ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 1/1 ojú ìwé 3-4
  • Orílẹ̀-èdè Aláyọ̀ Naa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Orílẹ̀-èdè Aláyọ̀ Naa
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Orílẹ̀-èdè Kan Ti O Jẹ Aláyọ̀ Nitootọ
  • Orílẹ̀-èdè Aláyọ̀ ti Òde-òní
  • Jèhófà Ni Ọba Wa!
    “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
  • Jèhófà Ni Ọba Wa!
    Kọrin sí Jèhófà
  • Ṣiṣẹ́sin Jehofa Pẹ̀lú Ìdùnnú-Ayọ̀ Ọkàn-Àyà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìdùnnú-Ayọ̀ Jehofa Ni Odi-Agbára Wa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 1/1 ojú ìwé 3-4

Orílẹ̀-èdè Aláyọ̀ Naa

ORÍLẸ̀-ÈDÈ aláyọ̀ naa! Njẹ apejuwe yii yẹ eyikeyii lara awọn orílẹ̀-èdè aráyé lonii bí? Orílẹ̀-èdè eyikeyii ha lè fi tayọtayọ sọ daju pe oun ti mú ìwà-ipá, ìwà-ọ̀daràn, òṣì, biba ayika jẹ, awọn òkùnrùn ti nsọnidi alaiwulo, ìwà ìbàjẹ́ òṣèlú, awọn ìkórìíra ìsìn kúrò bí? Orílẹ̀-èdè eyikeyii ha nawọ́ ireti tootọ ti ṣíṣàṣeyọrí irú awọn góńgó-ìlépa bẹẹ bí? Bẹẹkọ rárá!

Kinni niti ìrísí awọn nnkan yíká ilẹ̀-ayé? Mikhail Gorbachev, ààrẹ U.S.S.R. wí ní July 16 tí ó kọja yii pe: “Awa ńfi sànmánnì kan silẹ ninu àjọṣepọ̀ láàárín awọn orílẹ̀-èdè, a sì ńwọnú òmíràn, mo ronú pe ó jẹ́ sáà alaafia gbígbéṣẹ́, tí o pẹ́ títí.” Bí ó ti wù kí ó rí, ìwé-ìròhìn Time ti ọjọ kan naa ròhìn pe United States fojusun Moscow sibẹ pẹlu 120 ṣóńṣó orí àgbá oníná, ọkọọkan eyi tí yoo pa ìlú-ńlá naa run ráúráú. Kò sì sí iyèméjì pe awọn Soviet ti wà ní sẹpẹ́ lati dáhùnpadà bakan naa. Pẹlu awọn memba Iparapọ awọn Orilẹ-ede melookan tí wọn ti mọ̀ọ́ṣe nisinsinyi lati pèsè ohun ija atomik, kò sí ayọ̀ rárá ninu gbígbèrò nipa ẹni tí ó lè kọkọ ṣetán lati fi aibikita rọ̀jò ọta.

Orílẹ̀-èdè Kan Ti O Jẹ Aláyọ̀ Nitootọ

Lẹẹkan rí ninu ìtàn—ni nǹkan bíi 3,500 ọdun sẹ́hìn—orílẹ̀-èdè kan ti o jẹ aláyọ̀ wà nitootọ. Iyẹn ni Israẹli igbaani. Nigbati Ọlọrun dá awọn ènìyàn yẹn nídè kuro ninu ìninilára Ijibiti, wọn darapọ̀ mọ́ Mose ninu orin aláyọ̀ àṣeyọrí ti ìṣẹ́gun, wọn sì nbaa lọ lati yọ̀ niwọn ìgbà tí wọn ṣègbọràn sí Ọlọrun ati Olùdáninídè wọn.—Ẹksodu 15:1-21; Deuteronomi 28:1, 2, 15, 47.

Lábẹ́ ìṣàkóso Solomoni “Juda ati Israẹli pọ̀ gẹgẹbi iyanrìn tí nbẹ ní etí òkun ní ọpọlọpọ, wọn ńjẹ, wọn sì ńmu, wọn sì ńṣe àríyá.” Iyẹn jẹ́ àkókò ìdùnnú ńlá kan, tí a mú dé òtéńté nipa kíkọ́ ilé kan tí ó ṣeeṣe kí ó jẹ́ ológo julọ ninu ìtàn, tẹmpili fun ìjọsìn Jehofa ní Jerusalẹmu.—1 Ọba 4:20; 6:11-14.

Orílẹ̀-èdè Aláyọ̀ ti Òde-òní

Israẹli igbaani jẹ́ òjìji ìṣáájú fun orílẹ̀-èdè kan lóde-òní. Èwo ni? Ó ha jẹ́ Israẹli olóṣèlú ti Agbedeméjì Ìlà-oòrùn bí? Ìròhìn fihàn pe orílẹ̀-èdè tí ńjìjàkadì yẹn kò ní ayọ̀. Njẹ Iparapọ awọn Orilẹ-ede tí a fi ẹnu lásán pè bẹẹ ha mú ayọ̀ tootọ wá fun awọn orilẹ-ede ti wọn jẹ memba rẹ̀ bí? Bẹẹkọ, ayọ̀ tootọ ni a kò lè rí láàárín awọn orílẹ̀-èdè ti wọn nlọwọ ninu ìgbòkègbodò ìṣèlú. Ìwọra, ìwà-ìbàjẹ́, ati àbòsí pọ̀ gidigidi, ati ní ọpọlọpọ ilẹ̀ awọn ènìyàn gbáàtúù ńjìjàkadì láìláyọ̀ kìkì lati walaaye.—Owe 28:15; 29:2.

