Wíwo Ayé
Àwọn Alárùn Àsun-ùn-dá Ẹ̀jẹ̀ Gbowó Ìtanràn
Kóòtù Ìbílẹ̀ Róòmù fẹ̀sùn kan Iléeṣẹ́ Ètò Ìlera Ilẹ̀ Ítálì pé wọ́n “jọ̀gọ̀ nù, wọn ò sì bìkítà rárá” àti pé “wọ́n fi nǹkan falẹ̀ nígbà tó yẹ kí wọ́n tètè da àwọn ẹ̀jẹ̀ [tó lárùn nínú] nù,” fún ìdí yìí, kóòtù náà ti pàṣẹ pé kí iléeṣẹ́ náà san owó ìtanràn fún okòó dín nírínwó ó lé márùn-ún [385] àwọn alárùn àsun-ùn-dá ẹ̀jẹ̀ tí àwọn ẹ̀jẹ̀ tó lárùn nínú ti kó àrùn mẹ́dọ̀wú tàbí fáírọ́ọ̀sì tí ń fa àrùn éèdì ràn. Ìdámẹ́ta wọn ló ti kú o. Agbẹjọ́rò náà, Mario Lana, tí í ṣe ààrẹ Àjọ Àwọn Onímọ̀ Sáyẹ́ǹsì Aṣèwádìí Ìwà Ọ̀daràn fún Ìdáàbòbo Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ní Ítálì, sọ pé “ẹjọ́ tí wọ́n dá yìí fi hàn kedere pé ìwà àìbìkítà gbáà tí ń buni kù ni Ìjọba Ítálì hù, ìwà yìí ló sì fà á táwọn alárùn àsun-ùn-dá ẹ̀jẹ̀ náà fi kàgbákò.” Ní Ítálì, nǹkan bí ẹgbàá àwọn alárùn àsun-ùn-dá ẹ̀jẹ̀ ló ti kó fáírọ́ọ̀sì tí ń fa àrùn éèdì, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [5,000] tó ti kó oríṣi àrùn mẹ́dọ̀wú kan. Ẹgbẹ̀fà ó lé mẹ́rìndínláàádọ́ta [1,246] àwọn ará Ítálì ló ti kú, nítorí gbígba ẹ̀jẹ̀ wọ̀nyí tó lárùn nínú sára.
Kọ́lẹ́rà Gbẹ̀mígbẹ̀mí Tún Dé O
Ìwé ìròyìn Times of Zambia sọ pé, ní February ni àrùn kọ́lẹ́rà tún bẹ̀rẹ̀ sí gbẹ̀mí àwọn èèyàn nílùú Lùsákà, Zambia, ìyẹn ló sì mú kí káńsù ìlú fi òté lé e pé ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ “máa ta ohun jíjẹ èyíkéyìí lẹ́gbẹ̀ẹ́ títì mọ́.” Ìyẹn nìkan kọ́ o, ìròyìn náà tún fi yéni pé àwọn hòtẹ́ẹ̀lì àti ilé àrójẹ ò mórí bọ́ o, “tọwọ́tẹsẹ̀ ni wọ́n ń ṣọ́ wọn báyìí ní tọ̀sántòru, torí pé èèyàn méjìlélógójì ni kọ́lẹ́rà ti sáré lù pa ní olú ìlú náà.” Àyà àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera ti bẹ̀rẹ̀ sí já báyìí, torí pé àrùn onígbá méjì yìí tún ti “jà ràn-ìn láwọn ibòmíràn lórílẹ̀-èdè náà.” Láti gbógun ti ìṣòro náà, àwọn òṣìṣẹ́ Iléeṣẹ́ Ètò Ìlera àti ti Ẹ̀kọ́ ti dá àjọ agbógunti kọ́lẹ́rà sílẹ̀, iṣẹ́ wọn ni láti wá àwọn èèyàn púpọ̀ sí i tí yóò máa kó ìdọ̀tí, kí wọ́n sì rí sí i pé wọ́n fi èròjà chlorine sáwọn kànga tí kò jìn, tí omi inú ilẹ̀ tètè máa ń sọ di eléèérí. Daniel M’soka, agbẹnusọ Káńsù Ìlú Lùsákà, sọ pé: “Góńgó wa ni láti wá ẹ̀rọ̀ sí àjàkálẹ̀ àrùn kọ́lẹ́rà.”
