17 Kí ẹ pa ìlú náà run àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀;+ Jèhófà ló ni gbogbo rẹ̀. Ráhábù+ aṣẹ́wó nìkan ni kí ẹ dá ẹ̀mí rẹ̀ sí, òun àti gbogbo àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ilé, torí ó fi àwọn tí a rán níṣẹ́ pa mọ́.+
3 Ní báyìí, lọ ṣá àwọn ọmọ Ámálékì+ balẹ̀, kí o sì pa wọ́n run pátápátá+ pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n ní. O ò gbọ́dọ̀ dá wọn sí;* ṣe ni kí o pa gbogbo wọn,+ ọkùnrin àti obìnrin, ọmọdé àti ọmọ jòjòló, akọ màlúù àti àgùntàn, ràkúnmí àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.’”+