Monday, August 25
Bí ẹ ò tiẹ̀ rí i rí, ẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.—1 Pét. 1:8.
Jésù borí ìdẹwò Sátánì kódà nígbà tó sọ pé kó ṣe ohun tínú Jèhófà ò dùn sí. (Mát. 4:1-11) Ohun tí Sátánì fẹ́ ṣe ni pé kí Jésù ṣẹ̀ sí Jèhófà kó má bàa lè san ìràpadà. Nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ ẹ̀ láyé, ó fara da àwọn àdánwò míì tó le. Àwọn ọ̀tá ẹ̀ ṣenúnibíni sí i, wọ́n sì fẹ́ pa á. (Lúùkù 4:28, 29; 13:31) Yàtọ̀ síyẹn, ó fara da àìpé àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ torí pé wọ́n máa ń ṣe ohun tó dùn ún. (Máàkù 9:33, 34) Nígbà tí wọ́n ń gbẹ́jọ́ ẹ̀, wọ́n fìyà jẹ ẹ́ gan-an, wọ́n sì fi í ṣe yẹ̀yẹ́. Nígbà tí wọ́n fẹ́ pa á, wọ́n dá a lóró, wọ́n sì dójú tì í. (Héb. 12:1-3) Ní gbogbo àkókò tó fi fara da àwọn ìṣòro yìí, Jèhófà ò gbà á sílẹ̀. (Mát. 27:46) Ká sòótọ́, ohun kékeré kọ́ ni Jésù ṣe láti san ìràpadà. Torí náà, tá a bá ń ronú nípa ohun tí Jésù ṣe nígbà tó fi ara ẹ̀ rúbọ fún wa, ó máa ń jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. w24.01 10-11 ¶7-9
Tuesday, August 26
Ó dájú pé gbogbo àwọn tó bá ń kánjú yóò di aláìní.—Òwe 21:5.
Sùúrù tún máa ń jẹ́ ká ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn èèyàn. Ó máa ń jẹ́ ká fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn èèyàn tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀. (Jém. 1:19) Sùúrù tún máa ń jẹ́ ká wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn. Kì í jẹ́ ká tètè fara ya tàbí sọ ohun tí ò dáa tá a bá ní ìdààmú ọkàn. Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá ń ní sùúrù, tẹ́nì kan bá ṣe ohun tó dùn wá, a ò ní tètè bínú. Dípò ká gbẹ̀san, ṣe làá ‘máa fara dà á fún ara wa, àá sì máa dárí ji ara wa fàlàlà.’ (Kól. 3:12, 13) Tá a bá ń ní sùúrù, ó máa jẹ́ ká ṣe ìpinnu tó tọ́. Dípò ká kánjú ṣe ohun kan láì ro ibi tọ́rọ̀ náà máa já sí, ṣe ló yẹ ká ṣèwádìí nípa nǹkan náà ká lè ṣèpinnu tó tọ́. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ń wáṣẹ́, a lè fẹ́ gba iṣẹ́ tá a kọ́kọ́ rí. Àmọ́ tá a bá ní sùúrù, á jẹ́ ká ronú nípa àkóbá tí iṣẹ́ náà lè ṣe fún ìdílé wa àti ìjọsìn wa. Torí náà, tá a bá ń ní sùúrù, kò ní jẹ́ ká ṣe ìpinnu tí ò dáa. w23.08 22 ¶8-9
Wednesday, August 27
Mo rí òfin míì nínú ara mi tó ń bá òfin tó ń darí èrò mi jagun, tó sì ń sọ mí di ẹrú òfin ẹ̀ṣẹ̀ tó wà nínú ara mi.—Róòmù 7:23.
Inú ẹ lè má dùn torí pé nígbà míì nǹkan tí ò dáa máa ń wá sí ẹ lọ́kàn. Àmọ́, tó o bá ń ronú nípa ìlérí tó o ṣe fún Jèhófà nígbà tó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún un, wàá lókun tí wàá fi borí ìdẹwò náà. Lọ́nà wo? Nígbà tó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, ńṣe lo sẹ́ ara ẹ. Ìyẹn ni pé o ti kọ gbogbo ìwà tínú Jèhófà ò dùn sí àtàwọn nǹkan tí ò dáa tó lè máa wù ẹ́. (Mát. 16:24) Torí náà, tí ìdẹwò bá dé, o ò ní ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ronú nǹkan tó o máa ṣe. Ìdí ni pé o ti mọ ohun tó o máa ṣe tẹ́lẹ̀, ìyẹn sì ni pé wàá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Ìpinnu ẹ ni pé o fẹ́ múnú Jèhófà dùn. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá dà bíi Jóòbù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó láwọn ìṣòro tó le gan-an, ó fi ìdánilójú sọ pé: “Mi ò ní fi ìwà títọ́ mi sílẹ̀!”—Jóòbù 27:5. w24.03 9 ¶6-7