Wednesday, October 22
Ìgbàgbọ́ nìkan láìsí àwọn iṣẹ́ jẹ́ òkú.—Jém. 2:17.
Jémíìsì jẹ́ ká mọ̀ pé ọkùnrin kan lè sọ pé òun nígbàgbọ́, àmọ́ kò ṣe nǹkan tó fi hàn pé ó nígbàgbọ́. (Jém. 2:1-5, 9) Jémíìsì tún sọ nípa ẹnì kan tó rí ‘arákùnrin tàbí arábìnrin tí ò láṣọ, tí ò sì ní oúnjẹ,’ àmọ́ tí ò ràn án lọ́wọ́. Tírú ẹni bẹ́ẹ̀ bá sọ pé òun nígbàgbọ́ àmọ́ tí ò ṣe ohun tó fi hàn bẹ́ẹ̀, irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ ò wúlò. (Jém. 2:14-16) Jémíìsì wá sọ̀rọ̀ nípa Ráhábù, ó sì jẹ́ ká mọ̀ pé ó fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ká ṣe nǹkan tó fi hàn pé a nígbàgbọ́. (Jém. 2:25, 26) Ráhábù ti gbọ́ nípa Jèhófà, ó sì mọ̀ pé òun ló ń ran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́. (Jóṣ. 2:9-11) Ó ṣe nǹkan tó fi hàn pé ó nígbàgbọ́. Ó dáàbò bo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì méjì tí wọ́n lọ ṣe amí nígbà tí ẹ̀mí wọn wà nínú ewu. Torí ohun tí obìnrin aláìpé tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì yìí ṣe, a pè é ní olódodo bíi ti Ábúráhámù. Àpẹẹrẹ rere tó fi lélẹ̀ jẹ́ ká rí i pé ó ṣe pàtàkì pé ká ṣe àwọn iṣẹ́ tó fi hàn pé a nígbàgbọ́. w23.12 5 ¶12-13
Thursday, October 23
Kí ẹ ta gbòǹgbò, kí ẹ sì fìdí múlẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ náà.—Éfé. 3:17.
Kì í ṣe àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ nìkan ló yẹ káwa Kristẹni mọ̀. Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run tún máa ń jẹ́ kó wù wá láti lóye “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 2:9, 10) O ò ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nípa àwọn apá kan nínú Bíbélì táá jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà? Bí àpẹẹrẹ, o lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tó ṣe fáwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ nígbà àtijọ́ tó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn àtàwọn nǹkan tó ń ṣe fún ìwọ náà báyìí tó jẹ́ kó o mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ ẹ. O lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jèhófà ṣe ṣètò pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa jọ́sìn òun, kó o wá fi wé báwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń jọ́sìn ẹ̀ lónìí. Yàtọ̀ síyẹn, o tún lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣẹ sí Jésù lára nígbà tó ń ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ ẹ̀ láyé. Inú ẹ máa dùn gan-an tó o bá ṣèwádìí nípa àwọn nǹkan yìí nínú Watch Tower Publications Index lédè Gẹ̀ẹ́sì tàbí Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀, ìgbàgbọ́ ẹ máa lágbára, wàá sì “rí ìmọ̀ Ọlọ́run.”—Òwe 2:4, 5. w23.10 18-19 ¶3-5
Friday, October 24
Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún ara yín, torí ìfẹ́ máa ń bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.—1 Pét. 4:8.
Ọ̀rọ̀ tí Pétérù lò nínú ẹsẹ yìí, ìyẹn “jinlẹ̀” túmọ̀ sí kéèyàn “na nǹkan.” Apá kejì nínú ẹsẹ yẹn wá sọ ohun tó yẹ ká ṣe tá a bá ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ sáwọn èèyàn. Ó sọ pé ó máa ń bo ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ará mọ́lẹ̀. Ẹ jẹ́ ká ṣàpèjúwe ẹ̀ báyìí: Téèyàn bá fi ọwọ́ méjèèjì di aṣọ kan mú tó sì fẹ́ fi bo nǹkan, ńṣe lá bẹ̀rẹ̀ sí í nà án títí á fi bo gbogbo ohun tó fẹ́ bò. Lọ́nà kan náà, ó yẹ ká máa fi ìfẹ́ bo ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ará mọ́lẹ̀, kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ ẹyọ kan tàbí méjì, àmọ́ “ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀.” A lè fi béèyàn ṣe ń bo nǹkan wé béèyàn ṣe ń dárí ji àwọn ẹlòmíì. Bí aṣọ ṣe máa ń bo àbùkù ara, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ ká máa fi ìfẹ́ bo kùdìẹ̀-kudiẹ àwọn ará. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ará gan-an, àá dárí jì wọ́n, kódà tó bá ṣòro láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Kól. 3:13) Tá a bá ń dárí ji àwọn ará, ìyẹn máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, a sì fẹ́ múnú Jèhófà dùn. w23.11 10-12 ¶13-15