Ẹ́kísódù 29:4 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 4 “Kí o mú Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé,+ kí o sì fi omi wẹ̀ wọ́n.+ Ẹ́kísódù 29:7 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 7 kí o mú òróró àfiyanni,+ kí o sì dà á sí i lórí láti fòróró yàn án.+ Ẹ́kísódù 30:30 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 30 Kí o fi òróró yan Áárónì+ àti àwọn ọmọ rẹ̀,+ kí o sì sọ wọ́n di mímọ́ kí wọ́n lè di àlùfáà mi.+ Ìṣe 10:38 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 38 nípa Jésù tó wá láti Násárẹ́tì, bí Ọlọ́run ṣe fi ẹ̀mí mímọ́+ àti agbára yàn án, tí ó sì lọ káàkiri ilẹ̀ náà, tí ó ń ṣe rere, tí ó sì ń wo gbogbo àwọn tí Èṣù ń ni lára sàn,+ torí pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.+ 2 Kọ́ríńtì 1:21 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 21 Àmọ́ Ọlọ́run ni ẹni tó ń mú kó dájú pé àwa àti ẹ̀yin jẹ́ ti Kristi, òun ló sì yàn wá.+
38 nípa Jésù tó wá láti Násárẹ́tì, bí Ọlọ́run ṣe fi ẹ̀mí mímọ́+ àti agbára yàn án, tí ó sì lọ káàkiri ilẹ̀ náà, tí ó ń ṣe rere, tí ó sì ń wo gbogbo àwọn tí Èṣù ń ni lára sàn,+ torí pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.+