MARCH 23-29, 2026
ORIN 18 A Mọyì Ìràpadà
Kí Lo Máa Ṣe Kó O Lè Fi Hàn Pé O Mọyì Ìràpadà?
“Ìfẹ́ tí Kristi ní sọ ọ́ di dandan fún wa.”—2 KỌ́R. 5:14.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
Ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè ṣe ká lè fi hàn pé a mọyì ìràpadà.
1-2. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá ń ronú nípa ìràpadà tí Jésù san, kí sì nìdí? (2 Kọ́ríńtì 5:14, 15) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
KÁ SỌ pé ẹnì kan fà ẹ́ yọ lábẹ́ ilé tó wó, ṣé o ò ní mọyì oore ńlá tẹni náà ṣe bó ṣe gba ẹ̀mí ẹ là? Tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ìwọ nìkan kọ́ lẹni náà yọ lábẹ́ ilé náà, ó dájú pé wàá fẹ́ dìídì lọ dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ kó o lè fi hàn pé o mọyì ohun tó ṣe fún ẹ.
2 Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a ò lè gbara wa sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé tá a jogún. Àmọ́, ìràpadà tí Jésù san ti gbà wá ní ti pé, (1) Jèhófà lè dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, (2) a lè bọ́ lọ́wọ́ àìpé àti ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún àti (3) a lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Ìràpadà yìí tí mú ká nírètí láti wà láàyè títí láé nínú ayé tuntun tí Jèhófà ṣèlérí. Kò sí àní-àní pé ìràpadà yìí fi hàn pé Jésù nífẹ̀ẹ́ wa, kódà ó ti nífẹ̀ẹ́ wa kó tó wá sáyé. (Òwe 8:30, 31) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé “ìfẹ́ tí Kristi ní sọ ọ́ di dandan fún wa” láti ṣe àwọn nǹkan kan. (Ka 2 Kọ́ríńtì 5:14, 15.) Ìyẹn fi hàn pé àwọn nǹkan kan wà tá a gbọ́dọ̀ ṣe táá fi hàn pé lóòótọ́ la mọyì ìràpadà tí Jésù san.
Tí ẹnì kan bá yọ wá lábẹ́ ilé tó wó tàbí tó gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún, ó yẹ ká dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ ẹni náà (Wo ìpínrọ̀ 1-2)
3. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé bó o ṣe máa fi hàn pé o mọyì ìràpadà lè yàtọ̀ sí ti ẹlòmíì?
3 Kí lo lè ṣe táá fi hàn pé o mọyì ìràpadà? Ìdáhùn ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè yàtọ̀ síra. Kí nìdí? Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí. Ká sọ pé àwọn mẹ́ta fẹ́ pàdé ní ìlú kan, ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sì ni wọ́n ti ń bọ̀, ó dájú pé ọ̀nà tí kálukú wọn máa gbà débẹ̀ máa yàtọ̀ síra. Lọ́nà kan náà, bí kálukú wa ṣe máa fi hàn pé òun mọyì ìràpadà lè yàtọ̀ síra torí pé àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà ò rí bákan náà. Torí náà nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí àwùjọ mẹ́ta yìí ṣe lè fi hàn pé àwọn mọyì ìràpadà: Àwọn ni (1) àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, (2) àwọn tó ti ṣèrìbọmi àti (3) àwọn àgùntàn tó sọnù.
ÀWỌN TÁ À Ń KỌ́ LẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ
4. Kí ló jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀rọ̀ àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe pàtàkì lójú Jèhófà?
4 Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, má gbàgbé pé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó ò ń ṣe yìí fi hàn pé o wà lára àwọn tí Jèhófà ń fà sọ́dọ̀ ara ẹ̀, kí wọ́n lè di ọ̀rẹ́ ẹ̀. (Jòh. 6:44; Ìṣe 13:48) Bíbélì sọ pé: “Jèhófà ni olùṣàyẹ̀wò ọkàn.” Ìyẹn fi hàn pé ó ń rí gbogbo bó o ṣe ń sapá láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa òun, inú ẹ̀ sì ń dùn bó ṣe ń rí i tó ò ń tẹ̀ síwájú, tó o sì ń ṣe àwọn ìyípadà táá múnú ẹ̀ dùn. (Òwe 17:3; 27:11) Ìràpadà tí Jésù san ló jẹ́ kó o lè sún mọ́ Ọlọ́run. (Róòmù 5:10, 11) Jẹ́ kí òótọ́ ọ̀rọ̀ yìí máa wà lọ́kàn ẹ nígbà gbogbo.
