-
Nọ́ńbà 3:36, 37Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
36 Ojúṣe àwọn ọmọ Mérárì ni pé kí wọ́n máa bójú tó àwọn férémù+ àgọ́ ìjọsìn, àwọn ọ̀pá gbọọrọ rẹ̀,+ àwọn òpó rẹ̀,+ àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò rẹ̀, gbogbo ohun èlò+ rẹ̀ àti gbogbo iṣẹ́ tó jẹ mọ́ nǹkan wọ̀nyí,+ 37 títí kan àwọn òpó tó yí àgbàlá náà ká àti àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò+ wọn, èèkàn àgọ́ wọn àti okùn àgọ́ wọn.
-
-
Nọ́ńbà 4:31-33Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
31 Àwọn ohun tí wọ́n á máa gbé+ tó jẹ mọ́ iṣẹ́ wọn nínú àgọ́ ìpàdé nìyí: àwọn férémù+ àgọ́ ìjọsìn, àwọn ọ̀pá ìdábùú+ rẹ̀, àwọn òpó+ rẹ̀, àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò + rẹ̀; 32 àwọn òpó+ àgbàlá tó yí i ká, àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò + wọn, àwọn èèkàn+ àgọ́ wọn àti àwọn okùn àgọ́ wọn pẹ̀lú gbogbo ohun èlò wọn àti gbogbo iṣẹ́ tó jẹ mọ́ nǹkan wọ̀nyí. Kí ẹ fi orúkọ yan ohun tí kálúku wọn á máa gbé. 33 Bí ìdílé àwọn ọmọ Mérárì+ á ṣe máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé nìyí, kí Ítámárì ọmọ àlùfáà Áárónì+ máa darí wọn.”
-