Ìṣòro Àìríṣẹ́ṣe
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ITALI
Ọ̀ràn pàjáwìrì tí ń wá ojútùú ni ó jẹ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè bíi mélòó kan tí wọ́n ti gòkè àgbà—ṣùgbọ́n ó ń da àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà láàmú pẹ̀lú. Ó ti ya bo ibi tí ó jọ pé kò sí tẹ́lẹ̀ rí. Ó kan àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún ènìyàn—tí ọ̀pọ̀ lára wọn jẹ́ ìyá àti bàbá. Fún ìdá méjì nínú mẹ́ta gbogbo àwọn ará Itali, òun ni “olórí awuniléwu.” Ó ń ṣokùnfà àwọn ìṣòro tuntun láàárín ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà. Lápá kan, òun ni gbòǹgbò àwọn ìṣòro tí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tí ń kó wọnu àṣà lílo oògùn líle ń ní. Kì í jẹ́ kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn sùn, ó sì lè di ìṣòro fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn mìíràn láìpẹ́ . . .
ÈTÒ Àjọ Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti Ìdàgbàsókè Ọrọ̀ Ajé (OECD) sọ pé: “Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé àìríṣẹ́ṣe ni ohun àrà tí a ń bẹ̀rù jù lọ lákòókò wa.” Ìgbìmọ̀ Amúṣẹ́ṣe Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Europe kọ̀wé pé: “A mọ ibi tí ohun àrà yìí ti dé àti àbáyọrí rẹ̀,” ṣùgbọ́n “ó ṣòro gan-an láti kojú rẹ̀.” Ògbógi kan sọ pé, ó jẹ́ “àǹjọ̀nnú tí ń padà wá sí òpópónà Ògbólógbòó Kọ́ńtínẹ́ǹtì náà léraléra.” Ní Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Europe (EU), àwọn tí wọn kò ríṣẹ́ ṣe ti di nǹkan bí 20 mílíọ̀nù báyìí, àti ní October 1994, iye wọn wọ 2,726,000 ní Itali nìkan. Ní ti alábòójútó Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Europe náà, Padraig Flynn, “yíyanjú ìṣòro àìríṣẹ́ṣe ni ìpèníjà tí ó ṣe pàtàkì jù lọ tí a dojú kọ ní ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà àti ti ètò ọrọ̀ ajé.” Bí o kò bá níṣẹ́ lọ́wọ́ tàbí tí o wà nínú ewu pípàdánù iṣẹ́ rẹ, ìwọ yóò mọ irú ìbẹ̀rù tí ó máa ń mú wá.
Ṣùgbọ́n kì í ṣe ilẹ̀ Europe nìkan ni ó ní ìṣòro àìríṣẹ́ṣe. Ó ń pọ́n gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè America lójú. Kò yọ ilẹ̀ Áfíríkà, Asia, tàbí Oceania sílẹ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè ìhà ìlà oòrùn Europe ti ń mọ̀ ọ́n lára ní àwọn ọdún ẹnu àìpẹ́ yìí. Lótìítọ́, bákan náà kọ́ ni ó rí níbi gbogbo. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí àwọn onímọ̀ ètò ọrọ̀ ajé kan ti sọ, ìwọ̀n àìríṣẹ́ṣe ní ilẹ̀ Europe àti Àríwá America yóò máa ga sí i fún ìgbà pípẹ́ ju bí ó ti rí ní àwọn ẹ̀wádún tí ó ti kọjá.a Onímọ̀ ètò ọrọ̀ ajé Renato Brunetta sọ pé, ipò náà “ń burú sí i nítorí ìlọsókè àbọ̀ọ̀ṣẹ́ àti ìjórẹ̀yìn nínú bí iṣẹ́ tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ṣe gbámúṣe tó.”
