ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Òní

Monday, August 11

Ẹ jẹ́ kí gbogbo èèyàn rí i pé ẹ̀ ń fòye báni lò.—Fílí. 4:5.

Jésù máa ń fòye báni lò bíi ti Jèhófà. Jèhófà rán an wá sáyé kó lè wàásù fún “àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tó sọ nù.” Síbẹ̀, ó máa ń fòye báni lò bó ṣe ń wàásù fáwọn èèyàn. Nígbà kan, obìnrin kan tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀ ẹ́ pé kó wo ọmọbìnrin òun sàn torí pé ‘ẹ̀mí èṣù ń yọ ọ́ lẹ́nu gidigidi.’ Àánú obìnrin yẹn ṣe Jésù, ó ṣe ohun tó sọ, ó sì wo ọmọbìnrin ẹ̀ sàn. (Mát. 15:​21-28) Ẹ jẹ́ ká tún wo àpẹẹrẹ míì. Lẹ́yìn tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá sẹ́ mi . . . , èmi náà máa sẹ́ ẹ.” (Mát. 10:33) Àmọ́ nígbà tí Pétérù sẹ́ ẹ lẹ́ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ṣé ó pa á tì? Rárá. Jésù mọ̀ pé Pétérù kábàámọ̀ ohun tó ṣe, olóòótọ́ sì ni. Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó fara han Pétérù, ó sì ṣeé ṣe kó fi dá a lójú pé òun ti dárí jì í àti pé òun ṣì nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. (Lúùkù 24:​33, 34) Jèhófà àti Jésù Kristi máa ń fòye báni lò. Àwa ńkọ́? Jèhófà fẹ́ káwa náà máa fòye báni lò. w23.07 21 ¶6-7

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Tuesday, August 12

Ikú ò ní sí mọ́.—Ìfi. 21:4.

Kí la lè sọ fáwọn tí ò gbà pé Párádísè tí Ọlọ́run ṣèlérí máa dé? Àkọ́kọ́, Jèhófà fúnra ẹ̀ ló ṣèlérí yẹn. Ìwé Ìfihàn sọ pé: “Ẹni tó jókòó sórí ìtẹ́ sọ pé: ‘Wò ó! Mò ń sọ ohun gbogbo di tuntun.’” Jèhófà ní ọgbọ́n àti agbára láti mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ, ohun tó sì fẹ́ ṣe nìyẹn. Ìkejì, ó dá Jèhófà lójú háún-háún pé òun máa mú ìlérí òun ṣẹ, ìdí nìyẹn tó fi sọ ọ́ bíi pé ó ti ṣẹ. Ó sọ pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ yìí ṣeé gbára lé, òótọ́ sì ni. . . . Wọ́n ti rí bẹ́ẹ̀!” Ìkẹta, tí Jèhófà bá bẹ̀rẹ̀ ohun kan, ó dájú pé ó máa parí ẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi sọ pé: “Èmi ni Ááfà àti Ómégà.” (Ìfi. 21:6) Torí náà, Jèhófà máa fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì, kò sì lè dí òun lọ́wọ́ láti mú ìlérí òun ṣẹ. Torí náà, tẹ́nì kan bá sọ pé, “Àlá tí ò lè ṣẹ ni,” ka Ìfihàn 21:​5, 6 fún ẹni náà, kó o sì ṣàlàyé ẹ̀. O lè jẹ́ kí ẹni náà mọ̀ pé Jèhófà ti fi dá wa lójú pé òun máa mú ìlérí òun ṣẹ, òun sì ti fi òòtẹ̀ lù ú.—Àìsá. 65:16. w23.11 7 ¶18-19

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Wednesday, August 13

Màá mú kí o di orílẹ̀-èdè ńlá.—Jẹ́n. 12:2.

Jèhófà ṣèlérí yìí fún Ábúráhámù nígbà tó pé ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rin (75), tí kò sì lọ́mọ kankan. Ṣé Ábúráhámù rí ìlérí yẹn nígbà tó ṣẹ? Rárá, àmọ́ ó rí díẹ̀ lára ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tó sọdá Odò Yúfírétì, tó sì ti dúró kí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) kọjá, ó ṣojú ẹ̀ nígbà tí Jèhófà jẹ́ kí ìyàwó ẹ̀ bí Ísákì lọ́nà ìyanu. Ọgọ́ta ọdún (60) lẹ́yìn náà, ó ṣojú ẹ̀ nígbà tí wọ́n bí àwọn ọmọ ọmọ ẹ̀, ìyẹn Ísọ̀ àti Jékọ́bù. (Héb. 6:15) Àmọ́, Ábúráhámù ò sí láyé mọ́ nígbà táwọn àtọmọdọ́mọ ẹ̀ di orílẹ̀-èdè ńlá, tí wọ́n sì gba Ilẹ̀ Ìlérí. Síbẹ̀, ọkùnrin olóòótọ́ yìí ò fi Ẹlẹ́dàá ẹ̀ tó jẹ́ ọ̀rẹ́ ẹ̀ tímọ́tímọ́ sílẹ̀. (Jém. 2:23) Ẹ wo bí inú Ábúráhámù ṣe máa dùn tó nígbà tó bá jíǹde, tó sì mọ̀ pé ìgbàgbọ́ àti sùúrù tóun ní ló jẹ́ kí Jèhófà bù kún gbogbo aráyé! (Jẹ́n. 22:18) Kí la rí kọ́? Ohun tá a kọ́ ni pé gbogbo ìlérí tí Jèhófà ṣe lè má ṣẹ lójú wa. Àmọ́, tá a bá ní sùúrù bíi ti Ábúráhámù, ó dájú pé Jèhófà máa san èrè fún wa báyìí, á sì tún san èrè tó jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú ayé tuntun tó ṣèlérí.—Máàkù 10:​29, 30. w23.08 24 ¶14

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́