Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Àkókò Ìṣefàájì Mo gbà pé ọ̀pọ̀ ọ̀nà tí kò léwu ló wà fún àwọn ọ̀dọ́ láti gbádùn ara wọn, bí ẹ ṣe mẹ́nu bà á nínú àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ní Àkókò Ìṣefàájì?” (September 22, 1996) A lè lọ sí ibi ìkóhun ìṣẹ̀ǹbáyé sí tàbí ọgbà ẹranko tàbí kí a ṣe ìjáde fàájì tàbí àpèjẹ pàápàá. Kódà, àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ lówó nínú wa lè gbádùn ara wọn nípa pípe àwọn èwe mìíràn wá sílé wọn, kí wọ́n wá ṣe eré àṣedárayá tàbí kí wọ́n wá jẹun.
V. A., Brazil
Akọni Ológbò Ó yẹ kí n jẹ́ kí ẹ mọ bí mo ti mọyì àpilẹ̀kọ náà, “Ìdè Àárín Ìyá àti Àwọn Ìkókó Rẹ̀,” tí ó wà nínú ìtẹ̀jáde September 22, 1996, tó. Mo ń gbé orílẹ̀-èdè kan níbi tí kò ti sí ìkálọ́wọ́kò lórí àṣà ìbálòpọ̀, tí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́bìnrin kì í sì í lọ́ra láti ṣẹ́yún. Mo gbà gbọ́ pé ìyá ológbò tí a sọ ní Scarlett náà jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà, ní ti ìyá kan tí ẹ̀rí ọkàn ń ṣamọ̀nà rẹ̀.
E. B., Mali
Kíka ìtàn Scarlett, tí ó fi àìṣojo hàn ní gbígba àwọn ọmọ rẹ̀ là nínú ilé ìtọ́kọ̀ṣe kan tí ń jóná wú mi lórí. Ó wọ̀ mí lọ́kàn pé ọ̀pọ̀ ẹ̀dá ènìyàn lè rí ẹ̀kọ́ púpọ̀ kọ́ lára ológbò náà. Mo ro pé títẹ̀ tí ẹ ń tẹ irú àpilẹ̀kọ bẹ́ẹ̀ jáde ga lọ́lá.
D. W., Germany
Ìtàn amọ́kànyọ̀ tí ẹ kọ nípa Scarlett àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni àpilẹ̀kọ tí ó múni lọ́kàn jù lọ tí mo tí ì kà rí nípa ìṣẹ́yún.
J. G., United States
Mo ṣomi lójú nígbà tí mo ń ka àpilẹ̀kọ náà. Nígbà gbogbo ni mo ti máa ń fẹ́ràn onírúurú ẹranko, tí mo sì mọyì àwọn ẹ̀kọ́ tí Jèhófà ń kọ́ wa nípasẹ̀ wọn. Ó bà mí nínú jẹ́ láti mọ̀ pé àwọn ẹ̀dá ènìyàn “onílàákàyè” kì í fi irú ìbìkítà àti àfiyèsí kan náà hàn fún àwọn ọmọ wọn.
C. C., United States
Etí Híhó Ẹ ṣeun gan-an fún àpilẹ̀kọ náà, “Etí Híhó—Ariwo Tí A Óò Máa Mú Mọ́ra Ni Bí?” (September 22, 1996) Ó ti di ọdún mẹ́fà tí ó ti ń yọ mí lẹ́nu. Mo ń bẹ̀rù pé àrùn tí kò gbóògùn kan ló ń ṣe mí, nítorí pé kò sí dókítà kan tí ó tí ì lè sọ orúkọ àrùn tó ń ṣe mí fún mi. Kíka àpilẹ̀kọ yín ti fọkàn mi balẹ̀. Nísinsìnyí, mo ń gbìyànjú láti mú un mọ́ra, bí mo ṣe ń dúró de ayé tuntun ti Ọlọ́run, níbi tí ẹnikẹ́ni kì yóò ti máa ṣàìsàn.—Aísáyà 33:24.
C. F., Ítálì
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn tí mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìṣòro yìí. Ó ń pá mi láyà láti ronú pé n óò máa gbọ́ ariwo yìí léraléra! Àmọ́ lónìí, mo ń kọ́ láti mú etí mi tí ń pariwo mọ́ra. Mo ń fojú sọ́nà fún àkókò náà, nígbà tí, lágbára Jèhófà, etí mi yóò tún wà LÁÌPARIWO!
J. S., Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Czech
Mo ti ní àrùn etí híhó láti ọdún méjì ààbọ̀ wá, mo sì ti ṣe oríṣiríṣi àyẹ̀wò ìṣègùn, títí kan àyẹ̀wò ọpọlọ tí a ń fi ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà ṣe. Hílàhílo àti pákáǹleke ti jẹ́ ìṣòro ajánikulẹ̀ nínú ìgbésí ayé mi. Lẹ́yìn tí mo ka àpilẹ̀kọ yín, mo ń kọ́ láti mú àìsàn náà mọ́ra.
M. G. T. F., Sri Lanka
Ọkọ mi ní àrùn etí híhó. Ó tún ní ìsoríkọ́ gidigidi. Ìsọfúnni yìí ti ràn mí lọ́wọ́ láti túbọ̀ ní ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò fún un. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ariwo náà ń dà á láàmú gan-an, mo sì gbọ́dọ̀ jẹ́wọ́ pé n kò tí ì jẹ́ oníyọ̀ọ́nú tó bí ó ti yẹ. Tọkàntọkàn ni mo mọyì ọ̀nà bíbọ́gbọ́nmu tí ẹ gbà kọ àpilẹ̀kọ yìí. Ó dá mi lójú pé yóò ran ọ̀pọ̀ àwọn tí ọkọ tàbí aya wọn ní àrùn etí híhó lọ́wọ́ láti túbọ̀ lo òye.
L. F., United States