SIERRA LEONE ÀTI GUINEA
2002 sí 2013 Ohun Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Láwọn Ọdún Àìpẹ́ Yìí (Apá Kejì)
A Ran Àwọn Adití Lọ́wọ́
Àwọn kan fojú bù ú pé nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] sí ẹgbẹ̀rún márùn-ún [5,000] èèyàn ní orílẹ̀-èdè Sierra Leone àti ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn ní orílẹ̀-èdè Guinea ló jẹ́ adití. Níwọ̀n bó ti jẹ́ ìfẹ́ Jèhófà pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là,” báwo ni àwọn adití ṣe máa gbọ́ ìhìn rere?—1 Tím. 2:4.
Arábìnrin Michelle Washington, tó jẹ́ míṣọ́nnárì láti ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì, wá sí Sierra Leone lọ́dún 1998. Ó sọ pé: “Ètò Ọlọ́run fi èmi àti Kevin ọkọ mi sí ìjọ kan tí adití mẹ́rin wà. Torí pé mo lè fi Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà bá àwọn adití sọ̀rọ̀, mo fẹ́ láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Ẹ̀ka ọ́fíìsì ní kí n máa túmọ̀ àwọn ìpàdé àti àpéjọ wa fún àwọn adití, wọ́n sì sọ fún àwọn ìjọ tó wà nítòsí nípa ètò tí wọ́n ṣe yìí. Ẹ̀ka ọ́fíìsì sì tún ṣètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn akéde tó fẹ́ kọ́ èdè àwọn adití kí wọ́n lè máa fi ran àwọn adití lọ́wọ́. A wá bẹ̀rẹ̀ sí í wá àwọn adití kàn ní àgbègbè ibẹ̀, a sì ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tí ọ̀pọ̀ èèyàn ibẹ̀ ń rí akitiyan tá a ń ṣe láti ran àwọn adití lọ́wọ́, wọ́n yìn wá. Àmọ́, inú gbogbo èèyàn kọ́ ló dùn sí ohun tí à ń ṣe. Pásítọ̀ kan tó ń ṣèrànwọ́ fún àwọn adití sọ pé ‘wòlíì èké’ ni wá. Ó sì kìlọ̀ fún wọn pé kí àwọn àti ìdílé wọn máa yàgò fún wa. Ó sọ fún àwọn míì pé tí wọ́n bá tún rí wọn lọ́dọ̀ wa, owó ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n ń rí gbà parí nìyẹn. Bí àwọn adití tó wà ládùúgbò yẹn ṣe pín sí méjì nìyẹn o. Apá kan jẹ́ àwọn tí kò mọ̀ wá, tí wọ́n fara mọ́ ohun tí Pásítọ̀ ń sọ, apá kejì ni àwọn tó mọ̀ wá, tí wọn kò fara mọ́ ohun tí Pásítọ̀ náà ń sọ. Àwọn kan lára àwọn tó mọ̀ wá tí wọ́n sì fara mọ́ ohun tí a ń ṣe dúró nínú òtítọ́, wọ́n kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n sì ṣèrìbọmi.”
Àpẹẹrẹ kan ni ti Femi. Adití àti odi ni wọ́n bí i, ìwọ̀nba ìfaraṣàpèjúwe díẹ̀ ló sì mọ̀ tó fi lè báni sọ̀rọ̀. Gbogbo èèyàn ló máa ń fura sí, pàápàá àwọn tí kì í ṣe adití. Inú rẹ̀ kì í dùn, ó sì gbà pé kò sẹ́ni tó fẹ́ràn òun. Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn ará tó wà ní àwùjọ àwọn tó ń sọ èdè adití. Kò sì pẹ́ tó fi ń lọ sí ìpàdé déédéé, ó sì ń kọ́ èdè àwọn adití. Femi tẹ̀ síwájú, ó sì ṣe ìrìbọmi. Ní báyìí, ó ń fi tayọ̀tayọ̀ kọ́ àwọn adití míì ní ẹ̀kọ́ òtítọ́.
Femi rèé (lápá ọ̀tún pátápátá) tó ń kọrin Ìjọba Ọlọ́run
Ní July 2010, àwùjọ tó ń sọ Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà ní ìlú Freetown di ìjọ. Àwọn àwùjọ tó ń sọ èdè adití sì tún wà ní ìlú Bo àti Conakry.
