33 Tí Fáráò bá pè yín, tó sì bi yín pé, ‘Iṣẹ́ wo lẹ̀ ń ṣe?’ 34 Kí ẹ sọ pé, ‘Àti kékeré ni àwa ìránṣẹ́ rẹ ti ń tọ́jú ẹran ọ̀sìn, àwa àti àwọn baba ńlá+ wa,’ kí ẹ lè máa gbé ilẹ̀ Góṣénì,+ torí àwọn ará Íjíbítì+ kórìíra gbogbo àwọn tó ń da àgùntàn.”
26 Àmọ́ Mósè sọ pé: “Kò tọ́ ká ṣe bẹ́ẹ̀, torí àwọn ará Íjíbítì máa kórìíra ohun tí a fẹ́ fi rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run wa.+ Tí a bá fi ohun tí àwọn ará Íjíbítì kórìíra rúbọ níṣojú wọn, ṣé wọn ò ní sọ wá lókùúta?