Ìlọsókè Tí Kò Lẹ́rọ̀
Àìríṣẹ́ṣe ti kọlu gbogbo ẹ̀ka ètò ọrọ̀ ajé níkọ̀ọ̀kan: àkọ́kọ́ ni iṣẹ́ àgbẹ̀, pẹ̀lú ìmọ̀ ẹ̀rọ rẹ̀ tí ń ga sí i, tí ń sọ àwọn ènìyàn di aláìríṣẹ́ṣe; lẹ́yìn náà ni ilé iṣẹ́, tí rògbòdìyàn ohun àmúṣagbára ti ń ní ipa lórí rẹ̀ láti àwọn ọdún 1970 wá; àti ní báyìí, iṣẹ́ ọpọlọ—ìṣòwò, ìmọ̀ ẹ̀kọ́—ẹ̀ka tí a kà sí èyí tí kò lè níṣòro tẹ́lẹ̀ rí. Ní 20 ọdún sẹ́yìn, bí ìwọ̀n àìríṣẹ́ṣe bá pọ̀ tó ìpín 2 tàbí ìpín 3 nínú ọgọ́rùn-ún, yóò fa ìrúkèrúdò ńlá. Lónìí, orílẹ̀-èdè onílé iṣẹ́ ẹ̀rọ kan yóò kà á sí pé òún kẹ́sẹ járí bí àìríṣẹ́ṣe níbẹ̀ kò bá tó ìpín 5 tàbí ìpín 6 nínú ọgọ́rùn-ún, ọ̀pọ̀ lára àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti gòkè àgbà ní ìwọ̀n tí ó túbọ̀ pọ̀ ju ìyẹn lọ.
Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Àwọn Òṣìṣẹ́ Káàkiri Àwọn Orílẹ̀-Èdè (ILO) ti sọ, ẹnì kan tí kò ríṣẹ́ ṣe ni ẹni tí kò ní iṣẹ́ lọ́wọ́, tí ó ṣe tán láti ṣiṣẹ́, tí ó sì ń wá iṣẹ́ lójú méjèèjì. Ṣùgbọ́n ti ẹni tí kò ní iṣẹ́ alákòókò kíkún kan pàtó tàbí ẹni tí ń gbìyànjú láti ṣiṣẹ́ fún kìkì wákàtí díẹ̀ péré láàárín ọ̀sẹ̀ ńkọ́? Ojú tí ó yàtọ̀ síra ni a fi ń wo àbọ̀ọ̀ṣẹ́ láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn. Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn tí wọn kò ríṣẹ́ ṣe ní ti gidi ni àwọn ìjọba ti kà sí ẹni tí ó ti ríṣẹ́. Àwọn ipò tí kò ṣe pàtó tí ó wà láàárín ìríṣẹ́ṣe àti àìríṣẹ́ṣe ń mú kí ó ṣòro láti pinnu ẹni tí kò ríṣẹ́ ṣe ní ti gidi, nítorí ìdí yìí, àkọsílẹ̀ ṣàpèjúwe kìkì apá kan òkodoro ọ̀ràn náà. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní ilẹ̀ Europe sọ pé: “Kódà mílíọ̀nù 35 iye àwọn aláìríṣẹ́ṣe, tí àwọn ìjọba gbé jáde, [pé ó wà ní àwọn orílẹ̀-èdè OECD] kò fi àyè tí àìríṣẹ́ṣe dé hàn ní kíkún.”
Iye Gíga Tí Àìríṣẹ́ṣe Ń Náni
Ṣùgbọ́n nọ́ḿbà náà kò sọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ náà. Ìgbìmọ̀ Amúṣẹ́ṣe Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Europe sọ pé: “Ohun tí àìríṣẹ́ṣe ń náni ní ti ọrọ̀ ajé àti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà pọ̀ jọjọ,” wọn “kì í sì í ṣe látàrí owó tí a ń ná sórí ìtìlẹ́yìn fún àwọn aláìríṣẹ́ṣe gan-an ṣùgbọ́n látàrí àdánù nínú àròpọ̀ owó tí ń wọlé nípasẹ̀ owó orí sísan, tí àwọn aláìríṣẹ́ṣe ì bá ti san nínú rẹ̀ ká sọ pé wọ́n ń ríṣẹ́ kan ṣe ni.” Owó tí a sì fi ń ṣètìlẹ́yìn fún àwọn aláìríṣẹ́ṣe túbọ̀ ń di ẹrù ìnira sí i, kì í ṣe fún àwọn ìjọba nìkan, ṣùgbọ́n fún àwọn tí wọ́n ríṣẹ́ ṣe pẹ̀lú, tí wọ́n ń san owó orí gíga.
