ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 9/8 ojú ìwé 30-31
  • Láti Ọwọ́ Òǹkàwé Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Láti Ọwọ́ Òǹkàwé Wa
  • Jí!—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Lílóye Ìbẹ̀rù Kíkólòlò
    Jí!—1997
  • Ohun Téèyàn Lè Ṣe Tó Bá Ń Kólòlò
    Jí!—2010
  • Bí Mo Ṣe Kojú Ìkólòlò
    Jí!—1998
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 9/8 ojú ìwé 30-31

Láti Ọwọ́ Òǹkàwé Wa

Wíwo Ayé Ilé iṣẹ́ ìròyìn tí ń ṣe ìwé ìròyìn ni mo ti ń ṣiṣẹ́, ọ̀pọ̀ lára àwọn tí a jọ ń ṣiṣẹ́ sì fẹ́ràn láti máa ka ẹ̀ka “Wíwo Ayé” láti rí ọgbọ́n tí wọn óò máa lò nídìí iṣẹ́ tiwọn náà. Kí n sọ tòótọ́, àwọn kan lára àwọn àpilẹ̀kọ náà ti fún èmi alára ní ìṣírí. Mo kan sáárá sí àwọn olùtúmọ̀ àti àwọn akàwéṣàyẹ̀wò yín. Irú ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga fún èdè bẹ́ẹ̀ kò wọ́pọ̀ ní àwọn ilé iṣẹ́ tí ń gbé ìròyìn jáde.

J. B., Czechia

Ní ọdún bí mélòó kan sẹ́yìn tí mo bẹ̀rẹ̀ sí ka Jí!, n kì í fi bẹ́ẹ̀ gbádùn “Wíwo Ayé.” Nísinsìnyí, mo kà á sí èyí tí ó kún fún ìsọfúnni gan-an. Ní gidi, ọ̀pọ̀ àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ lágbàáyé tí n kò tíì rí gbọ́ nínú ìròyìn orí tẹlifíṣọ̀n ni ẹ̀ka “Wíwo Ayé” ti sọ nípa rẹ̀. Ẹ máa bá iṣẹ́ dáradára náà lọ!

I. K. M. C., Brazil

Àjàkálẹ̀ Àrùn Ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà, “Àjàkálẹ̀ Àrùn—Yóò Ha Dópin Láé Bí?” (November 22, 1997) sọ pé: “Àrùn tí ń gbèèràn ni ó ṣì ń pa ènìyàn jù lọ, ó kéré tán, ó pa ènìyàn tí ó lé ní 50 mílíọ̀nù ní 1996 nìkan.” Àmọ́, Àjọ Ìlera Àgbáyé ròyìn pé, ó lé ní mílíọ̀nù 52 ènìyàn tí ó pa ní 1996, mílíọ̀nù 17 tó kú ló jẹ́ àwọn àrùn àkóràn tàbí èyí tí ń gbé inú ara ló fà á.

B. B., United States

Inú ìwé ìròyìn ilẹ̀ Germany náà, “Nassauische Neue Presse,” ni a ti fa ọ̀rọ̀ náà yọ. Dájúdájú, àpilẹ̀kọ inú ìwé ìròyìn náà ṣi ọ̀rọ̀ tí Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ náà fà yọ. Nítorí náà, a dúpẹ́ fún àlàyé yìí.—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.

Kíkólòlò Ẹ ṣeun fún àpilẹ̀kọ náà, “Lílóye Ìbẹ̀rù Kíkólòlò.” (November 22, 1997) Àwọn èwe bí mélòó kan ní ìṣòro yìí nínú ìjọ wa, kì í sì í fìgbà gbogbo rọgbọ fún mi láti kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú wọn. Nítorí náà, inú mi dùn láti ka àwọn àbá tí ó gbéṣẹ́ tí ẹ pèsè tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti bá àwọn tí wọ́n kólòlò lò. Ẹ fún wa níṣìírí láti ṣèrànwọ́ fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, ẹ sì jẹ́ kí a mọ bí a ṣe lè ṣe é.

Y. N., Japan

Ní ilé ẹ̀kọ́, àwọn akólòlò méjì wà ní kíláàsì mi. Wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ má lè máa dáhùn ní kíláàsì, bí àpilẹ̀kọ yín sì ṣe sọ, bí a bá ni kí wọ́n kàwé sókè, a máa ń rí i pé ojora máa ń bò wọ́n. Ẹ ṣeun fún àpilẹ̀kọ yín, mo lóye ẹ̀rù tí wọ́n gbọ́dọ̀ borí rẹ̀ kí wọ́n bàa lè sọ̀rọ̀ ní kíláàsì.