Tálákà Ni Wọ́n Àmọ́ Wọ́n Jẹ́ “Ọlọ́rọ̀ Nínú Ìgbàgbọ́”
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé tálákà ni èyí tó pọ̀ jù lára àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ pé: “Ọlọ́run yan àwọn tí í ṣe òtòṣì ní ti ayé láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú ìgbàgbọ́ . . . àbí kò ṣe bẹ́ẹ̀?” (Ják. 2:5) Bákan náà, ìgbàgbọ́ tí àwọn akéde orílẹ̀-èdè Sierra Leone àti Guinea ní nínú Jèhófà ń fún wọn ní ìtùnú àti ìrètí.
Ìgbàgbọ́ ló mú kí ọ̀pọ̀ ìdílé Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ tálákà, tí wọ́n ń gbé ní àdádó, máa fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù tọ́jú owó pa mọ́ kí wọ́n lè fi wọkọ̀ lọ sí àpéjọ àgbègbè. Àwọn ẹlòmíì máa ń dìídì dáko, wọ́n á fi owó tí wọ́n bá pa níbẹ̀ bójú tó ìrìn àjò náà. Àwọn bí ogún sí ọgbọ̀n máa ń fún ara wọn mọ́ inú ooru nínú ọkọ̀ akẹ́rù, wọ́n á fi odidi ogún wákàtí tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ rìnrìn àjò lọ sí àpéjọ lójú ọ̀nà eléruku tó kún fún kòtò àti gegele. Àwọn míì sì máa ń fẹsẹ̀ rin ọ̀nà tó jìn. Arákùnrin kan sọ pé: “A kọ́kọ́ fẹsẹ̀ rin ọgọ́rin [80] kìlómítà, a sì gbé ẹrù ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹ́wẹ́ tó pọ̀ gan-an. A ta àwọn ọ̀gẹ̀dẹ̀ náà lójú ọ̀nà láti dín ẹrù wa kù, ká sì lè rí owó tó pọ̀ tó láti fi wọkọ̀ akẹ́rù tó máa gbé wa dé àpéjọ.”
Ọkọ̀ akẹ́rù ń gbé àwọn ará lọ àpéjọ àgbègbè
Ìgbàgbọ́ tí ọ̀pọ̀ akéde ní sì mú kí wọ́n pinnu pé bó ti wù kí ìlú le tó àwọn kò ní torí ìyẹn ṣí lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù. Emmanuel Patton tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Àpọ́n sọ pé: “Ó dá wa lójú pé Jèhófà máa pèsè àwọn ohun tá a nílò. Torí pé orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i là ń gbé, a sì rí i pé iṣẹ́ ìsìn wa wúlò gan-an níbí.” (Mát. 6:33) Alàgbà ni Emmanuel báyìí, òun àti aya rẹ̀ Eunice sì ń bá iṣẹ́ ìsìn Jèhófà lọ lójú méjèèjì. Ìdí tí àwọn olórí ìdílé míì kò fi ṣí lọ ni pé wọ́n fẹ́ kí ìdílé wọn wà pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan, kí wọ́n sì jọ máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Arákùnrin Timothy Nyuma tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe àti adelé alábòójútó àyíká sọ pé: “Mi ò ṣe iṣẹ́ tó bá máa mú kí n jìnnà sí ìdílé mi fún àkókò gígùn. Èmi àti Florence ìyàwó mi ní kí àwọn ọmọ wa kàwé ní àgbègbè ibi tí a wà dípò ká lọ kó wọn ti àwọn ẹlòmíì.”
Àwọn ará wa míì ṣe ohun tó fi hàn pé wọ́n ní ìgbàgbọ́, wọ́n ń bá àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni lọ lójú méjèèjì láìka onírúurú ìṣòro sí. Arákùnrin Kevin Washington tá a mẹ́nu kàn ṣáájú sọ pé: “Ọ̀pọ̀ akéde ló máa ń jáde òde ẹ̀rí déédéé, wọ́n sì ń bójú tó ojúṣe tí wọ́n ní nínú ìjọ dáadáa lójú àwọn ìṣòro tó lè mú kí àwa ní tiwa borí mọ́lé ká sì máa kanra. Bí àpẹẹrẹ, àìsàn tí kì í lọ bọ̀rọ̀ ń ṣe àwọn kan, wọn kì í sì í rí ìtọ́jú tàbí àwọn oògùn tó máa ń wà lárọ̀ọ́wọ́tó láwọn ibòmíì. Ṣe làwọn míì sì ń sa gbogbo ipá wọn kí wọ́n tó lè mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà. Tí mo bá fẹ́ máa ṣàríwísí nípa bí arákùnrin kan ṣe ṣiṣẹ́ rẹ̀, mo máa ń bi ara mi pé: ‘Tó bá jẹ́ pé mò ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ láti àárọ̀ ṣúlẹ̀, tí àìsàn tó le tún ń bá mi fínra, tí ojú mi ò fi bẹ́ẹ̀ ríran dáadáa tí mi ò sì ní ìgò ojú, tí mi ò fi bẹ́ẹ̀ ní ìwé ètò Ọlọ́run nílé, kò sì sí iná mànàmáná nílé mi, ṣé màá tiẹ̀ lè ṣe tó tiwọn?’”
