18 Bí ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ń bọ́ lọ* (torí ó ń kú lọ), ó sọ ọmọ náà ní Bẹni-ónì,* àmọ́ bàbá rẹ̀ sọ ọ́ ní Bẹ́ńjámínì.*+19 Réṣẹ́lì wá kú, wọ́n sì sin ín ní ojú ọ̀nà Éfúrátì, ìyẹn Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.+
38 Àmọ́ ó sọ pé: “Ọmọ mi ò ní bá yín lọ, torí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nìkan ló sì ṣẹ́ kù.+ Bí jàǹbá bá lọ ṣe é ní ìrìn àjò tí ẹ fẹ́ lọ yìí, ó dájú pé ẹ ó mú kí n ṣọ̀fọ̀+ wọnú Isà Òkú*+ pẹ̀lú ewú orí mi.”
7 Wọ́n fèsì pé: “Ọkùnrin náà bi wá nípa ara wa àti àwọn mọ̀lẹ́bí wa pé, ‘Ṣé bàbá yín ṣì wà láàyè? Ṣé ẹ ní arákùnrin míì?’ A sì sọ òótọ́ fún un.+ Báwo la ṣe fẹ́ mọ̀ pé yóò sọ pé, ‘Ẹ mú àbúrò yín wá’?”+