S. L., Germany

Ọmọ ọdún 16 ni mí, mo sì máa ń kólòlò. Mo fẹ́ fi tọkàntọkàn dúpẹ́ lọ́wọ́ yín nítorí ìṣírí tí mo rí gbà nípa kíka àpilẹ̀kọ náà. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan a máa ń soríkọ́ nítorí a kò lè ṣe gbogbo ohun tí a ń fẹ́. Nítorí náà, ohun àgbàyanu ni láti rí ohun tí Jèhófà ń rò nípa wa, tí ó sì fún wa níṣìírí. Mo lérò pé yóò ran gbogbo ẹni tí ó bá ka àpilẹ̀kọ náà lọ́wọ́ láti mọ bí àwọn akólòlò ṣe ń sapá tó.

S. D. A., Ítálì

Àpilẹ̀kọ náà ṣí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tí ń múni rántí àwọn ohun tí ń dunni payá. Àmọ́ ó tún jẹ́ kí n mọ bí Jèhófà ṣe bìkítà tó àti bí ó ti bù kún mi tó láti ọdún wọ̀nyí wá. Nígbà tí mo ṣèrìbọmi ní ọmọ ọdún 11, ohun tí mo fẹ́ gidigidi lọ́kàn mi ni láti máa yin Jèhófà bí ẹni tí ń bá àwọn àwùjọ sọ̀rọ̀. Mo lérò pé mo ní láti dúró de ayé tuntun Ọlọ́run láti lè ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, láàárín ọdún 37 tó ti kọjá, mo ti ní àǹfààní láti sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwíyé fún gbogbo ènìyàn àti àwọn ọ̀rọ̀ àwíyé fún àwọn àwùjọ ní àwọn ìpàdé àyíká àti ti àgbègbè.

R. F. D., England

Nítorí ẹ̀rù tó máa ń bà mí nípa kíkólòlò, n kì í dáhùn ní àwọn ìpàdé ìjọ. Mo tún máa ń dààmú nípa kíkólòlò nínú iṣẹ́ ìwàásù ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà, ní pàtàkì nígbà tí mo bá ń bá ẹni tí ọ̀rọ̀ dá ṣáṣá lẹ́nu rẹ̀ ṣiṣẹ́. Àpilẹ̀kọ yìí ràn mí lọ́wọ́ láti rí i pé Jèhófà lóye ìṣòro mi.

C. C. L., Brazil

Àwọn Ọmọdé àti Ogun Mo nímọ̀lára ìbànújẹ́ gidigidi nígbà tí mo ka ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà, “Ohun Tí Ogun Ń Ṣe fún Àwọn Ọmọdé.” (October 22, 1997) Àkókò ogun la bí èmi náà. Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, mo lo ọdún mẹ́rin ààbọ̀ ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Ngawi àti Bandung ti àwọn ará Japan. Ní ọmọ ọdún mẹ́wàá, wọn ya èmi àti àwọn òbí mi nípa, mo sì ń ṣe làálàá lójoojúmọ́ nínú oòrùn ilẹ̀ olóoru—láìjẹunkánú, tí àrùn bèríbèrí àti ìgbẹ́ ọ̀rìn sì yọ mí lẹ́nu. Síbẹ̀, gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi dà bí ohun àmúṣeré lásán lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìwà ìkà tí ẹnu kò jẹ́ ròyìn, tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ọmọdé ń fojú winá rẹ̀ lónìí. Kí a má ṣe rẹ̀wẹ̀sì nígbà kankan pé Jèhófà ń yọ̀ǹda àkókò fún àwọn ènìyàn kárí ayé, títí kan àwọn ọmọ tí a bí sí ogun, láti mọ̀ nípa àwọn ìlérí atuninínú rẹ̀!

R. B., United States

Ìkòkò Ọ̀rá Inú mi ń bàjẹ́ tẹ́lẹ̀, mo sì máa ń káàánú ara mi. Ní ọdún kan sẹ́yìn, ọkọ mi pinnu pé òun kò fẹ́ aya kan tó jẹ́ Kristẹni, ó sì lé èmi àti ọmọkùnrin mi jáde nínú ilé mèremère tó sọ pé òun rà fún mi. Mo di aláìní. Ó jọ pé n kò nírètí nínú ìgbésí ayé mọ́, mo sì ké pe Jèhófà pé kí ó ràn mí lọ́wọ́. Àpilẹ̀kọ náà, “Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Láti Inú Ìkòkò Ọ̀rá Kan” (October 22, 1997), kọ́ mi ní ẹ̀kọ́ kan. Ó rán mi létí pé kí n máa ní ìtẹ́lọ́rùn bí mo bá ti ní oúnjẹ àti aṣọ, kí n sì máa fi ire Ìjọba sí ipò kìíní.

