ORIN 144
Tẹjú Mọ́ Èrè Náà
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Afọ́jú yóò tún pa dà ríran, - Adití yóò sì pa dà gbọ́ràn, - Ọmọdé yóò máa fayọ̀ kọrin, - Àlàáfíà yóò kárí ayé, - Àwọn tó ti kú yóò tún jíǹde, - Sínú ayé tí kò sẹ́ṣẹ̀ mọ́. - (ÈGBÈ) - Wàá rí bí Jèhófà yóò ṣe ṣe é, - Tó o bá tẹjú mọ́ èrè náà. 
- 2. Àwọn ẹranko yóò máa gbé pọ̀. - Wọn kò ní máa para wọn jẹ mọ́. - Ọmọdé ni yóò máa darí wọn. - Wọn yóò máa tẹ̀ lé àṣẹ rẹ̀. - Kò ní sẹ́kún àti ọ̀fọ̀ mọ́. - Ìbẹ̀rù, ìrora kò sí mọ́. - (ÈGBÈ) - Wàá rí bí Jèhófà yóò ṣe ṣe é, - Tó o bá tẹjú mọ́ èrè náà. 
(Tún wo Àìsá. 11:6-9; 35:5-7; Jòh. 11:24.)