ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Òní

Sunday, August 24

Ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, ẹ dúró gbọn-in, ẹ má yẹsẹ̀.—1 Kọ́r. 15:58.

Lọ́dún 1978, wọ́n kọ́ ilé tó ní ọgọ́ta (60) àjà sílùú Tokyo, lórílẹ̀-èdè Japan, òun sì ni ilé tó ga jù nílùú yẹn. Àmọ́, nítorí ìmìtìtì ilẹ̀ tó máa ń ṣẹlẹ̀ nílùú yẹn, àwọn èèyàn rò pé ilé náà máa wó. Báwo ni wọ́n ṣe kọ́ ilé náà tí kò fi wó nígbà tí ìmìtìtì ilẹ̀ ṣẹlẹ̀? Àwọn tó kọ́ ilé náà ṣe ìpìlẹ̀ ẹ̀ lọ́nà tó dúró digbí, ó sì lè fì sọ́tùn-ún fì sósì débi pé tí ìmìtìtì ilẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ ilé náà ò ní wó. Àwa Kristẹni náà dà bí ilé gogoro yẹn. Lọ́nà wo? Àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ dúró gbọin-in, a ò sì gbọ́dọ̀ fọwọ́ tó le jù mú nǹkan. Ó yẹ ká jẹ́ adúróṣinṣin tó bá dọ̀rọ̀ ká tẹ̀ lé òfin àtàwọn ìlànà Jèhófà. Ó tún yẹ ká “ṣe tán láti ṣègbọràn,” ká má sì yí ìpinnu wa pa dà. Àmọ́ ṣá o, ó yẹ ká jẹ́ ẹni tó ń “fòye báni lò” tàbí ẹni tó máa ń gba tàwọn ẹlòmíì rò tá a bá rí ibi tó yẹ ká ti ṣe bẹ́ẹ̀. (Jém. 3:17) Tí Kristẹni kan bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, kò ní jẹ́ ẹni tó ń fọwọ́ tó le jù mú nǹkan, kò sì ní jẹ́ ẹni tó ń fọwọ́ yẹpẹrẹ mú nǹkan. w23.07 14 ¶1-2

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Monday, August 25

Bí ẹ ò tiẹ̀ rí i rí, ẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.—1 Pét. 1:8.

Jésù borí ìdẹwò Sátánì kódà nígbà tó sọ pé kó ṣe ohun tínú Jèhófà ò dùn sí. (Mát. 4:​1-11) Ohun tí Sátánì fẹ́ ṣe ni pé kí Jésù ṣẹ̀ sí Jèhófà kó má bàa lè san ìràpadà. Nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ ẹ̀ láyé, ó fara da àwọn àdánwò míì tó le. Àwọn ọ̀tá ẹ̀ ṣenúnibíni sí i, wọ́n sì fẹ́ pa á. (Lúùkù 4:​28, 29; 13:31) Yàtọ̀ síyẹn, ó fara da àìpé àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ torí pé wọ́n máa ń ṣe ohun tó dùn ún. (Máàkù 9:​33, 34) Nígbà tí wọ́n ń gbẹ́jọ́ ẹ̀, wọ́n fìyà jẹ ẹ́ gan-an, wọ́n sì fi í ṣe yẹ̀yẹ́. Nígbà tí wọ́n fẹ́ pa á, wọ́n dá a lóró, wọ́n sì dójú tì í. (Héb. 12:​1-3) Ní gbogbo àkókò tó fi fara da àwọn ìṣòro yìí, Jèhófà ò gbà á sílẹ̀. (Mát. 27:46) Ká sòótọ́, ohun kékeré kọ́ ni Jésù ṣe láti san ìràpadà. Torí náà, tá a bá ń ronú nípa ohun tí Jésù ṣe nígbà tó fi ara ẹ̀ rúbọ fún wa, ó máa ń jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. w24.01 10-11 ¶7-9

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Tuesday, August 26

Ó dájú pé gbogbo àwọn tó bá ń kánjú yóò di aláìní.—Òwe 21:5.

Sùúrù tún máa ń jẹ́ ká ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn èèyàn. Ó máa ń jẹ́ ká fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn èèyàn tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀. (Jém. 1:19) Sùúrù tún máa ń jẹ́ ká wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn. Kì í jẹ́ ká tètè fara ya tàbí sọ ohun tí ò dáa tá a bá ní ìdààmú ọkàn. Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá ń ní sùúrù, tẹ́nì kan bá ṣe ohun tó dùn wá, a ò ní tètè bínú. Dípò ká gbẹ̀san, ṣe làá ‘máa fara dà á fún ara wa, àá sì máa dárí ji ara wa fàlàlà.’ (Kól. 3:​12, 13) Tá a bá ń ní sùúrù, ó máa jẹ́ ká ṣe ìpinnu tó tọ́. Dípò ká kánjú ṣe ohun kan láì ro ibi tọ́rọ̀ náà máa já sí, ṣe ló yẹ ká ṣèwádìí nípa nǹkan náà ká lè ṣèpinnu tó tọ́. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ń wáṣẹ́, a lè fẹ́ gba iṣẹ́ tá a kọ́kọ́ rí. Àmọ́ tá a bá ní sùúrù, á jẹ́ ká ronú nípa àkóbá tí iṣẹ́ náà lè ṣe fún ìdílé wa àti ìjọsìn wa. Torí náà, tá a bá ń ní sùúrù, kò ní jẹ́ ká ṣe ìpinnu tí ò dáa. w23.08 22 ¶8-9

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́