Etí Híhó—Ariwo Tí A Óò Máa Mú Mọ́ra Ni Bí?
BEETHOVEN, Goethe, tí ó jẹ́ òǹkọ̀wé ará Germany, àti Michelangelo, tí ó jẹ́ oníṣẹ́ ọnà ará Ítálì—ó ṣeé ṣe kí gbogbo wọn ti ní in rí. Ó ṣeé ṣe kí àwọn ará Íjíbítì ìgbàanì pẹ̀lú ti mọ̀ nípa rẹ̀, tí wọ́n máa tọ́ka sí àìsàn náà bí “etí tí àjẹ́ mú.” Lónìí, a ń pè é ní etí híhó, ìfojúdíwọ̀n ìpín 15 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn olùgbé ìhà Ìwọ̀ Oòrùn ayé ló sì ń ṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tàbí láìdáwọ́dúró. Nǹkan bí ẹni 5 nínú 1,000 ni ó ń pọ́n lójú lọ́nà líle koko.
Kí tilẹ̀ ni àìsàn amúnibínú yìí jẹ́? Ọ̀rọ̀ náà “tinnitus” [etí híhó] wá láti inú ọ̀rọ̀ Latin náà tinnire, “láti ró wooro,” a sì ṣàpèjúwe rẹ̀ bí “ìró inú etí tí kì í ṣe pé ohun kan láti ìta ló ń fà á.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé The Merck Manual of Diagnosis and Therapy ṣe sọ, ó lè jẹ́ “ìṣesí dídún wọnranwọnran, lílagogo, bíbú, sísúfèé, tàbí kíkùn yùnmùyùnmù tàbí kí ó jẹ́ àwọn ìró tí ó túbọ̀ díjú tí ń yàtọ̀ bí àkókò ti ń lọ. Ó lè máa wá ní ìdákúrekú, léraléra, tàbí bí ìlùkìkì.” Bí ariwo yìí ṣe ń pọ̀ tó lè jẹ́ láti orí èyí tí a ń fi agbára káká gbọ́ dé orí èyí tí ń dún sókè kíkankíkan lọ́nà tí ń ṣèdíwọ́. Ariwo kan tí ẹni tí ń ṣe kò sì lè pa ni. Ariwo tí kì í dáwọ́ dúró náà lè tipa bẹ́ẹ̀ tanná ran ọ̀pọ̀ ìyọrísí búburú: ìrora ọkàn, àwọn ìṣòro oorun, ìrora, àwọn ìṣòro ìpọkànpọ̀, àárẹ̀, àwọn ìṣòro ìbánisọ̀rọ̀pọ̀, àti ìsoríkọ́.
Kí Ní Ń Fa Àìsàn Náà?
Lẹ́yìn tí etí híhó bá ti bẹ̀rẹ̀, ẹni tí ń ṣe lè fi ojora ṣe kàyéfì nípa ohun tó ṣẹlẹ̀. Ó lè bẹ̀rù pé ọpọlọ òun ń ṣẹ̀jẹ̀, pé òún ń jìyà ìṣiṣẹ́gbòdì kan nínú ọpọlọ, tàbí pé òún ní kókó ọlọ́yún. Lọ́nà ìrìnnàkore, àìsàn líle koko kan kì í sábà fa eti híhó. Àwọn kan ń ní etí híhó lẹ́yìn tí wọ́n fi orí pa. Ọ̀jọ̀gbọ́n Alf Axelsson, ti Göteborg, Sweden, olùṣèwádìí àti ògbógi lórí etí híhó, wí fún Jí! pé: “Tí a bá lo àwọn egbòogi kan, bí aspirin jù, ó lè fa etí híhó gẹ́gẹ́ bí àbájáde búburú fún ìgbà díẹ̀.”
Bí ó ti wù kí ó rí, ní gbogbogbòò, etí híhó jẹ́ àbáyọrí ìṣiṣẹ́gbòdì kan nínú etí. Ọ̀jọ̀gbọ́n Axelsson ṣàlàyé pé: “Ìṣòro náà sábà máa ń wà lára ẹ̀yà etí inú tí a ń pè ní cochlea, tí ó ní nǹkan bí 15,000 sẹ́ẹ̀lì irun arùmọ̀lára sókè tí a ń rí nípasẹ̀ awò asọhun-kékeré-di-ńlá. Bí àwọn kan lára wọ́n bá ti bà jẹ́, wọ́n lè fi ọ̀wọ́ àwọn àmì ìmọ̀lára tí kò wà déédéé ránṣẹ́, kí wọ́n sì gbà wọ́n. Èyí ni ẹni tí ń ṣe yóò máa gbọ́ bí ariwo.”
