Tuesday, August 12
Ikú ò ní sí mọ́.—Ìfi. 21:4.
Kí la lè sọ fáwọn tí ò gbà pé Párádísè tí Ọlọ́run ṣèlérí máa dé? Àkọ́kọ́, Jèhófà fúnra ẹ̀ ló ṣèlérí yẹn. Ìwé Ìfihàn sọ pé: “Ẹni tó jókòó sórí ìtẹ́ sọ pé: ‘Wò ó! Mò ń sọ ohun gbogbo di tuntun.’” Jèhófà ní ọgbọ́n àti agbára láti mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ, ohun tó sì fẹ́ ṣe nìyẹn. Ìkejì, ó dá Jèhófà lójú háún-háún pé òun máa mú ìlérí òun ṣẹ, ìdí nìyẹn tó fi sọ ọ́ bíi pé ó ti ṣẹ. Ó sọ pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ yìí ṣeé gbára lé, òótọ́ sì ni. . . . Wọ́n ti rí bẹ́ẹ̀!” Ìkẹta, tí Jèhófà bá bẹ̀rẹ̀ ohun kan, ó dájú pé ó máa parí ẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi sọ pé: “Èmi ni Ááfà àti Ómégà.” (Ìfi. 21:6) Torí náà, Jèhófà máa fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì, kò sì lè dí òun lọ́wọ́ láti mú ìlérí òun ṣẹ. Torí náà, tẹ́nì kan bá sọ pé, “Àlá tí ò lè ṣẹ ni,” ka Ìfihàn 21:5, 6 fún ẹni náà, kó o sì ṣàlàyé ẹ̀. O lè jẹ́ kí ẹni náà mọ̀ pé Jèhófà ti fi dá wa lójú pé òun máa mú ìlérí òun ṣẹ, òun sì ti fi òòtẹ̀ lù ú.—Àìsá. 65:16. w23.11 7 ¶18-19
Wednesday, August 13
Màá mú kí o di orílẹ̀-èdè ńlá.—Jẹ́n. 12:2.
Jèhófà ṣèlérí yìí fún Ábúráhámù nígbà tó pé ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rin (75), tí kò sì lọ́mọ kankan. Ṣé Ábúráhámù rí ìlérí yẹn nígbà tó ṣẹ? Rárá, àmọ́ ó rí díẹ̀ lára ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tó sọdá Odò Yúfírétì, tó sì ti dúró kí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) kọjá, ó ṣojú ẹ̀ nígbà tí Jèhófà jẹ́ kí ìyàwó ẹ̀ bí Ísákì lọ́nà ìyanu. Ọgọ́ta ọdún (60) lẹ́yìn náà, ó ṣojú ẹ̀ nígbà tí wọ́n bí àwọn ọmọ ọmọ ẹ̀, ìyẹn Ísọ̀ àti Jékọ́bù. (Héb. 6:15) Àmọ́, Ábúráhámù ò sí láyé mọ́ nígbà táwọn àtọmọdọ́mọ ẹ̀ di orílẹ̀-èdè ńlá, tí wọ́n sì gba Ilẹ̀ Ìlérí. Síbẹ̀, ọkùnrin olóòótọ́ yìí ò fi Ẹlẹ́dàá ẹ̀ tó jẹ́ ọ̀rẹ́ ẹ̀ tímọ́tímọ́ sílẹ̀. (Jém. 2:23) Ẹ wo bí inú Ábúráhámù ṣe máa dùn tó nígbà tó bá jíǹde, tó sì mọ̀ pé ìgbàgbọ́ àti sùúrù tóun ní ló jẹ́ kí Jèhófà bù kún gbogbo aráyé! (Jẹ́n. 22:18) Kí la rí kọ́? Ohun tá a kọ́ ni pé gbogbo ìlérí tí Jèhófà ṣe lè má ṣẹ lójú wa. Àmọ́, tá a bá ní sùúrù bíi ti Ábúráhámù, ó dájú pé Jèhófà máa san èrè fún wa báyìí, á sì tún san èrè tó jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú ayé tuntun tó ṣèlérí.—Máàkù 10:29, 30. w23.08 24 ¶14
Thursday, August 14
Ní gbogbo àkókò tó ń wá Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ mú kí ó láásìkí.—2 Kíró. 26:5.
Onírẹ̀lẹ̀ ni Ọba Ùsáyà nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́. Bíbélì sọ pé ó “bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́.” Ọdún méjìdínláàádọ́rin (68) ló lò láyé, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀ ni Jèhófà bù kún un. (2 Kíró. 26:1-4) Ùsáyà ṣẹ́gun èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọ̀tá wọn, ó sì rí i pé òun dáàbò bo Jerúsálẹ́mù. (2 Kíró. 26:6-15) Ó dájú pé inú Ùsáyà dùn gan-an torí gbogbo nǹkan tí Jèhófà jẹ́ kó gbé ṣe. (Oníw. 3:12, 13) Ọba ni Ùsáyà, torí náà ó máa ń pàṣẹ fáwọn èèyàn. Ṣé ìyẹn lè mú kó ronú pé ohun tó bá wu òun lòun lè ṣe? Lọ́jọ́ kan, Ùsáyà wọ inú tẹ́ńpìlì Jèhófà láti sun tùràrí, bẹ́ẹ̀ sì rèé, Jèhófà ò gba àwọn ọba láyè láti ṣe bẹ́ẹ̀. (2 Kíró. 26:16-18) Torí náà, Àlùfáà Àgbà Asaráyà tọ́ ọ sọ́nà, àmọ́ ńṣe ló gbaná jẹ. Ó ṣeni láàánú pé Ùsáyà ba orúkọ rere tó ní lọ́dọ̀ Jèhófà jẹ́, Jèhófà sì fi ẹ̀tẹ̀ kọ lù ú. (2 Kíró. 26:19-21) Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ì bá má ṣẹlẹ̀ sí i ká ní ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀. w23.09 10 ¶9-10