ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Owó Kọ́ Ló Ń Mú Kéèyàn Jẹ́ Olódodo
Sófárì sọ pé Ọlọ́run máa ń sọ àwọn ẹni burúkú tó ní ọrọ̀ di ẹdun arinlẹ̀, ohun tó ń dọ́gbọ́n sọ ni pé Jóòbù ti ní láti ṣẹ Ọlọ́run (Job 20:5, 10, 15)
Jóòbù dáhùn pé: ‘Kí wá ló dé tí àwọn ẹni burúkú fi ń di ọlọ́rọ̀?’ (Job 21:7-9)
Àpẹẹrẹ Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn tó ń sin Jèhófà tọkàntọkàn lè má lówó lọ́wọ́ (Lk 9:58)
RONÚ LÓRÍ ÌBÉÈRÈ YÌÍ: Yálà àwọn tó ń sin Jèhófà tọkàntọkàn lówó tàbí wọn ò ní, kí ló ṣe pàtàkì sí wọn?—Lk 12:21; w07 8/1 29 ¶12.