Àìríṣẹ́ṣe kì í ṣe ọ̀ràn ìsọfúnni oníṣirò àti nọ́ḿbà nìkan. Àwọn ọ̀ràn ìṣẹ̀lẹ̀ kọ̀ọ̀kan ni àbáyọrí rẹ̀, nítorí pé ìṣòro yìí ń bá àwọn ènìyàn fínra—àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn èwe ní gbogbo ipò ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà. Bí a bá pa ìṣòro àìríṣẹ́ṣe pọ̀ mọ́ gbogbo àwọn ìṣòro “awọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ó lè jẹ́ ẹrù ìnira kíkàmàmà. (2 Timoteu 3:1-5; Ìṣípayá 6:5, 6) Ní pàtàkì bí “àìríṣẹ́ṣe fún àkókò gígùn” bá kọ luni, tí kò bá sí ọ̀ràn mìíràn tí ó fara gbún un, yóò túbọ̀ ṣòro fún ẹni tí ó ti pẹ́ tí ó ti ṣiṣẹ́ gbẹ̀yìn láti rí iṣẹ́, ju fún ẹni tí kò pẹ́ tí ó ti ṣiṣẹ́ gbẹ̀yìn lọ. Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn kan lè máà rí iṣẹ́ mìíràn ṣe mọ́ rárá páàpáà.b
Àwọn afìṣemọ̀rònú ṣàwárí pé àwọn ìṣòro ọpọlọ àti ìrònú ń pọ̀ sí i láàárín àwọn tí wọn kò ríṣẹ́ ṣe lónìí, bẹ́ẹ̀ náà sì ni èrò ìmọ̀lára tí kò dúró sójú kan, ìjákulẹ̀, ìsoríkọ́ tí kò dáwọ́ dúró, àti ìpàdánù ọ̀wọ̀ ara ẹni. Nígbà tí ẹnì kan tí ó ní àwọn ọmọ láti pèsè fún bá pàdánù iṣẹ́, ìṣòro àdání líle koko gbáà ni. Ayé ti dojú rú. Ààbò wọn ti pòórá. Ní ti gidi, lónìí, àwọn ògbógi kan ṣàkíyèsí ìyọjú “àníyàn fífojú sọ́nà fún nǹkan” tí ó jẹ mọ́ ìṣeéṣe ti pípàdánù iṣẹ́ ẹni. Àníyàn yìí lè ní ipa lílágbára lórí ipò ìbátan ìdílé, ó sì lè ní àwọn ìyọrísí tí ó túbọ̀ léwu, bí ìṣekúpara-ẹni láàárín àwọn tí wọn kò ríṣẹ́ ṣe ti lè fi hàn. Síwájú sí i, ìṣòro ti rírí iṣẹ́ àkọ́kọ́ ẹni wà lára àwọn ohun tí ó ṣeé ṣe kí ó máa ṣokùnfa ìwà ọ̀daràn àti kí àwọn ọ̀dọ́ máa ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò láàárín àwọn ẹgbẹ́ wọn.
‘Àwọn Tí Ètò Ìgbékalẹ̀ Àìtọ́ Dì Nígbèkùn’
Jí! ti fọ̀rọ̀ wá àwọn ènìyàn bíi mélòó kan tí wọ́n ti pàdánù iṣẹ́ wọn lẹ́nu wò. Armando, ẹni 50 ọdún, sọ pé ní ti òun, ó túmọ̀ sí “rírí i tí ìsapá iṣẹ́ 30 ọdún ń forí ṣánpọ́n, tí òún sì tún ní láti ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀,” àti nínímọ̀lára “bí ẹni tí ètò ìgbékalẹ̀ àìtọ́ dì nígbèkùn.” Francesco ‘rí i tí ayé ń dojú rú fún òun.’ Stefano “nímọ̀lára ìjákulẹ̀ jíjinlẹ̀ nínú ètò ìgbékalẹ̀ ìgbésí ayé ìsinsìnyí.”
Ní ọwọ́ kejì, Luciano, tí a lé dànù lẹ́nu iṣẹ́ lẹ́yìn tí ó ti ṣiṣẹ́ níbi àbójútó iṣẹ́ ẹ̀rọ fún nǹkan bí 30 ọdún ní ilé iṣẹ́ pàtàkì kan tí ń ṣe ohun ìrìnnà ní Itali, “nírìírí ìbínú àti ìṣòro ọpọlọ nígbà tí ó rí i pé àwọn ìsapá, ìwà ìṣòtítọ́, àti ìwà ìṣeégbẹ́kẹ̀lé òun ní gbogbo ọ̀pọ̀ ọdún tí ó ti fi ṣiṣẹ́ ni a kò kà sí ohun tí ó já mọ́ nǹkan kan.”
