni àádọ́rin [70] ọdún dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé rẹ̀ tuntun tí wọ́n fi páànù kàn, omijé ayọ̀ ń dà lójú rẹ̀, ó sì kígbe pé: “Áà, Jèhófà o ṣeun! Jèhófà o ṣeun o! Ẹ̀yin ará, ẹ ṣé o!”

Ẹ̀ka ọ́fíìsì pẹ̀lú bẹ̀rẹ̀ sí í fi owó tó wà fún àwọn orílẹ̀-èdè táwọn ará ò ti fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́ kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba. Saidu Juanah tó jẹ́ alàgbà àti aṣáájú-ọ̀nà ní ìjọ Bo West sọ pé: “Arábìnrin kan sọ fún mi pé, ‘Tí òun bá gbọ́ pé a máa ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun, ọwọ́ nìkan kọ́ ni òun máa fi pàtẹ́wọ́, òun á tún fẹsẹ̀ pa á!’ Lóòótọ́, nígbà tí mo ṣe ìfilọ̀ pé a máa ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun, ṣe ni arábìnrin yìí fò dìde lórí ìjókòó, tó ń pàtẹ́wọ́ tó sì ń jó. Ẹ ò ri pé ọwọ́ nìkan kọ́ ló fi pàtẹ́wọ́ lóòótọ́, ó tún fẹsẹ̀ pa á!”

Lọ́dún 2010, ìjọ Waterloo ṣe ìyàsímímọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun kan tó ṣeé lò fún Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Ó gbà tó ẹgbẹ̀rin [800] èèyàn. Ó ṣẹlẹ̀ pé lọ́jọ́ tí ìjọ yìí ra ilẹ̀ yẹn, ẹlòmíì ti wá bá obìnrin tó ni ilẹ̀ náà pé òun fẹ́ rà á lówó tó ju ti ìjọ yẹn lọ. Àmọ́ obìnrin náà sọ pé: “Ó tẹ́ mi lọ́rùn kí wọ́n kọ́ ibi tí wọ́n á ti máa ṣe àpéjọ ìsìn sórí ilẹ̀ mi ju pé kí n tà á fáwọn táá máa ṣòwò níbẹ̀.”

Ètò tó wà fún ṣíṣèrànwọ́ fáwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn ará ò ti fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́ ti jẹ́ ká lè kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́tàdínlógún [17] ní orílẹ̀-èdè Sierra Leone, a sì kọ́ mẹ́fà ní orílẹ̀-èdè Guinea. Àwọn ibi ìjọsìn tó bójú mu tó sì wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì tá a ní yìí ti jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa wá sí àwọn ìpàdé wa.

A Rí Àwọn Àgùntàn Jèhófà Tó Sọ Nù

Bí àwọn ará tó ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù ṣe ń pọ̀ sí i, ẹ̀ka ọ́fíìsì ṣètò pé ká lọ fi oṣù méjì wàásù ní àwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù tí a kì í ṣe déédéé. Ìwé tí àwọn akéde fi sóde fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ [15,000], wọ́n sì ní ọ̀pọ̀ ìrírí alárinrin. Àwọn kan béèrè bóyá ó ṣeé ṣe kí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dá ìjọ sílẹ̀ ní àwọn ìlú tó wà ní àgbègbè yẹn. Bó ṣe di pé a dá ìjọ méjì sílẹ̀ níbẹ̀ nìyẹn. Ní abúlé kan tó wà ní àdádó, àwọn ará rí àwọn arábìnrin méjì kan tí wọn kò rí àwọn ará mọ́ láti ìgbà tí ogun ti lé wọn kúrò nílé. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ làwọn ará bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn ìpàdé ní abúlé náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níbẹ̀.

Lọ́dún 2009, ẹ̀ka ọ́fíìsì gbọ́ pé àwọn kan wà ní abúlé kan láàárín igbó kìjikìji lórílẹ̀-èdè Guinea tí wọ́n sọ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn. Nígbà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì rán àwọn ará lọ ṣèwádìí, wọ́n gbọ́ pé arákùnrin àgbàlagbà kan tó fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ló pa dà sí abúlé rẹ̀ níbẹ̀. Ó sì ti kọ́ àwọn ọkùnrin mélòó kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kó tó kú. Ọ̀kan lára àwọn tó bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ gba Jèhófà gbọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ tó ti mọ̀ látinú Bíbélì. Ó tún ń ṣe àwọn ìpàdé, àwọn ìwé arákùnrin tó ti kú náà ló sì fi ń ṣe é. Ó tó ogún ọdún tí àwùjọ yẹn ti ń sin Jèhófà kí akéde kan tó ṣèèṣì bá wọn pàdé. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ẹ̀ka ọ́fíìsì rán àwọn arákùnrin lọ síbẹ̀ pé kí wọ́n lọ ran àwùjọ náà lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. Lọ́dún 2012, àádọ́sàn-án ó lé méjì [172] èèyàn ló wá sí Ìrántí Ikú Kristi ní abúlé náà.

Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, a túbọ̀ ń ṣàwárí ọ̀pọ̀ àwọn tó dà bí àgùntàn tó sọ nù. Ṣe ni àwọn kan lára wọn sú lọ kúrò nínú òtítọ́, ìjọ ló sì yọ àwọn míì lẹ́gbẹ́. Ọ̀pọ̀ irú àwọn tó dà bí ọmọ onínàákúnàá yìí ló ti ronú pìwà dà, tí wọ́n sì pa dà wá sínú òtítọ́. Àwọn èèyàn Jèhófà sì tẹ́wọ́ gbà wọ́n pa dà tọkàntọkàn.—Lúùkù 15:11-24.

Àwọn Mùsùlùmí Tó Lọ́kàn Rere Gba Òtítọ́

Tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù bá ń wàásù ìhìn rere fún àwọn èèyàn, ó máa ń “di ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo.” (1 Kọ́r. 9:22, 23) Bákan náà, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lórílẹ̀-èdè Sierra Leone àti Guinea ti yí ọ̀nà tí wọ́n gbà ń bẹ̀rẹ̀ ìwàásù pa dà kó lè máa wu onírúurú èèyàn láti gbọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀sìn Mùsùlùmí ló gbilẹ̀ jù lórílẹ̀-èdè méjèèjì yìí, ẹ wo àpẹẹrẹ bí àwọn akéde kan ṣe máa ń bá àwọn Mùsùlùmí tó fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa sọ̀rọ̀.

Saidu Juanah tó jẹ́ Mùsùlùmí tẹ́lẹ̀ ṣàlàyé pé: “Àwọn Mùsùlùmí gbà pé erùpẹ̀ ni wọ́n fi dá Ádámù, àmọ́ ó kọ́kọ́ gbé inú Párádísè kan ní ọ̀run ná. Kí òye ọ̀rọ̀ náà lè yé wọn dáádáá, mo máa ń bi wọ́n pé, ‘Ibo la ti ń rí erùpẹ̀?’

“Wọ́n á ní: ‘Ilẹ̀ ayé.’

“Màá wá bi wọ́n pé: ‘Torí náà, ibo nìyẹn fi hàn pé wọ́n ti dá Ádámù?’

“Wọ́n á dáhùn pé: ‘Orí ilẹ̀ ayé ni.’

“Láti tẹ kókó yẹn mọ́ wọn lọ́kàn, màá ka Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28, màá wá bi wọ́n pé, ‘Ǹjẹ́ àwọn ẹ̀dá ọ̀run ń bímọ?’

“Wọ́n á ní: ‘Rárá o. Àwọn màláíkà kì í bímọ.’

“Màá wá béèrè pé: ‘Nígbà tí Ọlọ́run wá ní kí Ádámù àti Éfà máa bímọ, ibo ni ìyẹn fi hàn pé wọ́n wà?’

“Wọ́n á dáhùn pé: ‘Orí ilẹ̀ ayé.’

“Màá tún wá bi wọ́n pé: ‘Torí náà tí Ọlọ́run bá máa mú Párádísè wá, ibo ni Párádísè yẹn máa wá wà?’

“Wọ́n á ní: ‘Orí ilẹ̀ ayé níbí ni.’”

Saidu wá sọ pé: “Irú ìfèròwérò tó dá lórí Bíbélì bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ kí àwọn Mùsùlùmí tó lọ́kàn rere túbọ̀ fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa, kí wọ́n sì gba ìwé tá a fi ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”

Àpẹẹrẹ kan ni ti Momoh, Mùsùlùmí kan tó ní ṣọ́ọ̀bù tó ti ń tajà, tó sì ń ronú pé òun máa di Lèmọ́mù lọ́jọ́ kan. Nígbà tí àwọn míṣọ́nnárì ṣàlàyé ọ̀rọ̀ Bíbélì fún un, ó yà á lẹ́nu ó sì fẹ́ mọ̀ sí i. Ó lọ gbọ́ apá kan nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àyíká, ohun tó gbọ́ sì dùn mọ́ ọn. Ọjọ́ mẹ́rin lẹ́yìn náà, òun àti aya rẹ̀ Ramatu àti ọmọ wọn márùn-ún lọ síbi Ìrántí Ikú Kristi. Bí Momoh ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lójú méjèèjì nìyẹn o! Lẹ́yìn tó ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ bí ẹ̀ẹ̀melòó kan, kò ta sìgá mọ́. Ó ń sọ fún àwọn oníbàárà rẹ̀ pé sìgá mímu ń ṣàkóbá fára àti pé Ọlọ́run ò fẹ́ ẹ. Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ṣọ́ọ̀bù rẹ̀. Tí àwọn èèyàn bá fẹ́ rajà nígbà tí ìdílé rẹ̀ ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́, yóò ní kí wọ́n jókòó tí àwọn fi máa ṣe tán, pé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe pàtàkì fún ìdílé òun. Nígbà tí òun àti Ramatu lọ forúkọ ìgbéyàwó wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin, àwọn ẹbí wọn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àtakò sí wọn gan-an. Ṣùgbọ́n Momoh àti Ramatu ń fi ìgboyà wàásù fún àwọn ìbátan wọn láìfi àtakò pè. Àwọn yẹn sì ń fọ̀wọ̀ wọ̀ wọ́n nígbà tó yá nítorí ìwà rere wọn. Momoh ṣèrìbọmi lọ́dún 2008, Ramatu sì ṣèrìbọmi lọ́dún 2011.

