ORIN 63
Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ni Wá
- 1. Àwọn èèyàn ń bọ̀rìṣà - Wọn kò m’Ọlọ́run tòótọ́. - Olódùmarè ni; - Iṣẹ́ rẹ̀ ń fi hàn. - Àwọn ọlọ́run èké - Kò lè mọ ọjọ́ ọ̀la. - Kò sí ẹlẹ́rìí kankan fún wọn. - Wọ́n kéré sí Ọlọ́run wa. - (ÈGBÈ) - Ẹlẹ́rìí Jáà ni àwa. - À ń wàásù lọ láìbẹ̀rù. - Ọlọ́run wa ń sọ àsọtẹ́lẹ̀; - Gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló ń ṣẹ. 
- 2. À ń kéde orúkọ rẹ̀. - À ń jẹ́rìí rẹ̀ fáráyé. - À ń fìgboyà wàásù - Nípa ‘jọba rẹ̀. - À ń jẹ́ kọ́pọ̀ èèyàn mọ - Bóòótọ́ ṣe ń túni sílẹ̀. - Bá a ṣe ń kọ́ wọn, ó ńwọ̀ wọ́n lọ́kàn. - Àwọn náà wá ń yin Ọlọ́run. - (ÈGBÈ) - Ẹlẹ́rìí Jáà ni àwa. - À ń wàásù lọ láìbẹ̀rù. - Ọlọ́run wa ń sọ àsọtẹ́lẹ̀; - Gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló ń ṣẹ. 
- 3. Bá a ṣe ńgbórúkọ rẹ̀ ga - Ń mú kí ẹ̀gàn rẹ̀ kúrò. - À ń kìlọ̀ fẹ́ni ‘bi - Tó ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn. - Ṣùgbọ́n tó bá yí pa dà, - Jọ̀wọ́ Bàbá, dárí jì í. - Bí a ṣe ń sìn ọ́ látọkàn wá, - À ń láyọ̀, a sì nírètí. - (ÈGBÈ) - Ẹlẹ́rìí Jáà ni àwa. - À ń wàásù lọ láìbẹ̀rù. - Ọlọ́run wa ń sọ àsọtẹ́lẹ̀; - Gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló ń ṣẹ. 
((Tún wo Àìsá. 37:19; 55:11; Ìsík. 3:19.)