ORIN 73
Fún Wa Ní Ìgboyà
(Ìṣe 4:29)
- 1. Báa ṣe ń sọ̀rọ̀ Ìjọba náà, - Tá à ń kéde orúkọ rẹ, - Àwọn tó ń ta kò wá pọ̀ gan-an; - Wọ́n fẹ́ kó ‘tìjú bá wa. - Àwa kò bẹ̀rù èèyàn. - Ìwọ la gbọ́dọ̀ gbọ́ràn sí. - Fún wa ní ẹ̀mí rẹ, Jèhófà; - Jọ̀ọ́ bàbá, gbọ́ àdúrà wa. - (ÈGBÈ) - Fún wa nígboyà, ká wàásù. - Mú ìbẹ̀rù wa kúrò. - Kì wá láyà, fún wa lókun - Ká lè wàásù fáráyé - Pé Amágẹ́dọ́nì dé tán. - Àmọ́ kọ́jọ́ ńlá náà tó dé, - Fún wa nígboyà, ká wàásù; - Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa. 
- 2. Nígbà míì, ẹ̀rù lè bà wá. - O mọ̀ pérùpẹ̀ ni wá. - A mọ̀ pé wàá dúró tì wá; - Atóófaratì ni ọ́. - Àwọn ọ̀tá wa ń halẹ̀. - Wo bí wọ́n ṣe ń gbógun tì wá. - Ràn wá lọ́wọ́, ká má ṣe bọ́hùn - Báa ṣe ń wàásù lórúkọ rẹ. - (ÈGBÈ) - Fún wa nígboyà, ká wàásù. - Mú ìbẹ̀rù wa kúrò. - Kì wá láyà, fún wa lókun - Ká lè wàásù fáráyé - Pé Amágẹ́dọ́nì dé tán. - Àmọ́ kọ́jọ́ ńlá náà tó dé, - Fún wa nígboyà, ká wàásù; - Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa. 
(Tún wo 1 Tẹs. 2:2; Héb. 10:35.)