5. Báwo làwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú Fílípì 3:16?
5 Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, báwo lo ṣe lè fi hàn pé o mọyì ìràpadà? Ohun kan tó o lè ṣe ni pé kó o tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún àwọn ará Fílípì, tó sọ pé: “Níbi tí a tẹ̀ síwájú dé, ẹ jẹ́ kí a máa rìn létòlétò ní ọ̀nà kan náà.” (Fílí. 3:16) Ìtumọ̀ Bíbélì míì sọ pé: “Ibi tí a ti dé ná, ẹ jẹ́ kí á máa rìn ní ojú ọ̀nà kan náà.” Torí náà, á dáa kó o tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù yìí kó o sì pinnu pé o ò ní jẹ́ kí ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni dí ẹ lọ́wọ́ bó o ṣe ń rìn lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè.—Mát. 7:14; Lúùkù 9:62.
6. Kí làwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lè ṣe tí ò bá rọrùn fún wọn láti ṣe àwọn ìyípadà kan? (Diutarónómì 30:11-14) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
6 Ká sọ pé kò rọrùn fún ẹ láti fara mọ́ ohun kan tó o kọ́ nínú Bíbélì, kí lo lè ṣe? Á dáa kó o ṣèwádìí, kó o sì bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kọ́rọ̀ náà túbọ̀ yé ẹ dáadáa. (Sm. 86:11) Tọ́rọ̀ náà bá ṣì ń rú ẹ lójú, o lè fi sílẹ̀ ná, àmọ́ má dáwọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ẹ dúró. Ká wá sọ pé kò rọrùn fún ẹ láti jáwọ́ nínú ìwà kan tí Bíbélì sọ pé kò dáa ńkọ́? Máa rántí pé Jèhófà kì í sọ pé ká ṣe ohun tó ju agbára wa lọ, ó sì dájú pé o lè ṣe ohun tó fẹ́. (Ka Diutarónómì 30:11-14.) Jèhófà tún ṣèlérí pé òun máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Àìsá. 41:10, 13; 1 Kọ́r. 10:13) Torí náà, má jẹ́ kó sú ẹ. Dípò kó o máa da ara ẹ láàmú nípa àwọn nǹkan tó ṣòro fún ẹ láti ṣe, máa ronú nípa gbogbo nǹkan tí Jèhófà ti ṣe fún ẹ títí kan ìràpadà. Bó o ṣe túbọ̀ ń nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wàá rí i pé “àwọn àṣẹ rẹ̀ kò nira.”—1 Jòh. 5:3.a
Jèhófà kì í retí pé ká ṣe ohun tó ju agbára wa lọ, á sì ràn wá lọ́wọ́ láti fi àwọn ìlànà ẹ̀ sílò (Wo ìpínrọ̀ 6)
7. Kí ló yẹ káwọn ọmọ tí òbí wọn jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa rántí?
7 Tó bá jẹ́ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn òbí ẹ, tó sì jẹ́ pé àwọn ló ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ńkọ́? Máa rántí pé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìwọ náà. Kódà, ìwọ ni akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ṣe pàtàkì jù táwọn òbí ẹ ní. Bíbélì sọ pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, á sì sún mọ́ yín.” (Jém. 4:8; 1 Kíró. 28:9) Tó o bá ń ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kó o sún mọ́ Jèhófà, òun náà máa sún mọ́ ẹ. Kì í ṣe torí pé àwọn òbí ẹ jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ṣe ń fà ẹ́ sọ́dọ̀ ara ẹ̀, àmọ́ ó ń ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ ẹ, ó sì fẹ́ kó o di ọ̀rẹ́ òun. Kí ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ẹ láti di ọ̀rẹ́ Jèhófà? Ìràpadà ni, ìyẹn ẹ̀bùn iyebíye tí kò yẹ kó o fọwọ́ yẹpẹrẹ mú. (Róòmù 5:1, 2) Torí náà, kó o tó lọ sí Ìrántí Ikú Kristi ọdún yìí, á dáa kó o ronú nípa àǹfààní tí ikú Jésù ṣe fún ẹ. Lẹ́yìn náà, ronú nípa àwọn nǹkan tó o lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà táá fi hàn pé o mọyì ìràpadà tí Jèhófà pèsè nípasẹ̀ Jésù Ọmọ rẹ̀.b
