ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Òní

Tuesday, August 26

Ó dájú pé gbogbo àwọn tó bá ń kánjú yóò di aláìní.—Òwe 21:5.

Sùúrù tún máa ń jẹ́ ká ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn èèyàn. Ó máa ń jẹ́ ká fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn èèyàn tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀. (Jém. 1:19) Sùúrù tún máa ń jẹ́ ká wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn. Kì í jẹ́ ká tètè fara ya tàbí sọ ohun tí ò dáa tá a bá ní ìdààmú ọkàn. Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá ń ní sùúrù, tẹ́nì kan bá ṣe ohun tó dùn wá, a ò ní tètè bínú. Dípò ká gbẹ̀san, ṣe làá ‘máa fara dà á fún ara wa, àá sì máa dárí ji ara wa fàlàlà.’ (Kól. 3:​12, 13) Tá a bá ń ní sùúrù, ó máa jẹ́ ká ṣe ìpinnu tó tọ́. Dípò ká kánjú ṣe ohun kan láì ro ibi tọ́rọ̀ náà máa já sí, ṣe ló yẹ ká ṣèwádìí nípa nǹkan náà ká lè ṣèpinnu tó tọ́. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ń wáṣẹ́, a lè fẹ́ gba iṣẹ́ tá a kọ́kọ́ rí. Àmọ́ tá a bá ní sùúrù, á jẹ́ ká ronú nípa àkóbá tí iṣẹ́ náà lè ṣe fún ìdílé wa àti ìjọsìn wa. Torí náà, tá a bá ń ní sùúrù, kò ní jẹ́ ká ṣe ìpinnu tí ò dáa. w23.08 22 ¶8-9

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Wednesday, August 27

Mo rí òfin míì nínú ara mi tó ń bá òfin tó ń darí èrò mi jagun, tó sì ń sọ mí di ẹrú òfin ẹ̀ṣẹ̀ tó wà nínú ara mi.—Róòmù 7:23.

Inú ẹ lè má dùn torí pé nígbà míì nǹkan tí ò dáa máa ń wá sí ẹ lọ́kàn. Àmọ́, tó o bá ń ronú nípa ìlérí tó o ṣe fún Jèhófà nígbà tó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún un, wàá lókun tí wàá fi borí ìdẹwò náà. Lọ́nà wo? Nígbà tó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, ńṣe lo sẹ́ ara ẹ. Ìyẹn ni pé o ti kọ gbogbo ìwà tínú Jèhófà ò dùn sí àtàwọn nǹkan tí ò dáa tó lè máa wù ẹ́. (Mát. 16:24) Torí náà, tí ìdẹwò bá dé, o ò ní ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ronú nǹkan tó o máa ṣe. Ìdí ni pé o ti mọ ohun tó o máa ṣe tẹ́lẹ̀, ìyẹn sì ni pé wàá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Ìpinnu ẹ ni pé o fẹ́ múnú Jèhófà dùn. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá dà bíi Jóòbù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó láwọn ìṣòro tó le gan-an, ó fi ìdánilójú sọ pé: “Mi ò ní fi ìwà títọ́ mi sílẹ̀!”—Jóòbù 27:5. w24.03 9 ¶6-7

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025

Thursday, August 28

Jèhófà wà nítòsí gbogbo àwọn tó ń ké pè é, nítòsí gbogbo àwọn tó ń ké pè é ní òtítọ́.—Sm. 145:18.

Jèhófà “Ọlọ́run ìfẹ́” wà pẹ̀lú wa! (2 Kọ́r. 13:11) Ó nífẹ̀ẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Torí náà, ó dá wa lójú pé ‘ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ yí wa ká.’ (Sm. 32:10) Bá a bá ṣe ń ronú lórí ìfẹ́ tí Jèhófà fi hàn sí wa, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa rí i pé ó ń bójú tó wa, àá sì túbọ̀ sún mọ́ ọn. A láǹfààní láti gbàdúrà sí Jèhófà, ká sì sọ fún un pé kó túbọ̀ fìfẹ́ hàn sí wa. A lè sọ gbogbo ohun tó ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa fún un, kó sì dá wa lójú pé ó mọ ohun tá a fẹ́, á sì ràn wá lọ́wọ́. (Sm. 145:19) Bó ṣe máa ń wù wá pé ká yáná nígbà tí òtútù bá mú wa, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe máa ń wù wá kí Jèhófà fìfẹ́ hàn sí wa. Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa lágbára gan-an, ìfẹ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ sì ni. Jẹ́ kínú ẹ máa dùn torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ. Torí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa gbà kí Jèhófà máa fìfẹ́ hàn sí wa, ká sì máa sọ pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà”!—Sm. 116:1. w24.01 31 ¶19-20

Máa Ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2025
Ẹ Káàbọ̀.
Ìkànnì yìí wà fún ṣíṣe ìwádìí látinú àwọn ìwé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní oríṣiríṣi èdè.
Bí o bá fẹ́ wa ìwé jáde, jọ̀wọ́ lọ sí jw.org.
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́