Orin 146
Èmi Lẹ Ṣe É Fún
- Jésù ní àgùntàn mìíràn tó ń sìn pẹ̀lú - àwọn tó f’ẹ̀mí yàn, táá jẹ́ aya rẹ̀. - Gbogbo ohun tá a bá ṣe - kára lè tù wọ́n - Jésù máa san èrè rẹ̀ fún wa pátá. - (ÈGBÈ) - “Tẹ́ ẹ bá tù wọ́n nínú, ẹ tù mí nínú. - Tẹ́ ẹ bá ti ṣe é fún wọn, ẹ ti ṣe é fún mi. - Tẹ́ ẹ bá ṣiṣẹ́ sìn wọ́n, èmi lẹ ṣe é fún. - Ẹ ti ṣe é fún wọn; ẹ ti ṣe é fún mi. - Tẹ́ ẹ bá ti ṣe é fún wọn, ẹ ti ṣe é fún mi.” 
- “Ebi pa mí, òùngbẹ gbẹ mí, ẹ tọ́jú mi, - gbogbo ohun tí mo nílò lẹ fún mi.” - Wọ́n bi í pé: “Sọ fún wa - ìgbà wo la ṣe bẹ́ẹ̀?” - Ọba wá fèsì ó dá wọn lóhùn pé: - (ÈGBÈ) - “Tẹ́ ẹ bá tù wọ́n nínú, ẹ tù mí nínú. - Tẹ́ ẹ bá ti ṣe é fún wọn, ẹ ti ṣe é fún mi. - Tẹ́ ẹ bá ṣiṣẹ́ sìn wọ́n, èmi lẹ ṣe é fún. - Ẹ ti ṣe é fún wọn; ẹ ti ṣe é fún mi. - Tẹ́ ẹ bá ti ṣe é fún wọn, ẹ ti ṣe é fún mi.” 
- “Ẹ j’ólóòótọ́ sí mi, iṣẹ́ rere lẹ̀ ń ṣe, - ẹ̀ ń wàásù pẹ̀l’áwọn arákùnrin mi.” - Ọba máa sọ f’áwọn - àgùntàn ọ̀tún rẹ̀: - “Ẹ jogún ayé àti ìjẹ́pípé.” - (ÈGBÈ) - “Tẹ́ ẹ bá tù wọ́n nínú, ẹ tù mí nínú. - Tẹ́ ẹ bá ti ṣe é fún wọn, ẹ ti ṣe é fún mi. - Tẹ́ ẹ bá ṣiṣẹ́ sìn wọ́n, èmi lẹ ṣe é fún. - Ẹ ti ṣe é fún wọn; ẹ ti ṣe é fún mi. - Tẹ́ ẹ bá ti ṣe é fún wọn, ẹ ti ṣe é fún mi.” 
(Tún wo Òwe 19:17; Mát. 10:40-42; 2 Tím. 1:16, 17.)