ORIN 118
“Fún Wa Ní Ìgbàgbọ́ Sí I”
Bíi Ti Orí Ìwé
	- 1. Jèhófà, Bàbá wa, aláìpé ni wá. - Ìwà àìtọ́ lọkàn wa máa ń fà sí. - Ẹ̀ṣẹ̀ kan wà tó máa ń tètè wé mọ́ wa: - Àìnígbàgbọ́ nínú rẹ, Ọlọ́run. - (ÈGBÈ) - Jèhófà, jọ̀ọ́, fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i. - Ràn wá lọ́wọ́ bá a ṣe nílò rẹ̀ tó. - Nínú àánú rẹ, fún wa nígbàgbọ́ sí i, - Ká lè fìwà àtọ̀rọ̀ wa yìn ọ́. 
- 2. Láìsí ‘gbàgbọ́, a kò lè múnú rẹ dùn. - A gbọ́dọ̀ gbà pé ìgbàgbọ́ lérè. - Ìgbàgbọ́ wa máa ń jẹ́ ká nífaradà; - Ó ń dáàbò bò wá, a sì nírètí. - (ÈGBÈ) - Jèhófà, jọ̀ọ́, fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i. - Ràn wá lọ́wọ́ bá a ṣe nílò rẹ̀ tó. - Nínú àánú rẹ, fún wa nígbàgbọ́ sí i, - Ká lè fìwà àtọ̀rọ̀ wa yìn ọ́. 
(Tún wo Jẹ́n. 8:21; Héb. 11:6; 12:1.)