42 Ká ní Ọlọ́run bàbá mi,+ Ọlọ́run Ábúráhámù àti Ẹni tí Ísákì ń bẹ̀rù*+ kò tì mí lẹ́yìn ni, ọwọ́ òfo lò bá ní kí n kúrò lọ́dọ̀ rẹ. Ọlọ́run ti rí ìyà tó ń jẹ mí àti iṣẹ́ àṣekára tí mo fi ọwọ́ mi ṣe, ìdí nìyẹn tó fi bá ọ wí lóru àná.”+
6 Ó sọ pé: “Èmi ni Ọlọ́run bàbá rẹ, Ọlọ́run Ábúráhámù,+ Ọlọ́run Ísákì+ àti Ọlọ́run Jékọ́bù.”+ Ni Mósè bá fojú pa mọ́, torí ẹ̀rù ń bà á láti wo Ọlọ́run tòótọ́.