Àwọn Ìsọtẹ́lẹ̀ àti Ìjákulẹ̀
Àwọn onímọ̀ ètò ọrọ̀ ajé kan ti fojú sọ́nà fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó yàtọ̀ síra. Ní 1930, onímọ̀ ètò ọrọ̀ ajé John Maynard Keynes sàsọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú ìfojúsọ́nà fún rere pé “iṣẹ́ yóò wà fún gbogbo ènìyàn” láàárín 50 ọdún tí ó tẹ̀ lé e, iṣẹ́ alákòókò kíkún ni a sì ti kà sí góńgó tí ó ṣeé lé bá fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún. Ní 1945, Òfin ètò àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè gbé ọ̀ràn rírí iṣẹ́ alákòókò kíkún láìjáfara kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí góńgó kan. Títí di ẹnu àìpẹ́ yìí ni a gbà gbọ́ pé ìtẹ̀síwájú yóò túmọ̀ sí iṣẹ́ àti lílo ìwọ̀nba àkókò díẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́. Ṣùgbọ́n nǹkan kò tí ì rí bẹ́ẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ètò àjọ ILO ti sọ, ìlọsílẹ̀ ọrọ̀ ajé tí ó ṣẹlẹ̀ ni ẹ̀wádún tí ó kọjá ti fa “yánpọnyánrin iṣẹ́ tí ó burú jù lọ yíká ayé láti àkókò Ìjórẹ̀yìn Ọ̀rọ̀ Ajé Ńlá tí ó ṣẹlẹ̀ ní àwọn ọdún 1930.” Ní Gúúsù Áfíríkà, ó kéré tán mílíọ̀nù 3.6 ènìyàn ni kò níṣẹ́ lọ́wọ́, pẹ̀lú nǹkan bíi mílíọ̀nù 3 àwọn adúláwọ̀ ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà. Kódà Japan—tí ó ní àwọn tí wọn kò níṣẹ́ lọ́wọ́ tí iye wọ́n lé ní mílíọ̀nù méjì lọ́dún tó kọjá—wà nínú yánpọnyánrin kan báyìí.
Kí ló dé tí àìríṣẹ́ṣe fi jẹ́ irú ìṣòro tí ó gbalẹ̀ kan bẹ́ẹ̀? Àwọn ojútùú wo ni a ti dábàá láti lè yanjú rẹ̀?
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwọ̀n àìríṣẹ́ṣe ni ìpín ọrún àròpọ̀ àwọn tí wọ́n tóótun láti ṣiṣẹ́ ṣùgbọ́n tí wọn kò ríṣẹ́ ṣe.
b Àwọn “aláìríṣẹ́ṣe fún àkókò gígùn” ni àwọn tí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ wọn fún ohun tí ó lé ní oṣù 12. Nínú ètò àjọ EU, nǹkan bí ìdajì lára àwọn tí wọn kò ríṣẹ́ ṣe ni wọ́n wà lábẹ́ ìsọ̀rí yìí.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 2, 3]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Kánádà—Ìpín 9.6 nínú ọgọ́rùn-ún
U.S.A.—Ìpín 5.7 nínú ọgọ́rùn-ún
Colombia—Ìpín 9 nínú ọgọ́rùn-ún
Ireland—Ìpín 15.9 nínú ọgọ́rùn-ún
Spain—Ìpín 23.9 nínú ọgọ́rùn-ún
Finland—Ìpín 18.9 nínú ọgọ́rùn-ún
Albania—Ìpín 32.5 nínú ọgọ́rùn-ún
Gúúsù Áfíríkà—Ìpín 43 nínú ọgọ́rùn-ún
Japan—Ìpín 3.2 nínú ọgọ́rùn-ún
Philippines—Ìpín 9.8 nínú ọgọ́rùn-ún
Australia—Ìpín 8.9 nínú ọgọ́rùn-ún
[Credit Line]
Mountain High Maps™ copyright © 1993 Digital Wisdom, Inc.