ÀWỌN TÓ TI ṢÈRÌBỌMI
8. Báwo làwọn tó ti ṣèrìbọmi ṣe ń fi hàn pé àwọn nígbàgbọ́, àwọn sì mọyì ìràpadà?
8 Tó bá jẹ́ pé o ti ṣèrìbọmi, á jẹ́ pé onírúurú nǹkan lo ti ṣe tó fi hàn pé o nígbàgbọ́, o sì mọyì ìràpadà. Bí àpẹẹrẹ, o ti ṣe àwọn nǹkan tó jẹ́ kó o sún mọ́ Jèhófà, o sì ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ò ń pa àṣẹ Jésù mọ́ pé ká máa wàásù, ká sì máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. Kò tán síbẹ̀ o, o ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, o sì ṣèrìbọmi. Ṣé ìgbà kan wà tí wọ́n ti ṣe inúnibíni sí ẹ torí pé ò ń ṣe ìjọsìn tòótọ́? (2 Tím. 3:12) Bó o ṣe fara dà á, tó o sì jẹ́ olóòótọ́ fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, o sì mọyì ìràpadà tó pèsè nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀.—Héb. 12:2, 3.
9. Ewu wo ló yẹ káwọn tó ti ṣèrìbọmi ṣọ́ra fún?
9 Ewu kan wà tó yẹ káwa tá a ti ṣèrìbọmi ṣọ́ra fún. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, a lè má fi bẹ́ẹ̀ mọyì ìràpadà mọ́. Kí ló lè mú kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni tó ń gbé ní Éfésù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Jésù gbóríyìn fún wọn torí pé wọ́n fara da ọ̀pọ̀ ìṣòro. Àmọ́, ó sọ fún wọn pé: “Ohun tí mo rí tí o ṣe tí kò dáa ni pé o ti fi ìfẹ́ tí o ní níbẹ̀rẹ̀ sílẹ̀.” (Ìfi. 2:3, 4) Ohun tí Jésù sọ yìí jẹ́ ká rí i pé tí Kristẹni kan ò bá ṣọ́ra, bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ìjọsìn ẹ̀ lè di afaraṣe-má-fọkàn-ṣe. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè máa gbàdúrà, kó máa lọ sípàdé, kó sì máa wàásù, àmọ́ káwọn nǹkan yẹn má tọkàn ẹ̀ wá. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, kì í ṣe torí pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ló ṣe ń ṣe gbogbo ohun tó ń ṣe. Kí lo wá lè ṣe tó ò bá nítara mọ́ tàbí tó ò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ìjọsìn Jèhófà bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́?
10. Báwo la ṣe lè “máa ronú lórí” ohun tá à ń ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà, ká sì jẹ́ “kó gbà [wá] lọ́kàn”? (1 Tímótì 4:13, 15)
10 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba Tímótì níyànjú pé kó “máa ronú lórí” ohun tó ń ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà, kó sì jẹ́ “kó gbà [á] lọ́kàn.” (Ka 1 Tímótì 4:13, 15.) Ó yẹ káwa náà fi ìmọ̀ràn yẹn sílò, ká máa ronú nípa àwọn nǹkan táá jẹ́ ká túbọ̀ nítara lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, ‘kí ìnà ẹ̀mí sì máa jó nínú wa.’ (Róòmù 12:11; wo àlàyé ọ̀rọ̀ “Be aglow with the spirit” nínú nwtsty-E.) Bí àpẹẹrẹ, á dáa kó o túbọ̀ máa múra ìpàdé sílẹ̀ dáadáa, ìyẹn á jẹ́ kó o túbọ̀ máa pọkàn pọ̀ tó o bá wà níbẹ̀. Bákan náà, tó o bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ láyè ara ẹ, á dáa kó o wá ibì kan tó pa rọ́rọ́ kó o lè ronú jinlẹ̀ lórí ohun tó ò ń kọ́. Bó ṣe jẹ́ pé tá a bá kó igi síná, iná náà á máa jó dáadáa. Lọ́nà kan náà, tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan tá a mẹ́nu kàn yìí, àá túbọ̀ mọyì gbogbo ohun tí Jèhófà ṣe fún wa títí kan ìràpadà. Torí náà, láwọn ọ̀sẹ̀ tó ṣáájú Ìrántí Ikú Kristi, o ò ṣe ronú nípa àwọn nǹkan rere tá à ń gbádùn torí pé a jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá túbọ̀ mọyì ìràpadà, ìyẹn ẹ̀bùn tó jẹ́ kó o lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà.
