Ìsìn Wo Ni Ọlọ́run Fọwọ́ Sí?
Ó ṢENI láàánú pé ìkórìíra ìsìn tí ó wáyé ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún ní ilẹ̀ Faransé kò tán síbẹ̀. Ní ọ̀rúndún tó tẹ̀ lé e, ẹ̀tanú lílé koko fa Europe ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, nígbà tí àwọn Kátólíìkì àti àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì tún gbégbá ogun láàárín Ogun Ọlọ́gbọ̀n Ọdún (1618 sí 1648) náà. Lórúkọ Ọlọ́run, àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ Kristẹni tún sọ pípa ara wọn lọ́nà òǹrorò dọ̀tun.
Ìkórìíra àti ìpànìyàn lórúkọ ìsìn kò tí ì dáwọ́ dúró. Àwọn Kátólíìkì àti Pùròtẹ́sítáǹtì ti pa ara wọn láìpẹ́ yìí ní Ireland, àwọn mẹ́ńbà ìsìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì àti ti Roman Kátólíìkì ti ṣe bákan náà ní àgbègbè ilẹ̀ Yugoslavia tẹ́lẹ̀ rí. Bí ó sì ti lè jọ ohun tí kò ṣeé gbà gbọ́, nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní àti Èkejì, àwọn Kátólíìkì àti Pùròtẹ́sítáǹtì pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún lára àwọn mẹ́ńbà ìsìn wọn ní àwọn pápá ogun. A ha lè dá àre fún ìpànìyàn yí bí? Ojú wo ni Ọlọ́run fi wò ó?
Ìsapá Láti Dá A Láre
Ìwé náà, 1995 Britannica Book of the Year, sọ pé: “Ní 1994, onírúurú àwùjọ ènìyàn ló gbìyànjú dídá ìwà ipá láre lórúkọ ẹ̀kọ́ ìsìn.” Ní ohun tí ó lé ní 1,500 ọdún sẹ́yìn, Augustine “Mímọ́,” ọlọ́gbọ́n èrò orí, tí ó jẹ́ Kátólíìkì, gbìyànjú ohun kan tí ó jọ ìyẹn láti dá ìpànìyàn láre. Gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia ṣe sọ, òun “ni olùdásílẹ̀ àbá èrò ogun òdodo,” ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà sì sọ pé, ìrònú rẹ̀ ‘ń ní ipa ìdarí lóde òní pàápàá.’
Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì, Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì, àti Pùròtẹ́sítáǹtì ti fàyè gba ìpànìyàn lórúkọ Ọlọ́run, wọ́n tilẹ̀ ṣètìlẹ́yìn fún un. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àkọsílẹ̀ nípa àwọn ìsìn wọ̀nyí kún fún ìtàjẹ̀sílẹ̀, ti ọ̀pọ̀ àwọn ìsìn pàtàkì pàtàkì míràn jákèjádò ayé kò sàn jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nígbà náà, báwo ni o ṣe lè dá àwọn ènìyàn tí ń ṣe ìsìn tòótọ́ mọ̀?
Kì í ṣe nípa wíwulẹ̀ fetí sí ohun tí wọ́n sọ pé àwọn gbà gbọ́. Nípa ọ̀ràn yí, Jésù Kristi kìlọ̀ pé: “Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn wòlíì èké tí ń wá sọ́dọ̀ yín ní ìfẹ̀tànṣe-bí-àgùntàn ṣùgbọ́n lábẹ́lẹ̀ ọ̀yánnú ìkookò ni wọ́n. Ẹ óò dá wọn mọ̀ nípa àwọn èso wọn. . . . Igi tí ó dára yóò so èso rere ṣùgbọ́n igi jíjẹrà yóò so èso tí kò dára. . . . Igi èyíkéyìí tí kò so èso rere ni a gé lulẹ̀ a sì jù ú sínú iná.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.)—Mátíù 7:15-20, The New Jerusalem Bible.
A Fi Àwọn Èso Wọn Mọ̀ Wọ́n
Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn aláìlábòsí ti ń mọ̀ pé àwọn ìsìn ayé jẹ́ ‘igi jíjẹrà’ tí ó ti so “èso búburú,” ní pàtàkì, nípa ṣíṣonígbọ̀wọ́ àwọn ogun tí ó kún fún ìtàjẹ̀sílẹ̀. Nínú Bíbélì, a ṣàpèjúwe ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé bí aṣẹ́wó nípa tẹ̀mí kan tí a pè ní “Bábílónì Ńlá.” Bíbélì sọ pé, “nínú rẹ̀ ni a ti rí ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì àti ti àwọn ẹni mímọ́ àti ti gbogbo àwọn wọnnì tí a ti fikú pa lórí ilẹ̀ ayé.”—Ìṣípayá 17:3-6; 18:24.
