ORIN 86
A Gbọ́dọ̀ Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Jèhófà
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Jèhófà ń ké sí gbogbo wa ká wá kẹ́kọ̀ọ́. - Ẹ̀mí àtìyàwó ń sọ pé: “Máa bọ̀.” - Àtìgbàdégbà l’Ọlọ́run ń kọ́ wa - Kí àlàáfíà wa lè pọ̀ yanturu. 
- 2. Ó yẹ ká máa wá sípàdé ìjọ déédéé - Ká lè máa kẹ́kọ̀ọ́, ká ṣohun tó tọ́. - Ìpàdé wa yìí ń mú ká nígbàgbọ́, - Ẹ̀mí Ọlọ́run ló sì ń darí rẹ̀. 
- 3. Inú wa ńdùn bá a ṣe ń gbọ́ tí àwọn ará - Ń fayọ̀ kọrin ìyìn ní ìpàdé. - Ká máa pàdé pọ̀ pẹ̀láwọn ará, - Ká lè máa fìfẹ́ gbé ara wa ró! 
(Tún wo Héb. 10:24, 25; Ìfi. 22:17.)