ORIN 71
Ọmọ Ogun Jèhófà Ni Wá
- 1. Ọmọ ogun Jáà ni wá; - Kristi lọ̀gá wa. - Bí Èṣù tiẹ̀ ń ta kò wá, - A wà ní ìṣọ̀kan. - À ń jọ́sìn tọkàntọkàn; - À ń wàásù fáyé. - A sì ti pinnu pé - A kò ní bẹ̀rù. - (ÈGBÈ) - Ọmọ ogun Jáà ni wá. - À ń tẹ̀ lé Kristi. - À ń fayọ̀ kéde pé - ’Jọba Rẹ̀ bẹ̀rẹ̀. 
- 2. Jèhófà là ńṣiṣẹ́ sìn - Bá a ṣe ń wá àwọn - Àgùntàn rẹ̀ tó sọ nù, - Tó sì fọ́n káàkiri. - A fẹ́ ṣèrànwọ́ fún wọn, - Ká sì tọ́jú wọn. - A máa ń pè wọ́n wá sí - Gbọ̀ngàn Ìjọba. - (ÈGBÈ) - Ọmọ ogun Jáà ni wá. - À ń tẹ̀ lé Kristi. - À ń fayọ̀ kéde pé - ’Jọba Rẹ̀ bẹ̀rẹ̀. 
- 3. Àwa lọmọ ogun Jáà - Tí Kristi ń darí. - Gbogbo wa ti gbára dì; - A ti wà ní sẹpẹ́. - Ó yẹ ká wà lójúfò, - Ká sì dúró gbọn-in. - Tí àtakò bá dé, - Ká jẹ́ olóòótọ́. - (ÈGBÈ) - Ọmọ ogun Jáà ni wá. - À ń tẹ̀ lé Kristi. - À ń fayọ̀ kéde pé - ’Jọba Rẹ̀ bẹ̀rẹ̀. 
(Tún wo Fílí. 1:7; Fílém. 2.)