Nípa bẹ́ẹ̀, dípò fífọwọ́sí àwọn ogun tí àwọn aṣáájú ìsìn ti súre fún, Ọlọ́run yóò mú ìdájọ́ ṣẹ lórí àwọn ìsìn tí wọ́n ti pànìyàn lórúkọ rẹ̀ láìpẹ́. Òun yóò ṣe èyí ní ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tí ó wí pé: “Pẹ̀lú ìgbésọnù yíyára ni a óò fi Bábílónì ìlú ńlá títóbi náà sọ̀kò sísàlẹ̀, a kì yóò sì tún rí i mọ́ láé.” Nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ amọ́kànyọ̀ yẹn bá ṣẹlẹ̀, Ọlọ́run yóò ti “mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún sórí aṣẹ́wó ńlá náà” yóò sì “gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹrú rẹ̀ lára rẹ̀.”—Ìṣípayá 18:21; 19:2.
Àwọn ènìyàn tí gbogbo ìpànìyàn tí ó ti ń ṣẹlẹ̀ lórúkọ Ọlọ́run ti rí lára lè ṣe kàyéfì bí àwọn Kristẹni bá wà, tí wọ́n ń gbé ní ìbámu gidi pẹ̀lú ohun tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Wọn yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn. Orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ ogun mọ́.” (Aísáyà 2:4, NW) Ìwọ ha mọ àwọn ènìyàn olùbẹ̀rù Ọlọ́run ní tòótọ́ kan tí wọn kì í jagun bí?
Ìsìn Tí Ọlọ́run Fọwọ́ Sí
Ìwé kan nípa ìwádìí lórí àjọṣepọ̀ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà tí ó ní àkọlé náà, “Ìsọfúnni Púpọ̀ Sí I Nípa Dídá Ìwà Ipá Láre,” tí Yunifásítì Michigan ṣe jáde, sọ pé: “Láti ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún yìí, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti mú ìdúró ‘Àìdásí-Tọ̀túntòsì Kristẹni’ aláìníwà-ipá wọn láìdábọ̀ la àwọn ogun àgbáyé ńlá méjì àti àwọn ìforígbárí ológun ti sáà ‘Ogun Tútù’ lẹ́yìn ìgbà náà já.” Ní títọ́kasí ìdí tí Àwọn Ẹlẹ́rìí fi wà ní àìdásí-tọ̀túntòsì, ìwádìí náà sọ pé: “Ẹ̀kọ́ tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń kọ́ni wá láti inú ìdánilójú ìgbàgbọ́ wọn pé Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ó ní ìmísí.”
Bẹ́ẹ̀ ni, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú Bíbélì, tí ó kọ́ni pé: “Àwọn ọmọ Ọlọ́run àti àwọn ọmọ Èṣù hàn gbangba nípasẹ̀ òkodoro òtítọ́ yìí: Olúkúlùkù ẹni tí kì í bá a lọ ní ṣíṣe òdodo kò pilẹ̀ ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀. . . . A ní láti ní ìfẹ́ fún ara wa lẹ́nì kíní kejì; kì í ṣe bíi Kéènì, ẹni tí ó . . . fikú pa arákùnrin rẹ̀.”—Jòhánù Kíní 3:10-12.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti sábà máa ń pe àfiyèsí àwọn ènìyàn sí ẹ̀bi ìtàjẹ̀sílẹ̀ àwọn ìsìn ayé. Wọ́n tún ti gba ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ Bíbélì náà sọ pé: “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀ [Bábílónì Ńlá], ẹ̀yin ènìyàn mi, bí ẹ kò bá fẹ́ ṣàjọpín pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, bí ẹ kò bá sì fẹ́ gbà lára àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀. Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ti wọ́ jọ pọ̀ títí dé ọ̀run, Ọlọ́run sì ti pe àwọn ìṣe àìṣèdájọ́ òdodo rẹ̀ wá sí ìrántí.”—Ìṣípayá 18:4, 5.
Ọ̀pọ̀ àwọn aláìlábòsí ènìyàn ní ń kọbi ara sí ìpè náà láti jáde kúrò nínú ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé. Bí gbogbo ìpànìyàn tí àwọn ènìyàn ti ṣe lórúkọ ìsìn bá ta ọ́ kìjí gan-an, a ké sí ọ láti kàn sí ẹni tí ó fún ọ ní ìwé ìròyìn yí tàbí kí o kọ̀wé sí ọ̀kan lára àwọn àdírẹ́sì tí a tò sí ojú ìwé 5. Inú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kọ́ nípa ìlérí Bíbélì nípa ayé tuntun òdodo, nínú èyí tí ogun kò ní sí mọ́.—Orin Dáfídì 46:8, 9; Pétérù Kejì 3:13.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
“Wọ́n polongo ní gbangba pé àwọn mọ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n wọ́n sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nípa àwọn iṣẹ́ wọn.” Títù 1:16