Àwọn ọ̀nà yìí àti onírúurú ọ̀nà míì làwọn ará wa ní orílẹ̀-èdè Sierra Leone àti Guinea gbà ń gbé Jèhófà ga. Bíi tàwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní làwọn náà ṣe ń dámọ̀ràn ara wọn fún ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run “nípa ìfaradà púpọ̀, nípa àwọn ìpọ́njú, nípa àwọn ọ̀ràn àìní, . . . bí òtòṣì ṣùgbọ́n tí ń sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ di ọlọ́rọ̀, bí ẹni tí kò ní nǹkan kan, síbẹ̀ a ní ohun gbogbo.”—2 Kọ́r. 6:4, 10.
Ọkàn Wa Balẹ̀ Pé Ọ̀la Ń Bọ̀ Wá Dáa
Láti ohun tó lé ní àádọ́rùn-ún [90] ọdún sẹ́yìn ni Alfred Joseph àti Leonard Blackman ti sọ pé pápá Sierra Leone ti “funfun fún kíkórè.” (Jòh. 4:35) Ní nǹkan bí ọdún márùnlélọ́gbọ̀n [35] lẹ́yìn náà, Arákùnrin Manuel Diogo kọ̀wé láti ilẹ̀ Guinea pé: “Àwọn tó fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pọ̀ gan-an níbí.” Lónìí, ó dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè méjèèjì yìí lójú pé àwọn èèyàn púpọ̀ sí i ṣì máa fetí sí ìhìn rere.
Lọ́dún 2012, ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àti mọ́kàndín ní ọ̀rìnlénírínwó [3,479] èèyàn ló wá sí Ìrántí Ikú Kristi ní ilẹ̀ Guinea. Èyí lé ní ìlọ́po mẹ́rin ààbọ̀ iye akéde tó wà lórílẹ̀-èdè náà. Àwọn ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgbọ̀n [2,030] akéde ní orílẹ̀-èdè Sierra Leone ké sí ẹgbẹ̀rún méje àti ẹgbẹ̀rin ó lé mẹ́rìnléláàádọ́ta [7,854] wá sí Ìrántí Ikú Kristi. Àwọn tó wá yìí fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ìlọ́po mẹ́rin iye àwọn akéde ibẹ̀. Aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe kan tó ń jẹ́ Winifred Remmie, ẹni ọdún mẹ́tàléláàádọ́rùn-ún [93], tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn náà wà níbi Ìrántí Ikú Kristi yìí. Ọdún 1963 lòun àti ọkọ rẹ̀ Lichfield, dé sí orílẹ̀-èdè Sierra Leone. Arábìnrin yìí ṣì ń bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe lọ lẹ́yìn ọgọ́ta [60] ọdún tó ti wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún. Arábìnrin Remmie sọ pé: “Ta ló lè lálàá rẹ̀ pé ìgbà kan máa wà tí àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí ìgbàgbọ́ wọn lágbára tí wọ́n sì pọ̀ tó báyìí máa kún orílẹ̀-èdè Sierra Leone. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti dàgbà, mo ṣì ń fẹ́ kópa nínú ìbísí tó ń múni láyọ̀ yìí.”a
Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára arábìnrin yìí náà ló ṣe rí lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè Sierra Leone àti Guinea. Bí àwọn igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ létí odò, tó ń so èso déédéé, làwọn náà ṣe pinnu láti máa bá a nìṣó ní síso èso tó ń gbé Jèhófà ga. (Sm. 1:3) Lọ́lá agbára tí Jèhófà ń fúnni, wọ́n á máa bá a lọ láti polongo ojúlówó ìrètí òmìnira tí aráyé ní, ìyẹn “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.”—Róòmù 8:21.
Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka, láti apá òsì sí ọ̀tún: Collin Attick, Alfred Gunn, Tamba Josiah àti Delroy Williamson
a Arábìnrin Winifred Remmie kú nígbà tí à ń kọ ìtàn yìí lọ́wọ́.