15 Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má ṣe bá àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà dá májẹ̀mú, torí tí wọ́n bá ń bá àwọn ọlọ́run wọn ṣèṣekúṣe, tí wọ́n sì ń rúbọ sí àwọn ọlọ́run wọn,+ ẹnì kan yóò pè ọ́ wá, wàá sì jẹ nínú ẹbọ rẹ̀.+
16 Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Wò ó! O ò ní pẹ́ kú,* àwọn èèyàn yìí á sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ọlọ́run àjèjì tó yí wọn ká ní ilẹ̀ tí wọ́n ń lọ ṣe àgbèrè ẹ̀sìn.+ Wọ́n á pa mí tì,+ wọ́n á sì da májẹ̀mú mi tí mo bá wọn dá.+