Bí ó ti wù kí ó rí, orílẹ̀-èdè pípẹtẹrí kan wà lonii tí ó ní ayọ̀ lọna titayọ jùlọ. Kii ṣe ti ìṣèlú, nitori Olori rẹ̀, Kristi Jesu, wí niti awọn ènìyàn rẹ̀: “Ẹyin kii ṣe ti ayé.” (Johanu 15:19) Nigbati ó jẹ́ pe niti orukọ lasan ni Iparapọ awọn Orilẹ-ede fi sopọṣọkan, orílẹ̀-èdè alayọ naa nfa awọn alátìlẹhìn rẹ̀ ti wọn jẹ olufẹ alaafia mọra “lati inú orílẹ̀-èdè gbogbo, ati ẹ̀yà, ati ènìyàn, ati lati inú èdè gbogbo wá.” (Iṣipaya 7:4, 9) Iye rẹ̀ ti rekọja aadọta ọ̀kẹ́ mẹrin nisinsinyi, tí ó fi jẹ́ pe iye ènìyàn rẹ̀ pọ jù nǹkan bíi 60 ninu 159 awọn orílẹ̀-èdè ti wọn jẹ memba Iparapọ awọn Orilẹ-ede. Iye èdè ìbílẹ̀ ti awọn ènìyàn aadọta ọ̀kẹ́ mẹrin wọnyi nsọ tó nǹkan bíi 200; sibẹ gbogbo wọn wà ní ìsopọ̀ṣọ̀kan ninu sísọ “èdè mímọ́gaara” kan.—Sẹfanaya 3:9, New World Translation.

Kò ha ṣàjèjì pe ọpọlọpọ ìṣẹ̀dálẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nilati sọ èdè ajọsọ kan? Kò rí bẹẹ niti gidi, nitori èdè asonipọ̀ṣọ̀kan yii ní ìhìn-iṣẹ́ Ijọba òdodo Ọlọrun tí ńbọ̀ ninu. Orílẹ̀-èdè aláyọ̀ yii wá “lati ìkangun ilẹ̀-ayé” a sì mọ̀ ọ́n yíká ayé gẹgẹbi ‘awọn Ẹlẹrii Jehofa.’ (Aisaya 43:5-7, 10, NW; Sẹkaraya 8:23) Ó fẹrẹẹ jẹ́ pe ni ibikibi tí iwọ bá rìnrìn-àjò lọ lórí ilẹ̀-ayé yii, ni iwọ yoo ti rí wọn.

Ní Aisaya 2:2-4, wolii Ọlọrun ṣàpèjúwe ọ̀pọ̀ ènìyàn tí wọn ńwọ́jáde lati inú gbogbo awọn orílẹ̀-èdè, ni wiwipe: “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lọ sí òkè Oluwa [“Jehofa,” NW], sí ilé Ọlọrun Jakọbu; Oun yoo sì kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, awa yoo sì maa rìn ní ipa rẹ̀.” Pẹlu ìtara, awọn wọnyi ńkésí awọn miiran lati gba ìtọ́ni lati ọ̀dọ̀ Jehofa nipasẹ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli, kí wọn baa lè kẹ́kọ̀ọ́ lati ṣe ìfẹ́-inú rẹ̀. Orílẹ̀-èdè kan yii tẹle ipa-ọ̀nà alaafia tootọ, awọn ènìyàn rẹ̀ ti fi ‘idà rọ abẹ ohun-èèlò ìtulẹ̀ ati ọ̀kọ̀ rọ̀ àlùmọ́gàjí ìpọ̀mùnú, wọn kò sì kẹ́kọ̀ọ́ ogun mọ́.’ Orílẹ̀-èdè kan ti o jẹ aláyọ̀ ni nitootọ!

Iwọ pẹlu lè nípìn-ín ninu ayọ̀ yii. Iwọ lè kẹ́kọ̀ọ́ nipa ọjọ́ tí ńyárasúnmọ́lé naa nigbati Ọba naa, Kristi Jesu, yoo mú awọn ènìyàn ati ijọba aṣèparun kúrò tí yoo sì mú Paradise padàbọ̀sípò sórí ilẹ̀-ayé. (Daniẹli 2:44; Matiu 6:9, 10) Àní nisinsinyi pàápàá, gẹgẹbi orílẹ̀-èdè tí a sopọ̀ṣọ̀kan nitootọ, awọn Ẹlẹrii Jehofa rí ayọ̀ ńlá ninu iṣẹ́ imurasilẹ ti wọn nṣe fun sànmánnì ológo yẹn ti o jẹ ti alaafia tootọ, gẹgẹbi awọn ojú-ìwé tí wọn tẹle e yoo ti fihàn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́