ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Òní

Thursday, August 14

Ní gbogbo àkókò tó ń wá Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ mú kí ó láásìkí.—2 Kíró. 26:5.

Onírẹ̀lẹ̀ ni Ọba Ùsáyà nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́. Bíbélì sọ pé ó “bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́.” Ọdún méjìdínláàádọ́rin (68) ló lò láyé, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀ ni Jèhófà bù kún un. (2 Kíró. 26:​1-4) Ùsáyà ṣẹ́gun èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọ̀tá wọn, ó sì rí i pé òun dáàbò bo Jerúsálẹ́mù. (2 Kíró. 26:​6-15) Ó dájú pé inú Ùsáyà dùn gan-an torí gbogbo nǹkan tí Jèhófà jẹ́ kó gbé ṣe. (Oníw. 3:​12, 13) Ọba ni Ùsáyà, torí náà ó máa ń pàṣẹ fáwọn èèyàn. Ṣé ìyẹn lè mú kó ronú pé ohun tó bá wu òun lòun lè ṣe? Lọ́jọ́ kan, Ùsáyà wọ inú tẹ́ńpìlì Jèhófà láti sun tùràrí, bẹ́ẹ̀ sì rèé, Jèhófà ò gba àwọn ọba láyè láti ṣe bẹ́ẹ̀. (2 Kíró. 26:​16-18) Torí náà, Àlùfáà Àgbà Asaráyà tọ́ ọ sọ́nà, àmọ́ ńṣe ló gbaná jẹ. Ó ṣeni láàánú pé Ùsáyà ba orúkọ rere tó ní lọ́dọ̀ Jèhófà jẹ́, Jèhófà sì fi ẹ̀tẹ̀ kọ lù ú. (2 Kíró. 26:​19-21) Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ì bá má ṣẹlẹ̀ sí i ká ní ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀. w23.09 10 ¶9-10

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Friday, August 15

Ó ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀, torí ó ń bẹ̀rù àwọn tó dádọ̀dọ́.—Gál. 2:12.

Kódà lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pétérù di Kristẹni ẹni àmì òróró, ó ṣì ń bá àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ kan yí. Nígbà tó di ọdún 36 S.K., Pétérù wà níbẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run fẹ̀mí yan Kọ̀nílíù tí kì í ṣe Júù. Èyí jẹ́ ká rí i kedere pé “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú,” ó sì fẹ́ káwọn tí kì í ṣe Júù di ara ìjọ Kristẹni. (Ìṣe 10:​34, 44, 45) Àtìgbà yẹn ni Pétérù ti ń jẹun pẹ̀lú àwọn tí kì í ṣe Júù torí kì í ṣe bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀. Àmọ́ àwọn Júù kan ṣì ń rò pé kò yẹ káwọn Júù àtàwọn tí kì í ṣe Júù máa jẹun pa pọ̀. Nígbà táwọn Júù tó nírú èrò yẹn wá sí Áńtíókù, Pétérù ò jẹun pẹ̀lú àwọn Kristẹni tí kì í ṣe Júù mọ́, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ torí pé kò fẹ́ múnú bí àwọn Júù tó jẹ́ Kristẹni. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rí ohun tí Pétérù ṣe yìí, ó bá a wí lójú àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀. (Gál. 2:​13, 14) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Pétérù ṣàṣìṣe, ó ń sin Jèhófà nìṣó. w23.09 22 ¶8

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Saturday, August 16

Ó máa fẹsẹ̀ yín múlẹ̀ gbọn-in.—1 Pét. 5:10.

Tó o bá ṣàyẹ̀wò ara ẹ dáadáa, o lè rí i pé ó láwọn ibi tó o kù sí, àmọ́ má ṣe jẹ́ kó sú ẹ. Bíbélì sọ pé: “Onínúure ni [Jésù] Olúwa,” ó sì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ. (1 Pét. 2:3) Àpọ́sítélì Pétérù fi dá wa lójú pé: “Ọlọ́run . . . máa fúnra rẹ̀ parí ìdálẹ́kọ̀ọ́ yín. Ó máa fún yín lókun.” Ìgbà kan wà tí Pétérù ronú pé òun ò yẹ lẹ́ni tó ń di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. (Lúùkù 5:8) Àmọ́ torí pé Jèhófà àti Jésù ràn án lọ́wọ́, ó ṣiṣẹ́ kára kó lè máa jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi nìṣó. Torí náà, Jèhófà fún Pétérù láǹfààní láti “wọlé fàlàlà sínú Ìjọba ayérayé ti Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Kristi.” (2 Pét. 1:11) Ẹ ò rí i pé èrè ńlá nìyẹn! Tá a bá fara wé Pétérù, tá a jẹ́ kí Jèhófà dá wa lẹ́kọ̀ọ́ dáadáa, tá ò sì jẹ́ kó sú wa, àá gba èrè ìyè àìnípẹ̀kun. ‘Ọwọ́ wa sì máa tẹ èrè ìgbàgbọ́ wa, ìyẹn ìgbàlà wa.’—1 Pét. 1:9. w23.09 31 ¶16-17

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́