17 Èmi yóò sọ̀ kalẹ̀+ wá bá ọ sọ̀rọ̀ níbẹ̀,+ mo máa mú lára ẹ̀mí+ tó wà lára rẹ, màá sì fi sára wọn, wọ́n á sì máa ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ru ẹrù àwọn èèyàn náà, kí o má bàa dá ru ẹrù náà.+
8 Ojúkojú* ni mò ń bá a sọ̀rọ̀,+ láì fọ̀rọ̀ pa mọ́, kì í ṣe lówelówe; ìrísí Jèhófà ló sì ń rí. Kí wá nìdí tí ẹ̀rù ò fi bà yín láti sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí Mósè ìránṣẹ́ mi?”