8 Ó sọ nípa Léfì pé:+
“Túmímù rẹ àti Úrímù + rẹ jẹ́ ti ẹni tó jẹ́ adúróṣinṣin sí ọ,+
Ẹni tí o dán wò ní Másà.+
O bẹ̀rẹ̀ sí í bá a fà á lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi Mẹ́ríbà,+
9 Ẹni tó sọ nípa bàbá àti ìyá rẹ̀ pé, ‘Mi ò kà wọ́n sí.’
Ó tiẹ̀ tún kọ àwọn arákùnrin rẹ̀,+
Ó sì pa àwọn ọmọ rẹ̀ tì.
Torí wọ́n tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ rẹ,
Wọ́n sì pa májẹ̀mú rẹ mọ́.+