ORIN 146
Ọlọ́run Máa “Sọ Ohun Gbogbo Di Tuntun”
- 1. Ìjọba Jèhófà Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀. - Jésù ti gúnwà sórí ìtẹ́ rẹ̀. - Ibùgbé Èṣù kò sí lọ́run mọ́. - Láìpẹ́, ìfẹ́ Ọlọ́run la ó máa ṣe. - (ÈGBÈ) - Ẹ yọ̀! Jáà yóò máa bá wa gbé. - Àgọ́ rẹ̀ yóò wà pẹ̀lú wa. - Kò ní sẹ́kún àti ìrora mọ́. - Ọ̀fọ̀, oró ikú kò ní sí mọ́. - Ọlọ́run yóò sohun gbogbo dọ̀tun. - Òdodo àtòótọ́ ni. 
- 2. Ẹ wá wo Jerúsálẹ́mù tuntun náà, - Ìyàwó ọ̀dọ́ àgùntàn ń tàn yòò. - A ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́, ó sì rẹwà púpọ̀. - Jèhófà lorísun ìmọ́lẹ̀ rẹ̀. - (ÈGBÈ) - Ẹ yọ̀! Jáà yóò máa bá wa gbé. - Àgọ́ rẹ̀ yóò wà pẹ̀lú wa. - Kò ní sẹ́kún àti ìrora mọ́. - Ọ̀fọ̀, oró ikú kò ní sí mọ́. - Ọlọ́run yóò sohun gbogbo dọ̀tun. - Òdodo àtòótọ́ ni. 
- 3. Ìlú yìí yóò múnú gbogbo èèyàn dùn. - Ibodè rẹ̀ yóò máa wà ní ṣíṣí. - Ògo rẹ̀ yóò tàn sórí aráyé; - Àwọn ìránṣẹ́ Jáà ń fògo rẹ̀ hàn. - (ÈGBÈ) - Ẹ yọ̀! Jáà yóò máa bá wa gbé. - Àgọ́ rẹ̀ yóò wà pẹ̀lú wa. - Kò ní sẹ́kún àti ìrora mọ́. - Ọ̀fọ̀, oró ikú kò ní sí mọ́. - Ọlọ́run yóò sohun gbogbo dọ̀tun. - Òdodo àtòótọ́ ni. 
(Tún wo Mát. 16:3; Ìfi. 12:7-9; 21:23-25.)