11-12. Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé o ò nítara mọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ṣé ìyẹn fi hàn pé ẹ̀mí Ọlọ́run ò ṣiṣẹ́ lára ẹ mọ́? Ṣàlàyé. (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
11 Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé o ò nítara bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, má jẹ́ kó sú ẹ, má sì ronú pé ẹ̀mí Ọlọ́run ò ṣiṣẹ́ lára ẹ mọ́. Rántí ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ ẹ̀ nígbà tó ń kọ̀wé sáwọn ará Kọ́ríńtì, ó ní: “Tí kò bá ti inú mi wá, iṣẹ́ ìríjú kan ṣì wà ní ìkáwọ́ mi.” (1 Kọ́r. 9:17) Kí lohun tó sọ yìí túmọ̀ sí?
12 Àwọn ìgbà míì wà tí kì í wu Pọ́ọ̀lù láti wàásù. Síbẹ̀, ó pinnu pé òun ò ní dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù dúró láìka bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀ lákòókò yẹn. Ìwọ náà lè ṣe bíi ti Pọ́ọ̀lù. O lè pinnu pé wàá ṣe ohun tó tọ́ kódà tí ò bá wù ẹ́ láti ṣe. Torí náà, bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó máa wù ẹ́ láti ‘gbé ìgbésẹ̀, kó sì fún ẹ ní agbára láti ṣe é.’ (Fílí. 2:13) Má ṣe jáwọ́ nínú àwọn nǹkan táá jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Bó pé bó yá, àwọn nǹkan tó ò ń ṣe yìí máa mú kó o túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, á sì mú kó o pa dà nítara lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀.
Má ṣe dáwọ́ àwọn nǹkan tó ò ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà dúró tí ò bá tiẹ̀ wù ẹ́ kó o ṣe wọ́n (Wo ìpínrọ̀ 11-12)
13. Báwo la ṣe lè máa dán ara wa wò bóyá a ṣì wà “nínú ìgbàgbọ́”?
13 Látìgbàdégbà, ó yẹ ká máa ṣe ohun tí 2 Kọ́ríńtì 13:5 sọ, ó ní: “Ẹ máa dán ara yín wò bóyá ẹ wà nínú ìgbàgbọ́; ẹ máa wádìí ohun tí ẹ̀yin fúnra yín jẹ́.” Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a lè bi ara wa láwọn ìbéèrè bíi: ‘Ṣé àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run ni mo fi ṣáájú láyé mi?’ (Mát. 6:33) ‘Ṣé àwọn eré ìnàjú tí mò ń wò fi hàn pé mo kórìíra àwọn nǹkan tó burú?’ (Sm. 97:10) ‘Ṣé mò ń ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan túbọ̀ wà láàárín àwọn ará?’ (Éfé. 4:2, 3) Lákòókò Ìrántí Ikú Kristi, a máa ń ronú nípa ìràpadà tó jẹ́ ẹ̀bùn pàtàkì tí Jèhófà fún wa. Torí náà, á dáa ká fi àwọn ìbéèrè yìí yẹ ara wa wò, ká lè mọ̀ bóyá ohun tí Kristi fẹ́ là ń ṣe àbí ohun tó wù wá.c
ÀWỌN ÀGÙNTÀN TÓ SỌNÙ
14. Kí ló lè mú káwọn Kristẹni kan má wá sípàdé mọ́?
14 Àwọn Kristẹni kan ti sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ oṣù tàbí ọdún, àmọ́ ní báyìí wọn ò wá sípàdé mọ́. Kí nìdí? Kòókòó jàn-án-jàn-án ìgbésí ayé ni ò jẹ́ káwọn kan wá sípàdé mọ́. (Lúùkù 21:34) Ohun tó fà á táwọn míì ò fi wá mọ́ ni ohun tí ẹnì kan nínú ìjọ sọ tàbí ohun tó ṣe. (Jém. 3:2) Ní tàwọn míì, ṣe ni wọ́n dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, ìtìjú ò sì jẹ́ kí wọ́n wá ìrànlọ́wọ́. Ohun yòówù kó fà á, kí lo lè ṣe tó bá jẹ́ pé o kì í lọ sípàdé mọ́? Kí ni ìràpadà tó jẹ́ ẹ̀bùn tí Jèhófà fún wa lè mú kó o ṣe?
15. Kí ni Jèhófà ń ṣe tó fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn àgùntàn tó sọnù jẹ ẹ́ lógún? (Ìsíkíẹ́lì 34:11, 12, 16)
15 Ronú nípa bí ọ̀rọ̀ àwọn àgùntàn tó sọnù ṣe rí lára Jèhófà. Kì í pa wọ́n tì, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló máa ń wá wọn rí. Á bọ́ wọn, á sì ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa dà sọ́dọ̀ ẹ̀. (Ka Ìsíkíẹ́lì 34:11, 12, 16.) Ṣé ohun tí Jèhófà ń ṣe fún ìwọ náà nìyẹn? Bẹ́ẹ̀ ni! Tó bá jẹ́ pé ò ń ka àpilẹ̀kọ yìí báyìí, á jẹ́ pé o ṣì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Má gbàgbé pé Jèhófà rí ohun tó dáa lọ́kàn ẹ ló ṣe fà ẹ́ wá sínú òtítọ́. Títí di báyìí, ó ṣì ń rí ohun tó dáa lọ́kàn ẹ, ó sì fẹ́ kó o pa dà sọ́dọ̀ òun.
