ORIN 136
“Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Èrè” Látọ̀dọ̀ Jèhófà
- 1. Jèhófà jẹ́ olóòótọ́, ó rí àwọn - Tó ń fi gbogbo ọkàn wọn sìn ín. - Ó mọ àwọn ohun tí wọ́n pàdánù - Bí wọ́n ṣe ń wá Ìjọba rẹ̀. - Tó o bá ti filé, fẹbí, fọ̀rẹ́ sílẹ̀, - Gbogbo rẹ̀ ni Ọlọ́run rí. - Àwọn ará kárí ayé nífẹ̀ẹ́ rẹ; - Wàá tún ríyè àìnípẹ̀kun. - (ÈGBÈ) - Kí Jèhófà fìbùkún síṣẹ́ rẹ, - Kó fún ọ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ èrè. - Kó máa ṣọ́ ẹ, kó dáàbò bò ẹ́; - Jèhófà jólóòótọ́, onínú rere. 
- 2. Nígbà mí ì, ìdààmú àtìsoríkọ́ - Lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa. - Àtijẹ àtimu sì lè má rọrùn - A mọ̀ dájú pé Jèhófà, - Olùgbọ́ àdúrà tó ṣeé gbára lé, - Ẹgbẹ́ ará tó nífẹ̀ẹ́ wa, - Ẹ̀mí Ọlọ́run àtẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Rẹ̀, - Yóò mú ìtùnú wá bá wa. - (ÈGBÈ) - Kí Jèhófà fìbùkún síṣẹ́ rẹ, - Kó fún ọ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ èrè. - Kó máa ṣọ́ ẹ, kó dáàbò bò ẹ́; - Jèhófà jólóòótọ́, onínú rere. 
(Tún wo Oníd. 11:38-40; Àìsá. 41:10.)