12 “Ní báyìí, ìwọ Ísírẹ́lì, kí ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ kí o ṣe?+ Kò ju pé: kí o máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ kí o máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀,+ kí o máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, kí o máa fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara* rẹ sin Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+
5 Kí ẹ ṣáà rí i pé ẹ̀ ń tẹ̀ lé àṣẹ àti Òfin tí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà fún yín,+ kí ẹ máa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run yín,+ kí ẹ máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀,+ kí ẹ máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́,+ kí ẹ rọ̀ mọ́ ọn,+ kí ẹ sì máa fi gbogbo ọkàn yín àti gbogbo ara* yín+ sìn ín.”+
10 Àmọ́, Jésù sọ fún un pé: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì! Torí a ti kọ ọ́ pé: ‘Jèhófà* Ọlọ́run rẹ ni o gbọ́dọ̀ jọ́sìn,+ òun nìkan ṣoṣo sì ni o gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún.’”+