K. P., United States

Àwọn Ìṣòro Àárín Ọmọ Ìyá Àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Èé Ṣe Tí Wọ́n Ń Fún Arákùnrin Mi Ní Gbogbo Àfiyèsí?” (October 22, 1997) dé ní àkókò tí a nílò rẹ̀ gẹ́lẹ́. Ó mú kí a mọ̀ pé bí àwọn òbí wa bá ń hùwà sí wa lọ́nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ìyẹn kò fi dandan jẹ́ pé wọ́n ń ṣègbè. A ti wá rí i nísinsìnyí pé ó ní ohun tí ń mú kí àwọn òbí wa máa fún àwọn ọmọ ìyá wa tó kù ní àfiyèsí púpọ̀ sí i. A fara mọ́ àpilẹ̀kọ náà gidigidi.

B. K., H. K., àti G. U. O., Nàìjíríà

Ariwo Tí Ń Ṣèdíwọ́ Mo ti lo ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́nu iṣẹ́ nílé iṣẹ́ ńlá kan, èmi àti àwọn ẹlẹgbẹ́ mi kan sì ti fara gbá àwọn àbájáde ariwo ńlá tó wà níbẹ̀. Mo mú ìtẹ̀jáde November 8, 1997 lọ síbi iṣẹ́ (“Ariwo—Òun Ló Ń Ṣèdíwọ́ fún Wa Jù Bí?”), àwọn alábòójútó sì ti pinnu láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ ìṣọ́ra tó yẹ láti dáàbò bo ìlera gbogbo òṣìṣẹ́.

R. P., Ítálì

Ariwo tí aládùúgbò mi máa ń pa ti ń bí mi nínú láti ọdún mélòó kan wá. Ó ń ṣe òwò kan títí di òru. Nígbà mìíràn, mo ti bínú gan-an. Ṣùgbọ́n, mímọ̀ pé àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin tí ariwo ń dá lóró, ṣùgbọ́n tí wọ́n ń kojú rẹ̀ nípa kíkó ara wọn níjàánu wà, ti fún mi lókun.

T. O., Japan

Aládùúgbò mi kan máa ń dí mi lọ́wọ́ nípa lílo tẹlifóònù ní kùtùkùtù òwúrọ̀. Àwọn àpilẹ̀kọ wọ̀nyí ti fún mi ní àwọn àbá àgbàyanu nípa bí mo ṣe lè kojú ọ̀ràn yìí lọ́nà alálàáfíà, ti Kristẹni.

J. R., England

Magellan Mo mọyì àpilẹ̀kọ tí ẹ kọ nípa Ferdinand Magellan, ti ẹ pe àkọlé rẹ̀ ní “Ọkùnrin Tó Ṣí Ayé Payá” (November 8, 1997), mo sì gbádùn rẹ̀. Nígbà tí àpilẹ̀kọ náà jáde, a ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ lọ́wọ́ ní kíláàsì ìpele ẹ̀kọ́ karùn-ún. Ohun tí mo kọ́ nípa rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ náà ju èyí tí mo rí kọ́ nínú ìwé ẹ̀kọ́ ìbágbépọ̀ ẹ̀dá lọ. Mo fún olùkọ́ mi ní ẹ̀dà ìwé ìròyìn náà tó jẹ́ tèmi, ó sì gbádùn rẹ̀! Ó dá ìwé ìròyìn náà padà fún mi lọ́jọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, ó sì kọ ìwé kan sí i tí ó tún fi dúpẹ́ lọ́wọ́ mi.

B. V., United States

Ó jẹ́ ohun àgbàyanu láti finú ro bí Ferdinand Magellan, irú ọkùnrin onígboyà bẹ́ẹ̀, ṣe borí ìkóguntini àti onírúurú ìṣòro, kí ó lè ṣe ọ̀kan lára àwọn àṣeyọrí títóbijù nínú ìtàn. Ẹ ṣeun tí ẹ kọ nípa kókó kan tó fani lọ́kàn mọ́ra.

M. E., Ítálì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́