ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 22:18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 18 “O ò gbọ́dọ̀ dá àjẹ́ sí.+

  • Léfítíkù 19:31
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 31 “‘Ẹ má tọ àwọn abẹ́mìílò lọ.+ Ẹ má sì wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn woṣẹ́woṣẹ́,+ kí wọ́n má bàa sọ yín di aláìmọ́. Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.

  • Léfítíkù 20:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 “‘Ní ti ẹni tó bá tọ àwọn abẹ́mìílò+ lọ àti àwọn woṣẹ́woṣẹ́+ kó lè bá wọn ṣe àgbèrè ẹ̀sìn, ó dájú pé màá bínú sí onítọ̀hún,* màá sì pa á, kí n lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.+

  • Diutarónómì 18:10-12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Ẹnì kankan láàárín yín ò gbọ́dọ̀ sun ọmọkùnrin rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin rẹ̀ nínú iná,+ kò gbọ́dọ̀ woṣẹ́,+ kò gbọ́dọ̀ pidán,+ kò gbọ́dọ̀ wá àmì ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀,+ kò gbọ́dọ̀ di oṣó,+ 11 kò gbọ́dọ̀ fi èèdì di àwọn ẹlòmíì, kò gbọ́dọ̀ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ abẹ́mìílò+ tàbí woṣẹ́woṣẹ́,+ kò sì gbọ́dọ̀ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ òkú.+ 12 Torí Jèhófà kórìíra ẹnikẹ́ni tó bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, torí àwọn ohun ìríra yìí sì ni Jèhófà Ọlọ́run yín ṣe máa lé wọn kúrò níwájú yín.

  • Ìfihàn 21:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Àmọ́ ní ti àwọn ojo àti àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́+ àti àwọn tí èérí wọn ń ríni lára àti àwọn apààyàn+ àti àwọn oníṣekúṣe*+ àti àwọn tó ń bá ẹ̀mí lò àti àwọn abọ̀rìṣà àti gbogbo òpùrọ́,+ ìpín wọn máa wà nínú adágún tó ń jó, tí a fi imí ọjọ́ sí.+ Èyí túmọ̀ sí ikú kejì.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́