Kí ní ń ṣokùnfà irú ìbàjẹ́ etí bẹ́ẹ̀? Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Axelsson ti sọ, ohun kan tí ń ṣokùnfà etí híhó ni fífetí sí ariwo tí ó ròkè púpọ̀. Fún àpẹẹrẹ, àwọn tí ń gbé gbohùngbohùn àtẹ̀betí ẹ̀rọ amìjìnjìn sétí sábà máa ń ṣe ara wọn ní jàm̀bá nípa yíyí orin wọn sókè dé ìwọ̀n ìró kíkàmàmà. Ó ṣeé ṣe kí etí híhó jẹ́ àbáyọrí kan.
Dájúdájú, ó dára láti fi ọ̀rọ̀ tí Richard Hallam sọ nínú ìwé rẹ̀ Living With Tinnitus sọ́kàn pé: “Ara kì í ṣe ibì kan tí ó dákẹ́ rọ́rọ́ pátápátá, nítorí náà, ìwọ̀n ‘etí híhó’ díẹ̀ ṣì bójú mu. Ìró máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí iṣan, egungun, ẹ̀jẹ̀ àti atẹ́gùn bá ń yíra padà fúnra wọn. . . . A lérò pé lábẹ́ àwọn ipò ojoojúmọ́, àwọn ariwo ọwọ́ ẹ̀yìn yìí ni àwọn ariwo àyíká tí ó ròkè jù máa ń sé pa mọ́nú—a kì í wulẹ̀ gbọ́ wọn ni.” Kíka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí lè ti mú kí o túbọ̀ ṣàkíyèsí àwọn ariwo ọwọ́ ẹ̀yìn wọ̀nyẹn. Bí ó ti wù kí ó rí, wọn kì í ṣe ìṣòro fún ọ̀pọ̀ ènìyàn.
Báwo Ni A Ṣe Ń Tọ́jú Rẹ̀
Bí àìsàn náà bá ń pọ́n ọ lójú gidi gan-an ńkọ́? Ohun tí ó yẹ kí ó kọ́kọ́ ṣe ni kí o kàn sí dókítà rẹ. Òun yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣàwárí bí ó bá jẹ́ ìṣiṣẹ́gbòdì kan tí a lè tọ́jú ló ń ṣokùnfà àmì àrùn rẹ. Ó bani nínú jẹ́ pé nínú ọ̀ràn púpọ̀, kò sí ìwòsàn kankan fún ariwo náà. Ṣùgbọ́n àwọn ohun bíi mélòó kan wà tí a lè ṣe láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti máa mú un mọ́ra:
▪ Iṣẹ́ Abẹ: Ìwé pẹlẹbẹ Tinnitus, tí Àjọ Abójútó Ọ̀ràn Etí Híhó ní Britain tẹ̀ jáde, sọ pé: “Nígbà míràn, ìṣiṣẹ́gbòdì kan nínú etí àárín ló máa ń fa etí híhó, àìṣiṣẹ́déédéé ìṣàn ẹ̀jẹ̀ tàbí iṣan inú etí tàbí nítòsí rẹ̀ sì máa ń fà á lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Nínú àwọn ọ̀ràn tí kò wọ́pọ̀ wọ̀nyí, ó ṣeé ṣe láti mú etí híhó kúrò pátápátá nípasẹ̀ iṣẹ́ abẹ.”
▪ Egbòogi: Bí ẹnì kan tí ń ṣe bá ní ìṣòro rírí oorun sùn tàbí tó bá ń jìyà hílàhílo, pákáǹleke, tàbí ìsoríkọ́, dókítà kan lè kọ egbòogi akunnilóorun tàbí apẹ̀rọ̀ ìdààmú ọkàn láti mú àwọn àmì àrùn wọ̀nyí dẹ̀rọ̀ fún un.
▪ Àwọn Ìhùmọ̀ Àfigbọ́rọ̀ àti “Àwọn Aséròópa”: Bí a bá pàdánù ìgbọ́rọ̀ ní ráńpẹ́, ìhùmọ̀ àfigbọ́rọ̀ lè ṣèrànwọ́ púpọ̀. Ìhùmọ̀ kan tún wà tí a ń pè ní aséròópa, tí ó rí bí ìhùmọ̀ àfigbọ́rọ̀. Ó máa ń gbé ìró ọwọ́ ẹ̀yìn, láti sé ìró etí híhó náà pa mọ́nú, jáde. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà míràn, wíwulẹ̀ ṣí rédíò tàbí ṣíṣí fáànù kan máa ń ní irú ipa tí ó jọra.