Ọkàn-Àyà Tí Kò Rí Ìtọ́jú Gbà
Ìwé ìròyìn National Post sọ pé: “Dípò kí àwọn obìnrin Kánádà wá nǹkan ṣe sọ́ràn ìlera wọn, ìyà gidi ni wọ́n fi ń jẹ ọkàn-àyà wọn.” Láìpẹ́ yìí, Àjọ Tí Ń Rí Sọ́ràn Ọkàn-Àyà àti Àrùn Ẹ̀gbà ní Kánádà ṣe ìwádìí kan, wọ́n lo irínwó obìnrin ará Kánádà tọ́jọ́ orí wọ́n bẹ̀rẹ̀ láti ọdún márùndínláàádọ́ta sí ọdún mẹ́rìnléláàádọ́rin fún ìwádìí náà, ohun tí wọ́n ṣàwárí ni pé, “kìkì ìpín ọgbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún wọn ni kò sanra jù, ìpín mẹ́rìndínlógójì péré ló ń fara ṣiṣẹ́, ìpín mẹ́rìnléláàádọ́rin sì sọ pé másùnmáwo kò jẹ́ káwọn gbádùn, nítorí ọ̀kan-ò-jọ̀kan ẹrù iṣẹ́ tó já lé wọn léjìká.” Elissa Freeman, agbẹnusọ Àjọ náà wá sọ pé, “àwọn obìnrin ń tọ́jú baálé wọn ju bí wọ́n ti ń tọ́jú ara wọn.” Ìròyìn náà sọ pé, “àrùn ọkàn-àyà àti àrùn ẹ̀gbà ló ń fa ìpín ogójì nínú ọgọ́rùn-ún ikú tó ń pa àwọn obìnrin—èyí tó lé ní ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélógójì lọ́dọọdún.”
Ọkùnrin Túbọ̀ Ń Pàdánù Agbára Ìbímọ
Ìwé ìròyìn World Watch sọ pé: “Ìpíndọ́gba iye àtọ̀ tó lè dọmọ tó wà lára àwọn ọkùnrin ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà àti ní Yúróòpù ti lọọlẹ̀ gan-an, àní ó ti dín sín ìlàjì iye tó jẹ́ lọ́dún 1936 sí 1939. Àwárí yìí wá túbọ̀ dá kún ominú tó ń kọ àwọn èèyàn pé àfàìmọ̀ kí ó máà jẹ́ pé ṣe ni agbára ìbímọ àwọn ọkùnrin túbọ̀ ń bà jẹ́ sí i, ìbàjẹ́ yìí kò sì lè ṣẹ̀yìn àwọn ohun aṣèbàjẹ́ téèyàn ń tú sínú afẹ́fẹ́.” Ohun tó mú wọn dé ìparí èrò yìí ni àwọn ìwádìí mọ́kànlélọ́gọ́ta táwọn èèyàn ti tẹ̀ jáde láti ọdún 1938, ó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá èèyàn tí wọ́n lò nínú àwọn ìwádìí náà. Wọ́n ní ó jọ pé àwọn kẹ́míkà kan tó wà nínú afẹ́fẹ́ máa ń dààmú ètò omi inú ara, ó sì ń dabarú ètò tí ó fi ń darí ìdàgbàsókè, ìtẹ̀síwájú, àti agbára ìbímọ. Nǹkan bí ọgọ́ta kẹ́míkà ni wọ́n mọ̀ tó ń pitú yìí. Àmọ́ o, ìwé ìròyìn World Watch sọ pé, “ìwọ̀n kéréje lára nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́rin [80,000] àwọn kẹ́míkà táwọn èèyàn ń ṣe jáde lónìí fún lílò ni wọ́n yẹ̀ wò bóyá wọ́n ní àwọn nǹkan tó ń dabarú ọ̀nà ìṣiṣẹ́ omi inú ara.”
“Àìsàn Ayọ́kẹ́lẹ́-Ṣọṣẹ́”
Iléeṣẹ́ ìròyìn táa ń pè ní Ìròyìn Nípa Àyíká ròyìn pé: “Ní àwọn orílẹ̀-èdè tó tòṣì, àwọn ọmọ tí òjé pọ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ wọn, tó nǹkan bí mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí méjìdínlógún.” Fún àpẹẹrẹ, ní Íńdíà, a ti rí i pé iye òjé tó ti wọnú ara àwọn ọmọdé ń ṣàkóbá fún agbára ìmòye wọn. Ìwé ìròyìn The Indian Express ròyìn pé Dókítà Abraham George sọ pé àwọn ọmọdé “máa ń pàdánù agbára ìmòye wọn . . . torí pé tí òjé bá ti pẹ́ lára, ó máa ń ṣe jàǹbá fún ọpọlọ.” Ní àwọn ìlú ńlá Íńdíà, àwọn ohun ìrìnnà tó ṣì ń lo epo tó ní òjé nínú ni lájorí ohun tó ń tú májèlé òjé síni lára. Nítorí pé ìṣòro májèlé òjé kò fi bẹ́ẹ̀ hàn síta, ní ìfiwéra pẹ̀lú ìṣòro ipò òṣì àti ebi, ìyẹn ló jẹ́ kí Dókítà George pè é ní “àìsàn ayọ́kẹ́lẹ́-ṣọṣẹ́.”