Fífi Ìgboyà Tẹ̀ Lé Ìlànà Ìjẹ́mímọ́ Ẹ̀jẹ̀

Àwọn èèyàn Jèhófà ń fi ìgboyà tẹ̀ lé àwọn ìlànà ìwà híhù tí Ọlọ́run fi lélẹ̀, títí kan ohun tó sọ nípa ẹ̀jẹ̀. (Ìṣe 15:29) Àwọn oníṣègùn tó fara mọ́ ìpinnu wa lórí ìlànà Ọlọ́run yìí túbọ̀ ń pọ̀ sí i lórílẹ̀-èdè Sierra Leone àti Guinea.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 159]

Àwọn arákùnrin ń sọ̀rọ̀ ìyànjú fún arábìnrin kan nílé ìwòsàn

Lọ́dún 1978, àwọn ará pín ìwé kékeré tó sọ̀rọ̀ nípa ojú tí àwa Ẹlẹ́rìí fi ń wo ẹ̀jẹ̀, ìyẹn Jehovah’s Witnesses and the Question of Blood, fún àwọn dókítà, nọ́ọ̀sì, àwọn alábòójútó ilé ìwòsàn, àwọn amòfin àti adájọ́ jákèjádò orílẹ̀-èdè Sierra Leone. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni ẹ̀jẹ̀ tó pọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í dà lára arábìnrin kan tó ń rọbí, àwọn dókítà sì kọ̀ láti tọ́jú rẹ̀, wọ́n ní àfi tó bá gbẹ̀jẹ̀ sára. Ṣùgbọ́n dókítà kan gbà láti tọ́jú rẹ̀ torí pé ó ti ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé tó bọ́gbọ́n mu nínú ìwé kékeré tó sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀jẹ̀, ìyẹn ìwé Blood. Arábìnrin náà bí ọmọkùnrin làǹtì-lanti kan, ara tiẹ̀ náà sì pa dà yá gágá.

Ní nǹkan bí ọdún 1991, Dókítà Bashiru Koroma, tó jẹ́ dókítà oníṣẹ́-abẹ ní ilé ìwòsàn Kenema Hospital ka ìwé pẹlẹbẹ tó sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀jẹ̀, ìyẹn How Can Blood Save Your Life? Ohun tó kà níbẹ̀ wú u lórí gan-an, ló bá bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ń lọ sí ìpàdé. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni jàǹbá ṣẹlẹ̀ sí ọmọkùnrin Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án, èyí sì ṣàkóbá fún ikùn rẹ̀. Àwọn dókítà tó ń tọ́jú ọmọ náà kọ̀ láti ṣe iṣẹ́ abẹ fún un, wọ́n ní àfi kó gbẹ̀jẹ̀ sára. Wọ́n sọ fún àwọn òbí ọmọ náà pé, “Ẹ máa gbé ọmọ yín lọ, kó lọ kú sílé!” Ni àwọn òbí ọmọ náà bá lọ sọ́dọ̀ Dókítà Koroma, ó sì ṣe iṣẹ́ abẹ fún un, ara rẹ̀ sì yá.

Láìpẹ́, Dókítà Koroma di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó sì ń gbèjà ìtọ́jú ìṣègùn lójú méjèèjì láìlo ẹ̀jẹ̀. Nítorí èyí, àwọn dókítà yòókù ta á nù, àmọ́ ńṣe ni ara àwọn aláìsàn tó ń wá gba ìtọ́jú lọ́dọ̀ rẹ̀ ń yá gágá. Nígbà tó yá, àwọn dókítà bíi tiẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í lọ gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ rẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe lè ṣe iṣẹ́ abẹ tó díjú gan-an.

Láti ọdún 1994 ni Ẹ̀ka Tó Ń Pèsè Ìsọfúnni fún Àwọn Ilé Ìwòsàn láti ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní ìlú Freetown ti yan àwọn Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn ní orílẹ̀-èdè Sierra Leone àti Guinea. Àwọn ìgbìmọ̀ yìí máa ń ran àwọn Ẹlẹ́rìí tó bá ń ṣàìsàn lọ́wọ́ tìfẹ́tìfẹ́, wọ́n sì ti yí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn oníṣègùn lérò pa dà kí wọ́n lè máa fara mọ́ ìpinnu wa lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́