33 Jékọ́bù bá wòkè, ó sì rí Ísọ̀ tó ń bọ̀ pẹ̀lú ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọkùnrin.+ Torí náà, ó pín àwọn ọmọ sọ́dọ̀ Líà, Réṣẹ́lì àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin+ méjèèjì. 2 Ó fi àwọn ìránṣẹ́bìnrin náà àti àwọn ọmọ wọn síwájú,+ Líà àti àwọn ọmọ rẹ̀ tẹ̀ lé wọn,+ Réṣẹ́lì+ àti Jósẹ́fù sì wà lẹ́yìn wọn.