Àrùn Gágá Ṣì Ń Pààyàn O
Ó lé ní ọ̀ọ́dúnrún àwọn ògbógi nípa àrùn gágá tó pé jọ láìpẹ́ yìí sí oríléeṣẹ́ Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) nílùú Geneva, Switzerland, láti jíròrò bí wọ́n yóò ṣe gbógun ti òkùnrùn gbẹ̀mígbẹ̀mí yìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti tó àádọ́ta ọdún báyìí táwọn èèyàn ti ń ṣe gudugudu méje yààyàà mẹ́fà, síbẹ̀ Ẹ̀ka Agbéròyìnjáde fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ròyìn pé àrùn gágá ṣì ń pa ẹgbàágbèje lọ́dọọdún. Kí àjọ WHO lè túbọ̀ lágbára lórí àrùn gágá, kí wọ́n sì kápá rẹ̀, wọn yóò tẹ ìwéwèé kan jáde, tí yóò jẹ́ kó ṣeé ṣe láti gbára dì fún ohun tí àjọ náà pè ní “àjàkálẹ̀ àrùn gágá tó lè gbọ̀nà ẹ̀bùrú yọ.” Ọ̀gá àgbà àjọ WHO, Dókítà Gro Harlem Brundtland, sọ pé: “Tó bá ṣe pé ìgbà tó délẹ̀ tán la ṣẹ̀ṣẹ̀ ń sá kiri, ẹ̀pa lè máà bóró mọ́ o—gbàrà tí àrùn náà bá yọwọ́ tuntun ló ti máa di àjàkálẹ̀ àrùn tí kò ní gbóògùn mọ́.”
Ẹ̀yà Labalábá Monarch Ti Fẹ́ Kú Àkúrun
Gbogbo ìgbà ìwọ́wé ni ẹ̀yà labalábá tí wọ́n ń pè ní monarch máa ń rin ìrìn àjò tó ju ẹgbẹ̀rìndínlógún [3,200] kìlómítà, nígbà tí wọ́n bá ń ṣí láti Kánádà lọ síbi tí wọ́n ti ń lo ìgbà ọ̀gìnnìtìn nílùú California àti àwọn òkè Sierra Madre ní àárín Mexico. Ṣùgbọ́n o, lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ìṣànlọ ilẹ̀ àti ìgékúgèé táwọn èèyàn ń gé igi oyamel (igi gẹdú kan tó jẹ́ ẹ̀yà igi Abietaceae) ń ba ibi tí wọ́n ń sá pa mọ́ sí ní Mexico jẹ́. Ìwé ìròyìn The News ti Mexico City ròyìn pé, nítorí èyí, “ní èyí tó lé ní ọdún méjì báyìí ni iye àwọn labalábá monarch tí ń wá síbẹ̀ nígbà ọ̀gìnnìtìn ti dín kù níwọ̀n àádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ládùúgbò náà ń rowó gidi gbà lọ́wọ́ àwọn tó ń rin ìrìn àjò afẹ́ wá síbẹ̀, ṣùgbọ́n iṣẹ́ táwọn mí-ìn lára wọn fi ń powó wálé ni fífi àwọn ọkọ̀ agbégilódò jí igi wọ̀nyí kó lọ lóru, àwọn igi tí ìjọba ní kẹ́nikẹ́ni máà gé. Ìwé ìròyìn The News sọ pé: “Bí ìbàjẹ́ yìí ò bá ṣíwọ́, àwọn labalábá yìí tí ń gbé Àríwá Amẹ́ríkà nígbà ẹ̀ẹ̀rùn lè kú àkúrun o.”
Àbí Ojú Ṣẹ̀ṣẹ̀ Ń Là Síṣòro Híhùwà Àìdáa Sọ́mọdé Ni?
