ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 9/22 ojú ìwé 24-25
  • Ìdè Àárín Ìyá àti Àwọn Ìkókó Rẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìdè Àárín Ìyá àti Àwọn Ìkókó Rẹ̀
  • Jí!—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1997
  • “Mi Ò Rí Irú Ìfẹ́ Báyìí Rí”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • “Èmi Ti Pa Ìgbàgbọ́ Mọ́”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Èèyàn Bíi Sárà
    Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2016
Jí!—1996
g96 9/22 ojú ìwé 24-25

Ìdè Àárín Ìyá àti Àwọn Ìkókó Rẹ̀

Ó WULẸ̀ jẹ́ ológbò ọlọ́mọ márùn-ún tí ó ti ṣako lọ, tí irun ara rẹ̀ kò gùn, tí kò sì lórúkọ, tí ó ń tiraka láti máa wà láàyè nìṣó ní àwọn òpópó wúruwùru Ìlà Oòrùn New York. Ó ti múlé sí àwókù ilé ìtọ́kọ̀ṣe kan tí a ti pa tì, tí iná tí ń funi lára ti jó kọjá lọ́pọ̀ ìgbà. Ó máa ń wá èérún oúnjẹ kiri àdúgbò kí ó lè máa bọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà.

Gbogbo èyí fẹ́rẹ̀ẹ́ yí padà ní nǹkan bí agogo 6:06 òwúrọ̀ March 29, 1996. Iná afunilára kan mú ilé ìtọ́kọ̀ṣe náà kíákíá. Ibùgbé ìdílé ológbò náà gbiná. Ẹ̀ka iṣẹ́ panápaná Ladder Company 175 yára bẹ̀rẹ̀ sí í pa iná náà, wọ́n sì pa á tán láìpẹ́. Ọ̀kan lára àwọn panápaná náà, David Giannelli, gbọ́ igbe àwọn ọmọ ológbò náà. Ó bá mẹ́ta lára wọn gẹ́rẹ́ ní ìta ilé náà, òmíràn wà ní ìdá mẹ́ta nínú mẹ́rin ọ̀nà tí ó kọjá sí òdì kejì títì, ẹ̀karùn-ún sì wà ní ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀ létí títì náà. Àwọn ọmọ ológbò náà kéré jù láti dá sá là fúnra wọn. Giannelli kíyè sí i pé, bí iná ṣe jó àwọn ọmọ ológbò náà pawọ́ léra, nítorí àwọn kan ti pẹ́ níbẹ̀ bí ìyá wọn ṣe ń gbé wọn jáde lọ́kọ̀ọ̀kan.

Ìròyìn náà nínú ìwé agbéròyìnjáde Daily News ti New York, ti April 7, 1996, fúnni ní ìròyìn yìí nípa ìrewárẹ̀yìn àti àbójútó ìyá náà pé: “Giannelli rí màmá náà níbi tí ó wó sí nínú ìrora níbi àyè ṣíṣófo kan, ìran náà sì bà á lọ́kàn jẹ́. Èéfín ti mú kí ìpéǹpéjú ológbò náà wú bò. Àwọn awọ ẹsẹ̀ rẹ̀ jóná púpọ̀. Àwọn àpá iná ẹlẹ́rù jẹ̀jẹ̀ wà ní ojú, etí àti ẹsẹ̀ rẹ̀. Giannelli wá àpótí kan tí a fi bébà nínípọn ṣe. Ó rọra gbé màmá ológbò náà àti àwọn ọmọ rẹ̀ sínú rẹ̀. Giannelli sọ pé: ‘Kò tilẹ̀ lè lajú rárá. Ṣùgbọ́n ó fọwọ́ bà wọ́n lọ́kọ̀ọ̀kan, ó kà wọ́n.’”

Nígbà tí wọ́n fi dé ibi ìtọ́jú ẹranko ti North Shore Animal League, ipò náà ṣòro láti pinnu. Ìròyìn náà ń bá a lọ pé: “Wọ́n lo àwọn egbòogi ìgbógun ti ìpayà. Wọ́n lo túùbù oògùn agbógunti kòkòrò àrùn fún akíkanjú ológbò náà. Wọ́n tún rọra fi àwọn ìpara oògùn agbógunti kòkòrò àrùn pa àwọn ibi tí ó ti fara jóná. Wọ́n wáá gbé e sínú àgò àgbá afẹ́fẹ́ oxygen kan tí yóò jẹ́ kí ó lè máa mí dáradára nígbà tí gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ibi ìtọ́jú ẹranko náà ń wòye ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ . . . Láàárín wákàtí 48, akọni abo ológbò náà ti jókòó sára. Àwọn ojú rẹ̀ tí ó wú ti là, àwọn dókítà kò sì rí ìpalára kankan.”

Dúró kí o sì ronú ná. Lo àkókò díẹ̀ láti fojú inú yàwòrán ìyá onígboyà yìí, pẹ̀lú ẹ̀rù àdánidá rẹ̀ fún iná, bí ó ti ń wọ inú ilé tí ń jóná, tí èéfín kún inú rẹ̀ náà lọ, láti gba àwọn ọmọ rẹ̀ tí ń kígbe là. Láti sọ pé ó wọ inú rẹ̀ lọ lẹ́ẹ̀kan láti kó àwọn ọmọ rẹ̀ wẹ́wẹ́ tí kò lè dá ta pútú ṣòroó gbà gbọ́; láti ṣe é nígbà márùn-ún, pẹ̀lú ìrora àfikún ìjóná ní ẹsẹ̀ àti ojú rẹ̀ nígbà kọ̀ọ̀kan kò ṣeé lóye! Wọ́n sọ ẹranko ònígboyà náà ní Scarlett, nítorí pé iná tí ó jó o fi hàn pé àwọ̀ rírẹ̀ dòdò, tàbí àwọ̀ pupa ni awọ tí ó wà nísàlẹ̀ ara rẹ̀.

Nígbà tí wọ́n yára gbé ìtàn wíwọni lọ́kàn yìí, nípa ìdè àárín ìyá àti àwọn ìkókó rẹ̀ jáde fáráyé láti ibi ìtọ́jú ẹranko ti North Shore Animal League, àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í tẹni láago láìdáwọ́ dúró. Ó lé ní 6,000 ènìyàn láti àwọn ibi jíjìnnà tó Japan, Netherlands, àti Gúúsù Áfíríkà tí wọ́n tẹni láago láti wádìí ipò tí Scarlett wà. Nǹkan bí 1,500 ti gbà láti gba Scarlett àti àwọn ọmọ rẹ̀ tọ́jú. Ọ̀kan lára àwọn ọmọ náà kú lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.

Scarlett ṣe ohun tó wọ àwọn ènìyàn jákèjádò ayé lọ́kàn. Ó mú ọ ṣe kàyéfì bóyá àpẹẹrẹ ìdè àárín ìyá àti àwọn ìkókó rẹ̀ tí Scarlett fi lélẹ̀ kò ní í da ọkàn àwọn àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ìyá tí ń pa àwọn ọmọ wọn nínú ọlẹ̀ tàbí tí ń pa wọ́n láípẹ́ sí ìgbà tí wọ́n bí wọn, nípa lílò wọ́n nílòkulò, láàmú.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 24]

North Shore Animal League

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́