▪ Àwọn Ìtọ́jú Mìíràn: Ọ̀jọ̀gbọ́n Axelsson wí fún Jí! pé: “Ìtọ́jú ti lílò ju ìwọ̀n àgbára ìtújáde afẹ́fẹ́ wíwà déédéé lọ lè ṣèrànwọ́ fún àwọn aláìsàn kan. Èyí kan gbígbé ẹni tí ó ń ṣe náà sínú àkámọ́ adíwọ̀n afẹ́fẹ́, níbi tí ó ti ṣípayá sí ògidì afẹ́fẹ́. Èyí lè mú kí etí inú rí ìwòsàn.” Níwọ̀n bí ó sì ti jẹ́ pé ní ti àwọn aláìsàn kan, ó jọ pé àwọn àmì àrùn etí híhó máa ń burú sí i nígbà tí wọ́n bá ní ojora tàbí tí wọ́n bá ń ṣàníyàn, àwọn dókítà kan ti dámọ̀ràn onírúurú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún lílo ìséraró láti sinmẹ̀dọ̀.a Bí ó ti wù kí ó rí, kíkọ́ láti sinmẹ̀dọ̀, kí a sì yẹra fún másùnmáwo ti ara àti èrò orí bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó lè ṣàǹfààní.
Mímú Àìsàn Náà Mọ́ra
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a kò fojú sọ́nà láti rí ọ̀nà ìwòsàn gidi kan fún etí híhó ní kíákíá. Nítorí náà, etí híhó jẹ́ ariwo kan tí ó lè jẹ́ pé o ní láti kọ́ láti mú mọ́ra. Ìwé Living With Tinnitus sọ pé: “Èmi àti àwọn ẹlẹgbẹ́ mi gbà gbọ́ gidigidi nísinsìnyí pé ìhùwàpadà wíwà déédéé sí etí híhó jẹ́ mímú ìráragbaǹkansí dàgbà díẹ̀díẹ̀.”
Bẹ́ẹ̀ ni, o lè fi kọ́ ọpọlọ rẹ láti ṣàìka ìró náà sí, láti wò ó bí ohun tí kò yẹ láti fún ní àfiyèsí. Ṣé ibi tí ariwo ti pọ̀ ni o ń gbé? Tàbí o ha máa ń ṣí fáànù tàbí ẹ̀rọ amúlétutù sílẹ̀ bí? Àwọn ariwo wọ̀nyẹn lè ti máa kan ọ́ lára ní ìbẹ̀rẹ̀, àmọ́ lẹ́yìn àkókò díẹ̀, ìwọ yóò wulẹ̀ ṣàìkà wọ́n sí ni. Ní tòótọ́, o tilẹ̀ lè kọ́ láti sùn láìka àwọn ariwo yẹn sí! Bákan náà, o lè kọ́ láti má ṣe fiyè sí ọ̀ràn nípa etí híhó rẹ jù.
Etí híhó jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ àìsàn tí a ní láti máa mú mọ́ra títí di ìgbà tí ayé tuntun Ọlọ́run yóò dé, níbi tí “àwọn ará ibẹ̀ kì yóò wí pé Òótù ń pa mí.” (Aísáyà 33:24) Kí ó tó di ìgbà náà, etí híhó lè jẹ́ ìṣòro tí ń tánni ní sùúrù, àmọ́ kò yẹ kí ó ba ìgbésí ayé rẹ jẹ́ tàbí kí ó jọba lórí rẹ̀. Jẹ́ kí ó dá ọ lójú pé ó jẹ́ ariwo tí o lè kọ́ láti mú mọ́ra!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Kristẹni kan ní láti rí i dájú pé irú ìtọ́jú bẹ́ẹ̀ kò tẹ àwọn ìlànà Bíbélì lójú. Fún àpẹẹrẹ, wo ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ lórí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àdábọwọ́ ara ẹni nínú ìtẹ̀jáde Jí!, February 22, 1984 (Gẹ̀ẹ́sì).
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Lílọ fún àyẹ̀wò lọ́dọ̀ oníṣègùn kan tí ó tóótun lè jẹ́ ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ sí kíkọ́ láti máa mú etí híhó mọ́ra