ORIN 66
Ẹ Kéde Ìhìn Rere Náà
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Tipẹ́tipẹ́ laráyé ti jogún ẹ̀ṣẹ̀, - Àmọ́ Jèhófà ṣàánú wa, ó nífẹ̀ẹ́ wa. - Ó pinnu láti f’Ọmọ rẹ̀ ṣe Ọba wa, - Àmọ́ ó kọ́kọ́ ṣe ọ̀rọ̀ náà láṣìírí. - Ó ti wá fi àṣírí náà hàn wá báyìí. - Láìpẹ́, Ọmọ rẹ̀ máa bẹ̀rẹ̀ sí í - jọba ayé. - Jáà ti yan àwọn ẹni àmì òróró - Tó máa bá Jésù Ọmọ rẹ̀ jọba lọ́run. 
- 2. Jáà ti ṣètò pé tó bá d’àkókò òpin, - A máa kéde ìhìn rere yìí fáráyé. - Àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ ń fayọ̀ ràn wá lọ́wọ́; - Wọ́n ń tì wá lẹ́yìn bá a ṣe ńwàásù òtítọ́. - Iṣẹ́ pàtàkì ló já lé wa léjìká: - Ká máa yìn ọ́, ká jẹ́ - kórúkọ rẹ di mímọ́. - Ọlá ńlá ló jẹ́ bá a ṣe ń jẹ́ orúkọ mọ́ọ. - Tayọ̀tayọ̀ la ó máa ròyìn rẹ fáráyé. 
(Tún wo Máàkù 4:11; Ìṣe 5:31; 1 Kọ́r. 2:1, 7.)