3 Lẹ́yìn náà, Mósè wá, ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ Jèhófà àti gbogbo ìdájọ́ náà+ fún àwọn èèyàn, gbogbo àwọn èèyàn náà sì fohùn ṣọ̀kan, wọ́n fèsì pé: “Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ la múra tán láti ṣe.”+
9 Nígbà tí mo lọ sórí òkè láti gba àwọn wàláà òkúta,+ àwọn wàláà májẹ̀mú tí Jèhófà bá yín dá,+ ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru+ ni mo fi wà lórí òkè náà, tí mi ò jẹ, tí mi ò sì mu.