15 Fáráò sọ fún Jósẹ́fù pé: “Mo lá àlá kan, àmọ́ kò sẹ́ni tó lè túmọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n mo ti gbọ́ pé tí wọ́n bá rọ́ àlá fún ọ, o lè túmọ̀ rẹ̀.”+16 Jósẹ́fù dá Fáráò lóhùn pé: “Mi ò já mọ́ nǹkan kan! Ọlọ́run yóò sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Fáráò.”+
28 Àmọ́ Ọlọ́run kan wà ní ọ̀run, tó jẹ́ Ẹni tó ń ṣí àwọn àṣírí payá,+ ó sì ti jẹ́ kí Ọba Nebukadinésárì mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́. Àlá rẹ nìyí, àwọn ìran tí o sì rí nígbà tí o dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ nìyí:
45 bí o ṣe rí i tí òkúta kan gé kúrò lára òkè náà, tó jẹ́ pé ọwọ́ kọ́ ló gé e, tó sì fọ́ irin, bàbà, amọ̀, fàdákà àti wúrà túútúú.+ Ọlọ́run Atóbilọ́lá ti jẹ́ kí ọba mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.+ Òótọ́ ni àlá náà, ìtumọ̀ rẹ̀ sì ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé.”