16. Kí làwọn àgùntàn tó sọnù lè ṣe kí wọ́n lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
16 Ronú nípa ọ̀rọ̀ tó ń tuni nínú tó wà nínú ìwé Jọ̀wọ́ Pa Dà Sọ́dọ̀ Jèhófà, ó sọ pé: “Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà á wà pẹ̀lú rẹ bó o ṣe ń pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀. Á mú kó o borí àníyàn, á bá ẹ yanjú ohun tó ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ, á sì jẹ́ kó o ní àlááfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn téèyàn máa ń ní tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bá mọ́. Èyí á mú kó wù ẹ́ láti tún pa dà máa sin Jèhófà pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn olùjọsìn bíi tìẹ.” Bákan náà, má gbàgbé pé àwọn alàgbà ṣe tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́. Àwọn alàgbà yìí “dà bí ibi tó ṣeé fara pa mọ́ sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù, ibi ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò.” (Àìsá. 32:2) Torí pé o mọyì ìràpadà, á dáa kó o bi ara ẹ pé, ‘Àwọn nǹkan wo ni mo lè ṣe báyìí kí n lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà?’ (Àìsá. 1:18; 1 Pét. 2:25) Bí àpẹẹrẹ, ṣé o lè lọ sípàdé? Ṣé o lè ní kí alàgbà kan ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà? Alàgbà náà lè ṣètò pé kẹ́nì kan kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún àkókò díẹ̀. Tó o bá gbàdúrà nípa ẹ̀, tó o sì ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti fi hàn pé o mọyì ìràpadà, ó dájú pé Jèhófà máa bù kún ìsapá ẹ.
Bi ara ẹ pé, ‘Àwọn nǹkan wo ni mo lè ṣe báyìí kí n lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà?’ (Wo ìpínrọ̀ 16)
KÍ NI WÀÁ ṢE?
17-18. Kí ló yẹ kó o ṣe láwọn ọjọ́ tó ṣáájú Ìrántí Ikú Kristi tọdún yìí?
17 Jésù sọ pé Jèhófà pèsè ìràpadà “kí gbogbo ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòh. 3:16) Ìràpadà yìí ni Jèhófà lò láti gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Torí náà, gbogbo ìgbà ló yẹ ká mọyì ẹ̀bùn pàtàkì yìí. (Róòmù 3:23, 24; 2 Kọ́r. 6:1) Láwọn ọjọ́ tó ṣáájú Ìrántí Ikú Kristi, a máa ń ronú nípa ìfẹ́ tí Jèhófà àti Jésù fi hàn sí wa, ó sì yẹ kí ìfẹ́ yìí mú ká máa ṣe ohun táá múnú wọn dùn.
18 Kí lo máa ṣe láti fi hàn pé o mọyì ìràpadà? Ìdáhùn ẹ lè yàtọ̀ sí ti ẹlòmíì. Àmọ́ jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa bù kún ẹ bó o ṣe ń dara pọ̀ mọ́ àwọn ará wa kárí ayé tí wọ́n ti pinnu pé àwọn ò ní “wà láàyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tó kú fún wọn.”—2 Kọ́r. 5:15.
ORIN 14 Ẹ Yin Ọba Tuntun Tó Jẹ Lórí Ayé
a Kó o lè fi ohun tó ò ń kọ́ sílò, máa ṣe ohun tó wà nínú àpótí náà “Ohun tó yẹ kó o ṣe” tó wà níparí ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!
b Kó o lè mọ ohun tó o lè ṣe láti tẹ̀ síwájú, ka àpilẹ̀kọ náà “Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—‘Ẹ Máa Ṣiṣẹ́ Ìgbàlà Yín Yọrí’” nínú Ilé Ìṣọ́ December 2017.
c Tó o bá fẹ́ mọ ohun tó o lè ṣe kó o lè máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, ka àpilẹ̀kọ náà “Kí Ní Ń Sún Ọ Láti Ṣiṣẹ́sin Ọlọrun?” nínú Ilé Ìṣọ́ June 15, 1995.