ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Nọ́ńbà 21:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 Àwọn èèyàn náà wá ń sọ̀rọ̀ sí Ọlọ́run àti Mósè+ pé: “Kí ló dé tí ẹ kó wa kúrò ní Íjíbítì ká lè wá kú sínú aginjù? Kò sí oúnjẹ, kò sí omi,+ a* sì ti kórìíra oúnjẹ játijàti+ yìí.”*

  • Diutarónómì 8:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 má ṣe gbéra ga nínú ọkàn rẹ,+ kó sì mú kí o gbàgbé Jèhófà Ọlọ́run rẹ tó mú ọ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, kúrò ní ilé ẹrú,+

  • Diutarónómì 8:16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 ó sì fi mánà bọ́ ọ+ nínú aginjù, èyí tí àwọn bàbá rẹ ò mọ̀, kó lè rẹ̀ ọ́ sílẹ̀,+ kó sì dán ọ wò, kó lè ṣe ọ́ láǹfààní lọ́jọ́ ọ̀la.+

  • Jóṣúà 5:11, 12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ èso ilẹ̀ náà ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé Ìrékọjá, wọ́n jẹ búrẹ́dì aláìwú+ àti àyangbẹ ọkà lọ́jọ́ yẹn kan náà. 12 Mánà ò rọ̀ fún wọn ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé ọjọ́ tí wọ́n jẹ lára èso ilẹ̀ náà; àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò rí mánà kó mọ́,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ èso ilẹ̀ Kénáánì ní ọdún yẹn.+

  • Jòhánù 6:31, 32
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 31 Àwọn baba ńlá wa jẹ mánà ní aginjù,+ bí a ṣe kọ ọ́ pé: ‘Ó fún wọn ní oúnjẹ láti ọ̀run kí wọ́n lè jẹ.’”+ 32 Jésù wá sọ fún wọn pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, Mósè ò fún yín ní oúnjẹ láti ọ̀run, àmọ́ Baba mi fún yín ní oúnjẹ tòótọ́ láti ọ̀run.

  • Jòhánù 6:58
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 58 Oúnjẹ tó sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run nìyí. Kò dà bí ìgbà tí àwọn baba ńlá yín jẹun, síbẹ̀ tí wọ́n kú. Ẹnikẹ́ni tó bá ń jẹ oúnjẹ yìí máa wà láàyè títí láé.”+

  • 1 Kọ́ríńtì 10:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Ní báyìí, ẹ̀yin ará, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé gbogbo àwọn baba ńlá wa wà lábẹ́ ìkùukùu,*+ gbogbo wọn gba inú òkun kọjá,+

  • 1 Kọ́ríńtì 10:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 3 gbogbo wọn jẹ oúnjẹ tẹ̀mí+ kan náà,

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́