Ìwé ìròyìn El Universal ti ìlú Caracas sọ pé ìpíndọ́gba àwọn ọmọdé táwọn èèyàn ń hùwà àìdáa sí ní Venezuela ti pọ̀ sí i látorí ọ̀kan nínú gbogbo ọmọ mẹ́wàá lọ́dún 1980 dórí ọmọ mẹ́ta nínú gbogbo ọmọ mẹ́wàá lónìí. Lọ́dún 1980, ọdún méjìlá sí mẹ́rìnlá ni ìpíndọ́gba ọjọ́ orí àwọn ọmọ tí wọ́n ń hùwà àìdáa sí. Lónìí, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wọn kò tíì pé ọmọ ọdún mẹ́ta. Àwọn wo gan-an ló ń ṣe irú aṣemáṣe burúkú yìí? Èrò pé wọ́n jẹ́ àwọn kàràǹbàní ẹ̀dá tọ́mọ náà ò mọ̀, tó máa ń lúgọ síbi táwọn ọmọléèwé ti ń ṣeré, tó ń fẹ́ fi mindin-mín-ìndìn tàn wọ́n lọ, kì í ṣòótọ́ mọ́ o. Ìwé ìròyìn El Universal ṣàlàyé pé ìpín àádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó ń hùwàkiwà yìí jẹ́ àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ ìdílé wọn. Ó lé ní ìlàjì wọn tó jẹ́ ẹni tí bàbá tàbí ìyá wọ́n fẹ́, àwọn yòókù sì sábà máa ń jẹ́ ẹnì kan tó lè pàṣẹ fún wọn, irú bí ẹ̀gbọ́n, tàbí ìbátan mí-ìn, tàbí tíṣà.
Ọkọ̀ Ayọ́kẹ́lẹ́ Tìrìgàngàn
Àjọ Àwọn Olùṣe Ohun Ìrìnnà ní Amẹ́ríkà sọ pé láìpẹ́ yìí ni Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ṣe mọ́tò tó pọ̀ tó ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù. Ìwé ìròyìn Compressed Air ròyìn pé: “Ó gba ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n gbáko kí wọ́n tó lè ṣe mọ́tò tó pọ̀ tó mílíọ̀nù kan.” Àmọ́, lónìí, “ọgbọ̀n ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ akérò, ọkọ̀ akẹ́rù mẹ́wàá àti bọ́ọ̀sì mẹ́wàá ni wọ́n ń ṣe báyìí ní ìṣẹ́jú kọ̀ọ̀kan, ní gbogbo ọjọ́ iṣẹ́.” Bóo bá ṣírò àwọn iléeṣẹ́ tó ń to ọkọ̀, àwọn èyí tó ń ta ẹ̀yà ara ọkọ̀, àwọn tó ń ta ọkọ̀ àtàwọn tó ń tún un ṣe, àtàwọn èèyàn tó jẹ́ pé ọkọ̀ ni wọ́n ń wà jẹun, wàá rí i pé àwọn iléeṣẹ́ ohun ìrìnnà ló gba òṣìṣẹ́ kan síṣẹ́ nínú gbogbo òṣìṣẹ́ méje tí ń gbowó oṣù ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Wọ́n ṣírò pé nǹkan bí ogójì mílíọ̀nù ọkọ̀ làwọn èèyàn ń lò lọ́wọ́lọ́wọ́ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà.
Ẹ̀kọ́ Ti Kòṣòro
Iléeṣẹ́ ìròyìn ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n ń pè ní Ìròyìn Ò Lópin ròyìn pé: “Ẹ̀kọ́ ti kòṣòro láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, torí pé àrùnlélọ́gọ́fà [125] mílíọ̀nù àwọn ọmọ, tó jẹ́ pé obìnrin ló pọ̀ jù nínú wọn, ni kì í lọ iléèwé, kò tán síbẹ̀ o, àádọ́jọ mílíọ̀nù ló máa ń sá fi iléèwé sílẹ̀ kó tó di pé wọ́n mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà.” Ní báa ṣe ń wí yìí, ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, géńdé kan nínú mẹ́rin, tàbí ká kúkú sọ pé ẹgbẹ̀rin-lé-méjì-lé-láàádọ́rin [872] mílíọ̀nù èèyàn, ni kò mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà. Ìyẹn nìkan kọ́, ìṣòro tó dé bá ọ̀ràn ẹ̀kọ́ máa ń burú sí i nígbà táwọn orílẹ̀-èdè tí ọ̀pọ̀ èèyàn wọn jẹ́ púrúǹtù bá lọ ń yáwó lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ọlọ́rọ̀. Ìṣòro wo lèyí ń dá sílẹ̀? Owó pàtàkì tó yẹ kí wọ́n ná sórí ọ̀ràn ẹ̀kọ́ ni wọ́n máa ń fi san gbèsè. Ìyẹn nìṣòro àìmọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà kò fi tán nílẹ̀, tí òṣì kò sì yéé ta àwọn èèyàn.