Saturday
“Ẹ sa gbogbo ipá yín kó lè bá yín . . . láìní èérí àti àbààwọ́n àti ní àlàáfíà”—2 Pétérù 3:14
ÀÁRỌ̀
- 9:20 Fídíò Orin 
- 9:30 Orin 58 àti Àdúrà 
- 9:40 ÀPÍNSỌ ÀSỌYÉ: Múra Tán Láti Kéde “Ìhìn Rere Àlàáfíà” - • Jẹ́ Kí Iná Ìtara Ẹ Máa Jó (Róòmù 1:14, 15) 
- • Múra Sílẹ̀ Dáadáa (2 Tímótì 2:15) 
- • Máa Lo Àǹfààní Tó Bá Yọ (Jòhánù 4:6, 7, 9, 25, 26) 
- • Pa Dà Lọ Sọ́dọ̀ Àwọn Tó Nífẹ̀ẹ́ Sọ́rọ̀ Ẹ (1 Kọ́ríńtì 3:6) 
- • Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Túbọ̀ Sún Mọ́ Jèhófà (Hébérù 6:1) 
 
- 10:40 Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Fi Ayé Yín Ṣe Ohun Táá Jẹ́ Kí Ọkàn Yín Balẹ̀! (Mátíù 6:33; Lúùkù 7:35; Jémíìsì 1:4) 
- 11:00 Orin 135 àti Ìfilọ̀ 
- 11:10 FÍDÍÒ: Ọkàn Àwọn Ará Wa Balẹ̀ Bí Wọ́n Tiẹ̀ Ń Dojú Kọ . . . - • Àtakò 
- • Àìsàn 
- • Ìṣòro Àìlówó Lọ́wọ́ 
- • Àjálù 
 
- 11:45 ÌRÌBỌMI: Ẹ Máa Rìn “ní Ọ̀nà Àlàáfíà” (Lúùkù 1:79; 2 Kọ́ríńtì 4:16-18; 13:11) 
- 12:15 Orin 54 àti Àkókò Ìsinmi 
Ọ̀SÁN
- 1:35 Fídíò Orin 
- 1:45 Orin 29 
- 1:50 ÀPÍNSỌ ÀSỌYÉ: Ẹ Yẹra fún Ohun Tó Lè Ba Àlàáfíà Jẹ́ - • Kéèyàn Máa Fọ́nnu (Éfésù 4:22; 1 Kọ́ríńtì 4:7) 
- • Ìlara (Fílípì 2:3, 4) 
- • Àìṣòótọ́ (Éfésù 4:25) 
- • Òfófó Tó Ń Pani Lára (Òwe 15:28) 
- • Ìbínú Òdì (Jémíìsì 1:19) 
 
- 2:45 FÍDÍÒ: Jèhófà Ń Darí Wa ní Ọ̀nà Àlàáfíà—Apá 1 (Àìsáyà 48:17, 18) 
- 3:15 Orin 130 àti Ìfilọ̀ 
- 3:25 ÀPÍNSỌ ÀSỌYÉ: ‘Máa Wá Àlàáfíà, Kó O sì Máa Lépa Rẹ̀’ . . . - • Má Tètè Máa Bínú (Òwe 19:11; Oníwàásù 7:9; 1 Pétérù 3:11) 
- • Máa Tọrọ Àforíjì (Mátíù 5:23, 24; Ìṣe 23:3-5) 
- • Máa Dárí Jini Fàlàlà (Kólósè 3:13) 
- • Máa Sọ Ohun Tó Máa Ṣe Àwọn Èèyàn Láǹfààní (Òwe 12:18; 18:21) 
 
- 4:15 Má Ṣe Jẹ́ Kí Àlàáfíà Tó Wà Láàárìn Wa Bà Jẹ́ (Éfésù 4:1-6) 
- 4:50 Orin 113 àti Àdúrà Ìparí